Nuru Isah; ẹni àádọ́ta ọdún ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí látàrí pé ó lu iyàwó rẹ̀ kejì; Wasila Abdullah pa.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Wasila, oúnjẹ ìṣínu ló fa ijà láàrin òun àti ọkọ rẹ̀; Nuru ní alẹ́ àná, ọ̀rọ̀ náà le gan-an tí Nuru fi yọ ẹgba tìí tó sì lù ú pa.
Ìpínlẹ̀ Bauchi ni èyí tis ̣ẹ̀, alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi; Ahmed Wakil ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé Nuru ti ń ṣẹ́jú pàkòpàkò bíi ẹran Nuru ní àgọ́ àwọn lórí ẹ̀sùn pé ó lu ìyàwó rẹ̀ pa.
Oníṣòwò ni Nuru, agbègbè Fadaman Mada ni ó ń gbé. Òun àti iyàwó rẹ̀ keji; Wasila ní gbọ́lóhùn asọ̀ lórí oúnjẹ ìṣínu ní alẹ́ àná, Nuru yọ ẹgba tìí ó sì lùú títí tó fi dákú. Nígbà tí wọn yóò fi gbé e délé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Abubakar Tafawa Balewa, Wasila ti kú pátápátá.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi wí pé àwọn ti mú ẹgba tí Nuru fi na ìyàwó rẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí, wọ́n ṣe ìlérí pé ìdájọ òdodo yóò wáyé lórí ikú Wasila.
Lónìí lọ́la bí ẹkún apọkọjẹ lọ̀rọ̀ bí tọkọtaya ṣe ń lu ara wọn pa lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí. Inú oṣù tó lọ yìí náà ni àwọn tọkọtaya kan ṣá ara wọn ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Ekiti. A mú ìròyìn náà wá pé ‘Ọ̀rọ̀ náà ṣe àwọn ọmọ wọn gan-an ní kàyéfì, kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ó ṣe ṣẹ̀lẹ̀ nítorí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí.
Àkọ́bí wọn lọ́kùnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà pé bàbá àwọn dé ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́, ó ní òun kò le jẹun àyàfi bí ìyá àwọn bá dé.
Nígbà tí ìyá wọn dé, gbogbo wọn jọ jẹun, wọ́n gbàdúrà, bàbá wọn ka bíbélì sí wọn létí, gbogbo wọn sì wọ yàrá wọn lọ sùn.
Nígbà tó di òru ni àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró àdá láti inú yàrá bàbá wọn, títì láti inú ni ìlẹ̀kùn wọn wà, àwọn ọmọ bá lọ pe awon ará àdúgbò, nígbà tí wọn yóò fi dé, wẹ́lo ni yàrá náà kò sí ariwo kankan mọ́.
Àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò já ìlẹ̀kùn yàrá náà, òkú tọkọtaya ni wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpá àdá tó jinú lára wọn. Kódà, nǹkan ọmọkùnrin bàbá ti dá dúrò nílẹ̀; kò sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́.
Ohun tí wọ́n le sọ nípa ipò tí wọ́n bá wọn náà ni pé bóyá ìyàwó gé okó ọkọ rẹ̀ ni ọkọ náà bá kó àdá bò ó ni wọ́n bá ṣá ara wọn pa. Èrò lásán ni èyí, kò ṣojú ẹnìkankan.
Àwọn akọ̀ròyìn bi ọmọ náà léèrè pé ṣé àwọn òbí wọn máa ń jà tẹ́lẹ̀.
Ọmọ yìí fèsì pé ìjà kìí ṣe ohun titun nílé àwọn nítorí pé gbogbo ìgbà ni ìyá àwọn máa ń bá bàbá àwọn jà lórí ẹ̀sùn pé bàbá àwọn ń yan àlè.
Ó wí pé bàbá àwọn máa ń bá àwọn ṣeré dáadáa àmọ́ tí ìyá awo bá ti dé ni àyà rẹ̀ ó máa já. Ọmọ yìí wí pé bàbá òun sọ fún òun lọ́jọ́ kan pé ẹ̀rù ìyá òun ń ba òun.
Àmọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, ìjà ni àwọn ń retí bí ìyá àwọn ṣe dé àmọ́ ẹ̀rín àti ọ̀yàyà ni ìyá wọn bá wọlé, inú gbogbo wọn dùn láìmọ̀ pé gbẹgẹdẹ ó padà gbiná lóru.
Ọmọ mẹ́rin ló wà láàárín tọkọtaya yìí, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni àkọ́bí wọn, kò sí èyí tó tójú bọ́ nínú wọn.
Àwọn ará àdúgbò náà kín àlàyé tí ọmọ yìí ṣe lẹ́yìn. Wọ́n ní fádèyí olóró àdúgbò ni arábìnrin náà, gbogbo ìgbà ni ó máa ń bá ọkọ rẹ̀ jà, á wí pé ọkọ òun ń yan àlè.
Wọ́n ní ohun tó ṣẹlẹ̀ lóru ọjọ́ náà gan-an kò yé ẹnikẹ́ni tààrà nítorí pé wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí. Àwọn ará àdúgbò tilẹ̀ ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ̀ngbọ̀n nítorí pé ọlọ́pàá ni ọkùnrin náà kó tó kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà’
A kò tíì gbọ́ àbọ̀ ìwádìí títí di àsìkò yìí. Ibo lẹ rò pé yóò yọrí sí?
Ṣẹ́ ẹ rántí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun níjọ́sí? Níbi tí Iyanu ti gún ọkọ rẹ̀ Jimoh lọ́bẹ pa nítorí ṕ ó fura síi pé ó ń yan àlè. Kódà, fúnra Iyanu ló lọ fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá pé òun gún ọkọ òun lọ́bẹ pa. kò dà wọ́n láàmú kí wọ́n ṣẹṣẹ̀ máa wáa kiri. A mú ìròyìn náà wá pé ‘Ìyàwó ilé kan tó pe orúkọ ara rẹ̀ ní Iyanu Adedeji ló gún ọkọ rẹ̀; Funsho Jimoh lọ́bẹ pa nítorí ó fura síi pé ó yan àlè.
Ọmọ ọdún méjìlélógún ni Iyanu nígbà tí ọkọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n. Ìgbéyàwó wọn ti lé lọ́dún mẹ́jọ, ọmọ méjì ló wà láàrin wọn.
Agbègbè Ifelodun, Gbonagun ní Abeokuta ni èyí ti ṣẹ̀, ní ọgbọ̀njọ́, oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin tọkọtaya yìí, ìjà náà dá lérí ẹ̀sùn tí Iyanu fi kan ọkọ rẹ̀ pé ó ń yan àlè, ó mú ọ̀bẹ ó sì fi gún Funsho láyà.
Lẹ́yìn náà ló gbé e lọ sílé ìwòsàn ìjọba Idi-Aba, Dọ́kítà wí pé Funsho ti kú.
Fúnra Iyanu ló lọ fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá pé òun gún ọkọ òun pa o.
Omolola Odutola; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ló fi ọ̀rọ̀ náà léde pé Iyanu gún ọkọ rẹ̀ pa o lórí ẹ̀sùn pé ó ń yan àlè.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn tọkọtaya láti yàgò fún èdè àìyedè tó bá ti mú wàhálà dání’
Kò sí ibi tí ìṣe ò sí àmọ́ orí bíbẹ́ kọ́ ni òògùn orí fífọ́.