Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michael James ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó jí ara rẹ̀ gbé. Mílíọ́nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n náírà ni ó fẹ́ gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ owó ìtúsílẹ̀.
Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Edo ni Michael àmọ́ Delta ló tẹ̀dó sí. Ó ṣe àlàyé pé gbèsè tí òun jẹ tí òun ò mọ bí òun ṣe le san án padà ni ó mú kí òun hùwà bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́ láti ẹnu Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta, lọ́jọ́ kìíní, oṣù yìi, wọ́n rán Michael kí ó lọ da ilẹ̀ nù nílé, bí ó ṣe da ilẹ̀ náà nù tán ló kọ̀ láti padà sílé tó sì wọgbó lọ.
Ó pe ìyá rẹ̀ pé wọ́n ti jí òun gbé o kí wọn ó fi mílíọ́nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ránṣẹ́, lẹ́yìn náà ló pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nígbà tí òjò fẹ́ rọ̀ ni ó gbé ọ̀kadà kúrò níbi tó wà lọ sí apá ibòmíràn, ó tún pe ìyá rẹ̀ pé kí ó fi owó ránṣẹ́ nítorí wọ́n ń lu òun. Ìyá rẹ̀ dáa lóhùn pé àwọn ọdẹ àdúgbò ti jáde láti wá gbà á sílẹ̀.
Kò gbé aago rẹ̀ mọ́ lẹ́yìn èyí, nígbà tó ríi pé wọn kò ní fi owó ránṣẹ́ ló kúrò níbi tó wà lọ sí ibòmíràn tó sì pe ìyá rẹ̀ pé òun ti sá mọ́ àwọn ajínigbé náà lọ́wọ́- Michael jí ara rẹ̀ gbé.
Bright Edafe wí pé àwọn ọlọ́pàá ta mọ́ra nígbà tí wọ́n gba ìpè ìjínigbé náà, wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ kí ó tó di pé Michael fúnra rẹ̀ jáde níbi tó gbé ara rẹ̀ pamọ́ sí-Michael jí ara rẹ̀ gbé.
Michael kọ́ ni yóò kọ́ jí ara rẹ̀ gbé, obìnrin kan náà ti jí ara rẹ̀ gbé rí láti gba owó lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀:
Orílẹ̀-èdè South Africa ni ọkọ obìnrin yìí ń gbé, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Bélú, ọdún 2025 ni ó pe ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà pé wọ́n ti jí ìyàwó òun gbé, ó ní òun ti san mílíọ́nù mẹ́ta náírà owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ wọn kò fi sílẹ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bá ta mọ́ra, wọ́n kò sí ìwádìí, ṣàdédé ni obìnrin náà dé sílé tó ní wọ́n dá òun sílẹ̀.
Obìnrin yìí ṣe àlàyé pé àwọn ajínigbé dá òun lọ́nà, mẹ́fà ni iye wọn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́, ó ní wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun olówó iyebíye iphone 12promax. Ó ní inú àpò owó òun ni ọkọ òun san owó ìtúsílẹ̀ náà sí tí òun sì tari rẹ̀ sínú àpò owó àwọn ajínigbé.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àlàyé tí obìnrin yìí ṣe kò bára mu, wọ́n ṣe ìwádìí nọ́ḿbà tí wọ́n fi bá ọkọ sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì Whatsapp.
Ẹdẹ ni ẹni tó ni nọ́ḿbà náà wà, àwọn ọlọ́pàá lọ gbé e ó sì jẹ́wọ́ pé ọ̀rẹ́ òun náà tọrọ láti fi nọ́ḿbà òun ṣí ìkànnì Whatsapp òun sì fi òǹkà OTP ránṣẹ́ síi, ó ní òun kò mọ ohun tí ó fẹ́ fi ṣe.
Bákan náà ni wọ́n tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ iphone 12pro max dé ọwọ́ ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n kan, ó ṣe àlàyé pé òun ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ obìnrin náà ní ọ̀rìnlélọ́ọ̀dúnrún ẹ̀gbẹ̀rún náírà #380,000 pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí òun má tan ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní obìnrin náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí. Wọ́n rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún ìwà ọ̀daràn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá korò ojú sí ìwà yìí, wọ́n wí pé ìwà ọ̀daràn gbáà ni pàápàá lásìkò tí ìjínigbé gba ìlú kan yìí.
Lára àwọn ojúlówó ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó ti wáyé ni:
Inú oṣù Ẹrẹ́nà, ọdún 2025 ni àwọn Fulani ajínigbé ikọ̀ ẹni márùn-ún kan lọ gbé ọ̀gbẹ́ni Chibueze ní abúlé Ogwashi-Uku, wọ́n mú un rìn lọ sí abúlé Ubulu-Uku níbi tí wọ́n ti gbé ọ̀gbẹ́ni Afam, Inú oko kan lọ́nà Powerline ní Ubulu-Uku ni wọ́n kó wọn sí fún ọjọ́ díẹ̀ kí wọ́ tó máa pe àwọn ẹbí wọn fún owó.
Oko tí wọ́n kó awọn ẹni yìí sí jẹ́ oko ọ̀gbẹ́ni Godwin, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ẹrẹ́nà kan náà ni ọ̀gbẹ́ni Godwin, ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ló ṣiṣẹ́ lóko, wọn kò mọ̀ pé àwọn Fulani ajínigbé wà nínú oko, àwọn kàn ń ṣiṣẹ́ lọ ni tí wọ́n fi yọ sí wọn gúlẹ́.
Ẹ̀sẹkẹsẹ̀ ni wọ́n kó wọn mọ́ àwọn tí wọ́n jí gbé tẹ́lẹ̀, ìgbà tí àwọn ẹbí wọn kò tètè rówó san ni wọ́n pa ọ̀gbẹ́ni Godwin lójú aya àti àwọn ọmọ rẹ̀, owó rọ̀gùrọ́gún sì ni wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn méjì yòókù kí wọ́n tó fi wọ́n sílẹ̀.
Àwọn ará Ubulu-Uku wí pé àwọn Fulani ti sọ abúlé náà di ilé pàápàá àwọn ikọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún yìí, wọ́n wí pé ojoojúmọ́ ni àwọn ń sọnù ní abúlé náà tó sì jẹ́ pé àwọn márùn-ún yìí ló ń jí wọn gbé. Wọ́n ké sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀.
Ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì ọdún 2025 ni wọ́n gbé Tsiga ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori ní ìpínlẹ̀ Kastina. Ó wí pé ‘ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ la ń jẹun, Tuwo dawa náà sì ni wọ́n ń fún wa jẹ. Àkekèé àti èjò kò ṣàjòjì sí wa mọ́ nítorí pé ojoojúmọ́ la ń rí wọn. Àwọn ajínigbé yìí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á ní ká má wulè pe Ọlọ́run pé owó ni ká mú wá. Nǹkan tí wọ́n bẹ̀rù náà ni àwọn jagungagun ojú òfurufú, ẹ̀rù ikú máa ń bà wọ́n ó sì máa ń hàn lójú wọn bí àwọn jagunjagun ojú òfurufú náà bá dé. Bí àwọn ológun ojú òfurufú bá dé, àwa ni wọn yóò kó síta fi borí kó le jẹ́ pé àwa ni ọta yóò bà, Ọlọ́run ló fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ mi láwọn àsìkò náà.
Òpọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló wà ní ibẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn lọ́gàálọ́gàá àti àwọn èèyàn jàkànjàkàn láàrin ìlú ló kún ibẹ̀. Lílù kò tó nínà, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń nà wá nítorí àìrówó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn wa, Èyí mú ìpalára bá ìlera mi nítorí pé mo ní àìsàn ìpayà lára tẹ́lẹ̀, yàtọ̀ sí lílù, oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa jẹ́ kìkí iyọ̀ ní èyí tí kò dáa fún ìlera mi; bí ẹ ṣe ń wò mí yìí, mi ò le gun àtẹ̀gùn rárá’
Tsiga dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ yìí fún akitiyan rẹ̀ láti gba òun sílẹ̀. Ó ní akọ iṣẹ́ ni iṣẹ́ ológun pàápàá dídojú ìjà kọ àwọn ajínigbé. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara, Sokoto, Kastina àti Niger fún ìlàkàkà wọn láti ìgbà tí wọ́n ti gbé òun.
