Ọ̀rọ̀ kan n jà ranyinranyin lórí ẹ̀rọ̀ ayélujára pé Olóṣèlú tó lágbára lágbàáyé, Ààrẹ DONALD TRUMP ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé kí ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ tú NNAMDI KANU , ẹni tó jẹ́ ajìjàgbara fún àwọn ẹ̀yà igbo kí wọ́n le è dáwá, kí wọ́n pínyà lára kúrò lábẹ́ Àsíá Ilẹ̀ Nàìjíríà, Kí ẹ̀yà ìgbo di orílẹ̀ èdè BIAFRA tú u sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí wọn jù ú sí.
Ní oṣù kẹfà ọdún 2021 ni NNAMDI KANU tó n jà fún òmìnira àwọn ẹ̀yà Ìgbò ni ìjọba àpapọ̀ fi ọwọ́ ṣìkún òfin mú lórìlẹ̀ èdè INTERPOL KENYA tí wọ́n sì fàá lé ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́wọ́. Orí ẹ̀rọ alátagbà Fesìbúùkù tó ní àwọn akópa bí i ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdíndínlọ́gbọ̀n ni a ti rí fọ́nrán kan níbi tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, DONALD TRUMP ti ní kí wọ́n tú NNAMDI KANU sílẹ̀ ní àhámọ́. Nínú fọ́nrán náà ni Ààrẹ DONALD TRUMP ti n ké tantan pé kí wọ́n fi arákùnrin ajìjàgbara àwọn ẹ̀yà ìgbò IPOB sílẹ̀ ní àhámọ́ tí ìjọba àpapọ̀ jù ú sí láti ọdún yìí wá.Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rí fọ́nrán náà, wọ́n ní òfúùtù-fẹ́ẹ̀tẹ̀ aásà tí kò ní kánún ni fọ́nrán tí wọ́n gbé síta náà, òfégè ni, kò já mọ́ nnkankan rárá, àti pé Ààrẹ DONALD TRUMP kò sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan ló n tú irọ́ tà bí èlùbọ́. Wọ́n ní ẹ̀rọ̀ AI (ARTIFICIAL INTELLIGENCE) lásán làsàn ni wọ́n pè ní Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, irọ́ lásán la bá m bẹ̀.
Láìpẹ́ yìí, ní ìpínlẹ̀ Enugu ni àwọn èèyàn kan bẹ̀bẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ MAZI NNAMDI KANU, olórí àjọ IPOB tó n jà fú ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà ìgbò. Wọ́n ní ìtẹtọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn mọ́lẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò ilẹ̀ SOUTH EAST níbi ìpàdé tí wọ́n fi sọrí PEACE AND SECURITY ni wọ́n ti sọ fún gbogbo olóye àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn nílẹ̀ yìí láti fi ojú ṣùnnùkùn wo ọ̀rọ̀ yìí àti ohun tó ṣokùnfà rẹ̀ gan an. Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti tọ́ka sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ̀tọ́ ẹni dúnni àti ìtìmọ́lé lọ́nà àìtọ́ pàápàá jùlọ àwọn ọlọ́pàá SOUTH-EAST.
Ọ̀gbẹ́ni NNAMDI KANU n jẹ́jọ́ ẹ̀sùn oríṣiríṣi lọ́wọ́ tó sì n jẹ́jọ́ yìí láti ìgbà tí wọ́n ti mú u ní ìlú INTERPOL KENYA lóṣù kẹfà ọdún 2021. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ íbò ló gbé dàgbà, síbẹ̀, ìlú ọba ní òkè òkun ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè. Lẹ́yìn ìgbà tí NNAMDI KANU ti dá ẹgbẹ́ IPOB tó n jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà ìgbò sílẹ̀ lọ́dún 2014, NNAMDI KANU pe àwọn ẹ̀ya ìgbò tó fi òkè òkun ṣe ibùgbé pé kí wọ́n pínyà, kí BIAFRA dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè olómìnira tirẹ̀, tí kò ni fi ibì kankan ní nnkan ṣe papọ̀ mọ́ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà. NNAMDI KANU tún ní kí wọ́n dìde ogun, kí wọ́n gbógun ti ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà nítorí ìwà àjẹbánu wọn.
Nígbà kan, ẹgbẹ́ ALL PROGRESSIVE CONGRESS (APC) fi ẹ̀sùn kan NNAMDI KANU pé ó n kẹ̀yìn àwọn ọmọ Nàìjíríà sí ìjọba ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ IPOB, tó n ja fún òmìnira ẹ̀yà ìgbò ní kò rí bẹ́ẹ̀, òmìnira ọmọ BIAFRA ló jẹ wọ́n lógùn jùlọ. Nínú àtẹ̀jáde fọ́nrán náà ni Ààrẹ DONALD TRUMP ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà yóò ti ẹ̀yà ígbó lẹ́yìn láti le è du ipò tó bá wù ú lábẹ́ òfin àgbááyé.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rí fọ́nrán náà, wọ́n ní òfúùtù-fẹ́ẹ̀tẹ̀ aásà tí kò ní kánún ni fọ́nrán tí wọ́n gbé síta náà, òfégè ni, kò já mọ́ nnkankan rárá, àti pé Ààrẹ DONALD TRUMP kò sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kan ló n tú irọ́ tà bí èlùbọ́. Wọ́n ní ẹ̀rọ̀ AI (ARTIFICIAL INTELLIGENCE) lásán làsàn ni wọ́n pè ní Ààrẹ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, irọ́ lásán la bá m bẹ̀.Ọ̀gbẹ́ni NNAMDI KANU n jẹ́jọ́ ẹ̀sùn oríṣiríṣi lọ́wọ́ tó sì n jẹ́jọ́ yìí láti ìgbà tí wọ́n ti mú u ní ìlú INTERPOL KENYA lóṣù kẹfà ọdún 2021. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ íbò ló gbé dàgbà, síbẹ̀, ìlú ọba ní òkè òkun ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè. Lẹ́yìn ìgbà tí NNAMDI KANU ti dá ẹgbẹ́ IPOB tó n jà fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà ìgbò sílẹ̀ lọ́dún 2014, NNAMDI KANU pe àwọn ẹ̀ya ìgbò tó fi òkè òkun ṣe ibùgbé pé kí wọ́n pínyà, kí BIAFRA dúró gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè olómìnira tirẹ̀, tí kò ni fi ibì kankan ní nnkan ṣe papọ̀ mọ́ pẹ̀lú ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà. NNAMDI KANU tún ní kí wọ́n dìde ogun, kí wọ́n gbógun ti ìjọba ilẹ̀ Nàìjíríà nítorí ìwà àjẹbánu wọn.
Láìpẹ́ yìí, ní ìpínlẹ̀ Enugu ni àwọn èèyàn kan bẹ̀bẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ MAZI NNAMDI KANU, olórí àjọ IPOB tó n jà fú ẹ̀tọ́ àwọn ẹ̀yà ìgbò. Wọ́n ní ìtẹtọ̀ọ́ ọmọ ènìyàn mọ́lẹ̀. Àwọn agbẹjọ́rò ilẹ̀ SOUTH EAST níbi ìpàdé tí wọ́n fi sọrí PEACE AND SECURITY ni wọ́n ti sọ fún gbogbo olóye àti àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn nílẹ̀ yìí láti fi ojú ṣùnnùkùn wo ọ̀rọ̀ yìí àti ohun tó ṣokùnfà rẹ̀ gan an. Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti tọ́ka sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ̀tọ́ ẹni dúnni àti ìtìmọ́lé lọ́nà àìtọ́ pàápàá jùlọ àwọn ọlọ́pàá SOUTH-EAST.Ní oṣù kẹfà ọdún 2021 ni NNAMDI KANU tó n jà fún òmìnira àwọn ẹ̀yà Ìgbò ni ìjọba àpapọ̀ fi ọwọ́ ṣìkún òfin mú lórìlẹ̀ èdè INTERPOL KENYA tí wọ́n sì fàá lé ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà lọ́wọ́. Orí ẹ̀rọ alátagbà Fesìbúùkù tó ní àwọn akópa bí i ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdíndínlọ́gbọ̀n ni a ti rí fọ́nrán kan níbi tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, DONALD TRUMP ti ní kí wọ́n tú NNAMDI KANU sílẹ̀ ní àhámọ́. Nínú fọ́nrán náà ni Ààrẹ DONALD TRUMP ti n ké tantan pé kí wọ́n fi arákùnrin ajìjàgbara àwọn ẹ̀yà ìgbò IPOB sílẹ̀ ní àhámọ́ tí ìjọba àpapọ̀ jù ú sí láti ọdún yìí wá.