Ilé ìgbìmọ̀ aṣofin Èkó gbóná janjan láàrọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ di làásìgbò láàrin àwọn ọmọ ilé ìgbimo asofin Èkó àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò DSS.
Aṣọ dúdú ni àwọn òṣìṣẹ́ DSS náà wọ̀, wọ́n dé akoto wọ́n sì dira ogun, ẹnu ọ̀nà àbàwọlé ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ni wọ́n dúró sí tí wọ́n sì ń bá àwọn aṣofin wọ̀yàájà níkọ̀ọ̀kan.
Rògbòdìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí oníkálukú bẹ̀rẹ̀ sí du orí ara rẹ̀ kó le ríi gbé délé.
Ohun tó fa èyí gan-an kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí. Ohun tí àwọn èèyàn fura pé ó le fà á náà ni rògbòdìyàn tó wà nílẹ̀ lórí ìyọnípò Ọbásà ní èyí tó ti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà bíi ti ẹjọ́ tí Gómìnà Sanwoolu ń jẹ́ lọ́wọ́.
A mú ìròyìn wá fún yín níjelòó nípa ìgbìmọ̀ tí wọ́n gbé dìde láti wádìí Sanwoolu tíi ṣe Gómìnà Èkó.
Ẹni tí kò bá ní ẹ́fídẹ́ńsì, àlàyé rẹ̀ yóò pọ̀ gan-an ni, Gómìnà Babajide Sanwoolu gbọdọ̀ ní àwọn ẹ́fídẹ́ńsì rẹpẹtẹ nítorí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́fà dìde nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó láti ṣèwádìí owó rọ̀gùn-rọ́gún tí Sanwó-olú tí í ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ná lórí àkànṣe iṣẹ́ iná.
Àkànṣe iṣẹ́ iná náà tó wà ní abẹ́ ìdarí ilé-iṣẹ́ Agbára àti Àlùmọ́nì ilẹ̀ ní in lọ́kàn láti pèsè agbára iná tó ṣeé simi lé fáwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó.
Níbi ìjókòó àwọn aṣòfin lọ́jọ́ Ajé tó kọjá, olórí-ilé tí í ṣe Mojísọ́lá Meranda, yàn àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ kan èyí tí Abíọ́dún Tobun, Desmond Elliot, Stephen Ògúndipẹ̀, Abíọ́dún Ọ̀rẹ́kọ̀yà, Fẹ́mi Saheed àti Sabur wà lára wọn.
Meranda tẹnu mọ́ ọn bó ṣe ṣe pàtàkì láti lo àgbájọ ọwọ́ fún pípèsè ìmọ́lẹ̀ fún Èkó ; ó sì sọ bí iṣẹ̀ náà ṣe jẹ́ pàtàkì sí. Ó tún sọ ọ́ nínú ìjíròrò náà bí àwọn ṣe gbọ́dọ̀ pèsè iná ìgboro fún àwọn olùgbé Èkó, èyí yóò mú ààbò tó péye àti ìdáàbò bò ẹ̀mí àti dúkìá jákè-jádò ipinle Èkó.
“ Èyí nìkan ni ọ̀nà tá a fi lè yanjú ìṣòro àìsí ààbò ; nígbà tí gbogbo àyíká bá mọ́lẹ̀ rokoso, a ó lè dá ẹni tó ń bọ̀ mọ̀; a ó mọ̀ bóyá elewu ènìyàn ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Èyí ni àfojúsùn Èròǹgbà wa lórí àkànṣe iṣẹ́ náà”
Ó tún sọ ọ́ síwájú sí i pé “ ó yẹ kí a la àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ lọ́yẹ̀ pé iná ìgboro gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àkànṣe iṣẹ́ tá a bá gbé fún agbaṣẹ́ṣe lórí ọ̀nà.
Lákòótán, ó rọ ìpínlè àti ìjọba ìbílẹ̀ láti fi kún ìsapá wọn fún àbójútó ọlọ́kan-ò-jọ̀kan.
Bí a bá fi owó ra òòyì, ó ṣáà yẹ kó kọ́ni lójú, àìrí iná ọba lò déédéé ní ìpínlẹ̀ Èkó lẹ́yìn owó ribiribi tí Gómìnà ná lé orí rẹ̀ ni ìgbìmọ̀ yìí fẹ́ ṣe ìwádìí rẹ̀.
Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an ní pàtó nínú ìṣèjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò yé ẹnìkan tààrà. Ọdún yìí náà ni wọ́n yọ Mudashiru Obasa nípò agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ aṣòfin Èkó lórí ẹ̀sùn pé ó fi àwọn owó kan ṣe iṣẹ́ àkànṣe tí kò lábọ̀.
Obasa náà wí tẹnu rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà wí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ń ṣàwàdà ni pé wọn kò le yọ òun nípò bíi báun, ó ní òun ṣì ni agbẹnusọ pé aṣọ tí ìpìn bá bọ́ sílẹ̀, kò sí ẹranko tó le gbé e wọ̀. Ṣé lóòótọ́ ni pé àtàrí àjànàkú ni ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kìí ṣe ẹrù ọmọdé?
Ilé aṣòfin Èkó fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Obasa sọ yìí, wọ́n ṣe àlàyé ipò tí ìyọnípò Obasa wà báyìí àti àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde láti ẹnu Olukayode Ogundipe pé àwọn tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin nínú ìyọnípò rẹ̀ pé àwáwí lásán ni Obasa ń sọ pé wọn kò tẹ̀lé òfin.
Èkejì ni pé Obasa kò wá síbi ìpàde tó wáyé lórí ìyọnípò rẹ̀. Ogundipe wí pé ó yẹ kí ó wá sí ìpàdé náà kó mójú ajé kònísọ̀ àmọ́ ó kọ̀ kò yọjú.
Yàtọ̀ sí pé Obasa tó lọ̀rọ̀ kò wá sí ìpàdé, ìdí tí ìpàdé lórí ìyọnípò rẹ̀ kò fi wáyé ni pé arábìnrin Meranda ṣẹ̀ṣẹ̀ wọṣẹ́ bíi agbẹnusọ náà ni nítorí náà, àwọn ohun mìíràn tó ṣe pàtàkì ló mójútó.
Kò tán síbẹ̀ o, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin wí pé kékeré ni ẹ̀sùn owó géètì àti owó ọkọ̀ bọ̀gìnnì tí àwọn fi kan Obasa o, wọ́n ní àwọn ẹ̀sùn mìíràn tó wà nílẹ̀ tó jẹ mọ́ owó rọ̀gùnrọ́gún wà nílẹ̀ tó sì jẹ́ pé òun ni ajé rẹ̀ ṣí mọ́ lórí. Ilé aṣòfin wí pé bí Obasa bá ti wá sí ìpàdé, àwọn yóò tẹ́ pẹpẹ àwọn ẹ̀sùn rẹ̀ fún un.
Àwọn akọ̀ròyìn bi Ogundipe léèrè bí wọn yóò bá pe àjọ EFCC sí ọ̀rọ̀ náà, Èsì tó fọ̀ náà ni pé lẹ́yìn tí àwọn àgbà aṣòfin bá gbé àwọn ẹ̀sùn náà wò, wọn yóò mọ̀ bí wọn yóò pe EFCC tàbí wọn kò ní pè é.
Ohun tí Obasa ń jẹ lẹ́nu ni pé òun kò sí nílé lásìkò tí wọ́n yọ òun ní èyí tó lòdì sí òfin.
Obasa wí pé lábẹ́ òfin, dandan ni kí òun ó wà lórí ìjokòó bí wọ́n bá fẹ́ yọ òun nípò àbí ojú àwo ṣá ni àwo fi ń gba ọbẹ̀, ẹnìkan kìí sì fárí lẹ́yìn olórí, ó ṣe jẹ́ ìgbà tí òun lọ ìrìn àjò ni wọ́n yọ òun? Kò le ṣe é ṣe o.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀sùn tí ilé aṣòfin fi kan òun kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, òfûtùfẹ́tẹ̀ ásà tí ò ní káún nínú ni. Wọ́n ní òun fi bílíọ̀nù mérìndínlógún ṣe géètì, Obasa wí pé ṣé géètì Jẹ́ríkò ni géètì náà ni?
Wọ́n tún ní òun fi ogójì bílíọ̀nù ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì, Obasa wí pé kí ẹ má dá wọn lóhùn o, àwáwí ni wọ́n ń wá kiri.
Títí di àsìkò yìí, Obasa àti ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kò tíì yanjú ọ̀rọ̀ náà kódà Obasa ti wọ́ wọn lọ sí ilé ẹjọ́.