Adarí ilé iṣé ọkọ̀ ojú irin; Kayode Opeifa ti sọ̀rọ̀ lórí ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin tó wáyé lánàá.
Ó wí pé òun tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, yàtọ sí èyí, òun gba ẹ̀bi ìjàmbá náà ní tòun.
Nínú ìfòròwánilénuwò tí Ọ̀gbẹ́ni Kayode Opeifa ṣe lówǔrọ̀ yìí lórí ìkànnì Channels ni ó ti ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ pé:
‘Gẹ́gẹ́ bíi adarí ilé iṣé ọkọ̀ ojú irin, mo gba ẹ̀bi ìjàmbá náà. Bí irú nǹkan báyìí bá ṣẹlẹ̀, dandan ni kí adarí ẹ̀ka bẹ́ẹ̀ ó gba ẹ̀bi rẹ̀, nítorí náà, mo gba ẹ̀bi ìjàmbá yìí.
A dúpẹ́ fún Ọlọ́run pé kò sí ẹni tó kú nínú ìjàmbá yìí, irú ìjàmbá yìí le mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lọ àmọ́ a dúpẹ́ pé ẹnìkankan kò bá a lọ.
Nínú àwọn mẹ́fà tó fara pa náà, àwọn méjì ti lọ sí ilé wọn nígbà tí àwọn mẹ́rin yòókù wà ní ilé ìwòsàn. Àwọn mẹ́rin náà wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run ni lásìkò yìí, a ó ṣe àbẹ̀wò sí wọn.
A ní ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn èrò yòókù tí iye wọn lé ní ẹgbẹ̀ta, a ó kàn sí gbogbo wọn láti bèèrè àlàáfíà wọn nítorí ìbẹ̀rùbojo ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ Ọ̀gbẹ́ni Kayode tẹ̀síwájú pé ‘kò yẹ kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa ṣẹlẹ̀ àmọ́ bí ó bá ti ṣẹlẹ̀, a ó fi ṣe dáadáa síi ni’.
‘Mo fi dá gbogbo ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà lójú pé a ó ṣe àtúnṣe tó yẹ lójú ọ̀nà náà, ṣebí ẹ rí iṣẹ́ tí a ń ṣe lójú ọ̀nà Wariri sí Itakpe? Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn la bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, a gé àwọn irin tó ti gbó náà kúrò a sì ń gé irin titun síi’
Olóòtú bèèrè lọ́wọ́ Opeifa pé ṣé kìí ṣe àwọn agbésùnmọ̀mí ló da ọkọ̀ náà nù?
Ọ̀gbẹ́ni Kayode Opeifa fèsì pé ìwádìí ohun tó ṣe okùnfà ìjàmbá náà ṣì ń lọ lọ́wọ́ òun kò sì le sọ bí bẹ́ẹ̀ni àbí bẹ́ẹ̀kọ́ àmọ́ ohun tó dá òun lójú ni pé àwọn ojú irin náà ní ààbò tó péye, kò tó ìṣẹ́jú mẹ́wàá tí ọkọ̀ náà dànù tí àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti dé ibẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ológun ló ń dáàbò bo àwọn ojú irin wa a kò sì ní àkọsílẹ̀ ìgbésùnmọ̀mí lójú ọ̀nà náà.
Ohun tí a ó kọ́ ṣe ni pé a ó ti ojú irin náà pa fún àwọn àtúnṣe, àjọ NSIB yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láìpẹ́ lórí rẹ̀.
Bákan náà ni Opeifa sọ pé àhesọ ọ̀rọ̀ ni pé àwọn ọkọ̀ ojú irin náà kò dára tó, kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, a sì ti dá owó ọkọ̀ àwọn èrò náà padà.
Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé irú ìjàmbá yìí kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.
Bí ìjàmbá náà ṣe wáyé:
Ọkọ̀ ojú irin tó kó èrò láti Abuja lọ sí Kaduna ti dànù lójú ọ̀nà láàárọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá, ọkọ̀ ojú irin yìí yà bàrà kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ̀; àwọn ọkọ̀ àsomọ́ rẹ̀ fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀.
Àwọn èrò inú ọkọ̀ yìí rí fìrífìrí ọ̀run nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà fi ẹgbẹ́ lélẹ̀, àyà wọn já, ìbẹ̀rùbojo sì bá wọn.
Àwọn èrò náà ṣe àlàyé pé òjijì ni ọkọ̀ náà yà bàrà kúrò lójú ọ̀nà rẹ̀ ní èyí tó mú kí àwọn ọkọ̀ àsomọ́ rẹ̀ ó fi ẹ̀gbẹ́ lélẹ̀, àwọn èrò náà sáré du ara wọn jáde nínú rẹ̀.
Àwọn èèyàn mẹ́fà ni ó fara pa, kò tíì sí ẹni tó kú lásìkò yìí àmọ́ àwọn èèyàn kan ṣì há sínú àwọn ọkọ̀ náà.
Adarí ilé iṣé ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ yìí; Kayode Opeifa fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn , ó ni òun kò tíì le ṣe àlàyé rẹpẹtẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àmọ́ ohun tí òun le fìdí ẹ̀ múlẹ̀ ni pé ọkọ̀ náà dànù lóòótọ́.
Ní báyìí, Ọ̀gbẹ́ni Kayode Opeifa rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà kí wọ́n ó fi ọwọ́ wọ́nú, ó ní irú rẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.
Yàtọ̀ sí ìjàmbá ọkọ̀ ojú irin yìí, ìjàmbá ókọ̀ kan náà wáyé lórí afárá Third mainland ní èyí tí àwọn èèyàn méjì inú ọkọ̀ náà kó sínú ọ̀sà.
A gbọ́ pé:
Obìnrin kan tó jẹ́ ayàwòrán ni ọkọ̀ rẹ̀ forí ṣánpọ́n lórí afárá Third mainland lọ́jọ́ Àbámẹ́ta tó sì kó sínú ọ̀sà.
Àbúrò rẹ̀ tó wà nínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ náà kó sínú ọ̀sà pẹ̀lú rẹ.
Àwọn apẹja ni àwọn ẹbí wọn bẹ̀ kí wọn ó bá wọn wá àwọn èèyàn náà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà irinwó ni àwọn apẹja náà gbà kí wọn ó tó wá àwọn èèyàn náà jáde.
Ìròyìn fi yé wa pé nǹkan bíi aago márùún ìdájí ni ìjám̀bá náà wáyé ní itòsí Iyana Oworo, Èbúté mẹ́ta.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta náà ni wọ́n rí òkú obìnrin náà àmọ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun ni wọ́n rí òkú ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ yọ.
Àwọn ẹbí obìnrin yìí fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA àti àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka pàjáwìrì pé ìjàmbá náà ṣojú wọn àmọ́ wọn kò gbìyànjú àti yọ àwọn ẹni náà jáde, wọ́n kàn ń wòran ni, nígbà tí àwọn bẹ̀ wọ́n títí, wọ́n ní àwọn kò ní irinṣẹ́ ni àwọn ṣe tọ àwọn apẹja ìbílẹ̀ lọ, àwọn apẹja yìí gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà irinwó naira ₦400,000 kí wọ́n tó wá àwọn èèyàn náà jáde.
Àwọn èèyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ilé iṣẹ́ pàjáwìrì ìpínlẹ̀ Èkó lórí ìtàkùn ayélujára, wọ́n ní àfi kí wọn ó gba owó lọ́wọ́ àwọn tó bá ní ìjàmbá ọkọ̀ wọn kìí ṣe ìrànwọ́ kankan.
Ẹnìkan náà wí pé òun dẹ́kun wíwọ ọkọ̀ ojú omi láti ọjọ́ tí ọkọ̀ ojú omi òun dànù tí àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì sì ń wo àwọn níran láti òkè. Ó ní láti ọjọ́ náà ni òun kò ti wọ ọkọ̀ ojú omi mọ́.





