Lórí fọ́nrán àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Igbinedion tó lu síta nínú èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta kan ti ń lu akẹgbẹ́ wọn bíi kíkú bíi yíyè, mọ̀lẹ́bí ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ọmọ tí wọ́n lù náà.
Tim Asoro; bàba Choice Asoro ló bu ọwọ́ lu ìwé ìtọrọ àforíjìn náà. Ẹbí Asoro ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ya àwọn lẹ́nu ó sì tún bàwọ́n lọ́kàn jẹ́, fọ́nrán náà jẹ́ ohun kan tó ba àwọn nínú jẹ́ jù láyé yìí gẹ́gẹ́ bíi òbí, ohun ìdòjútì ni fún àwọn pé ọmọ wọn le hu ìwà tó mú ìpalára bá akẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ tí wọ́n lù náà, àwọn ẹbí rẹ̀ àti iléèwé náà lápapọ̀. Dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà wà ní àlàáfíà àmọ́ ipò ìmọ̀lára ọmọ náà kò dára to.
Àwọn ẹbí Asoro ní èyí fi àwọn lọ́kàn balẹ̀ díẹ̀ àwọn sì ṣetán láti ṣe ìrànwọ́ lórí ìmọ̀lára ọmọ náà. Bákan náà ni wọ́n tọrọ àforíjì lọ́wọ́ iléèwé Igbinedion lórí àbùkù tí ó bá orúkọ wọn látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ wọn tẹ̀síwájú pé àwọn ti bá Choice sọ̀rọ̀ gidi ó sì ti ronú pìwàdà lórí ìwà tó hù náà, ó sì ti mọ ohun tó le tẹ̀yìn rẹ̀ yọ fún òun alára, ọmọ tí wọ́n lù náà àti ilé ìwé náà.
Wọ́n ní àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ lórí bí yóò ṣe di àtúnbí tí yóò rí olùgbaninímọ̀ràn tí yóò sì yí padà di ọmọ rere bíi iyán.
‘Lẹ́ẹ̀kan síi, a tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ tí wọ́n lù yìí a sì ṣe ìlérí pé gbogbo ẹni tí ó fi ara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni yóò rí ìwòsàn’ Tim Asoro

ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ YÌNBỌN PA AWAKỌ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OSUN.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ilẹ̀ wa ti yìnbọn pa awakọ̀ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ní agbègbè Onibueja ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Osogbo sí Iwo.
Àwọn èrò pé lé ọkọ̀ náà lórí, wọ́n ká fọ́nrán rẹ̀ wọ́n sì rí fọ́nrán àwọn tó yìnbọn náà ká kí wọ́n tó sá lọ.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè náà ń lé awakọ̀ náà bọ̀ láti ọ̀nà Iwo, nígbà tí wọ́n lé e dé Onibueja ni wọ́n ṣíná ìbọn mọ́ ọkọ̀ rẹ̀, gbogbo ara ọkọ̀ náà ló lu kárí tí awakọ̀ náà sì kú lójú ẹsẹ̀.
Àwọn ẹni yìí kò wọ aṣọ iṣẹ́ wọn àmọ́ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ṣe ìdámọ̀ wọn pé ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ni wọ́n.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abiodun Ojelabi pé àwọn ti ṣe ìdámọ̀ àwọn ẹni náà, wọ́n ní ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè ni wọ́n àwọn sì ti mú méjì nínú wọn sí àhámọ́.
Àwọn èrò bèèrè fún ìwádìí àti ìdàjọ́ òdodo lórí ikú ọkùnrin awakọ̀ náà.

WỌ́N TI YÌNBỌN FÚN ‘BRODA SHAGGY’ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní yàjóyàjó ni pé wọ́n yìnbọn fún Samuel Perry; adẹ́rìn-ínpòṣónú tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ ‘Broda Shaggy’ ní abẹ́ afárá Sango ní ìpínlẹ̀ Ogun níbi tó ti ń ya eré apanilẹ́rìn-ín rẹ̀.
A kò tíì rí ọ̀rọ̀ gbà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ ọlọ́pàá kan fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n yìnbọn fún un lóòótọ́.
A ríì gbọ́ pé ilé ìwòsàn Blooming Care tó wà ní Alakuko ní ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n gbé e lọ fún ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ àmọ́ ó ṣì nílò iṣẹ́ abẹ láti yọ ọta náà wọ́n sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Duchess ní Ikeja.
A kò rí àwọn ilé ìwòsàn méjéèjì bá sọ̀rọ̀ láti fìdí èyí múkẹ̀ àmọ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Abimbola Adebisi ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè láti ilé ìwòsàn Duchess, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ti kó àwọn ọlọ́pàá ránṣẹ́ síbẹ̀.
Wọ́n bá Shaggy lórí ìtẹ́ pẹ̀lú ojú ọgbẹ́ ní itan rẹ̀. Abimbola wí pé ìpínlẹ̀ Ogun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Ogun ni yóò wádìí rẹ̀.

ÌJỌBA TI KÉDE ỌJỌ́BỌ ÀTI ỌJỌ́ ẸTÌ NÍ ỌJỌ́ ÌSINMI.
Ní àbájá oṣù ràmàdánà tó ń parí lọ yìí, ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ kọkàndínlógún àti ogúnjọ́ gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún ọdún ìtunu ààwẹ̀ náà.
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́; Olubunmi Tunji-Ojo ló sọ èyí di mímọ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹtàdínlógún.
Tunji-Ojo bá àwọn Mùsùlùmí yọ̀ lórí àbájá ààwẹ̀ ọdún yìí, ó rọ̀ wọ́n láti ṣe àmúlò gbogbo àwọn ohun tí oṣù yìí fi kọ́ wa lẹ́yìn tó bá lọ tán.
Bákan náà ni mínísítà rọ gbogbo ọmọ Nàìjíríà láti fi àsìkò yìí gbàdúrà sí Ọlórun ọba kí ó túbọ̀ máa ran ìṣèjọba tó wà lóde yìí lówọ́ nítorí ìlọsíwájú ni ó jẹ wọ́n lógún.
AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉÈWÉ GÍGA OWERRI MÉJÌ TI KÚ SÓDÒ.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì kan tí wọ́n jẹ́ ti ilé ìwé gíga ìjọba tó wà ní Nekede, Owerri ti kú sínú odò Otammiri tó wà ní Imo.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí tẹ̀lé àwọn ọ̀rẹ́ wọn lọ sí odò náà lọ wẹ̀ kí wọ́n sì ya àwòrán, aráàlú kan kì wọ́n nílò lódò náà pé ilẹ̀ ti ṣú kí wọ́n má wẹ̀ àmọ́ wọn kò gbọ́, wọ́n kó sódò méjì sì rì nínú wọn.

AFURASÍ GAN MỌ́ INÁ ỌBA NÍBI TÓ TI Ń GBÌYÀNJÚ ÀTIJÍ ÀWỌN WÁYÀ INÁ.
Afurasí kan tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ti gan mọ́ iná níbi tó ti ń gbìyànjú àtijí àwọn wáyà iná lára ẹ̀rọ amúnáwá tiransifọ́mà.
Agbègbè Indepence ní ìpínlẹ̀ Enugu ni èyí ti ṣẹ̀, àwọn ará àdúgbò náà jí ni wọ́n bá ọkùnrin náà tó gan mọ́ ara ẹ̀rọ náà wọ́n sì fura síi pé bóyá níbi tó ti ń ká àwọn wáyà iná ara ẹ̀rọ náà ni ó ti gan mọ́ ọn.




