Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni Kemi lórí ìtàkùn ayélujára ṣaájú ikú bàbá rẹ̀. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀; Dọ́kítà Omololu Olunloyo kú tán ni Kemi tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tó sì fi oríṣìí ẹ̀sùn kan bàbá náà.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni Dọ́kítà Victor Olunloyo dágbére fáyé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún. A mú ìròyìn ikú bàbá náà wá pé:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kan rí; Dọ́kítà Victor Omololu Olunloyo ti kí ayé pé ó dìgbóṣe lẹ́ni àádọ́run-ún ọdún.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìdílé Olunloyo ni pé Victor Olounloyo jáde láyé ní ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún rẹ̀ ku ọjọ́ péréte.
Oladapo Olunloyo ló bu ọwọ́ lu ìwé ìtúfọ̀ náà lórúkọ gbogbo ẹbí. Nínú rẹ̀ la ti ríi kà pé Victor Olunloyo jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti amojú ẹ̀rọ. Òun sì ni Balogun ìlú Ọ̀yọ́ àti Ọ̀tun Bobasewa ti Ilé-Ifẹ̀. Àwọn ipò mìíràn tí wọ́n ti dì mú ni ọ̀gá àgbà àkọ́kọ́ ní ilé ìwé gíga Ìbàdàn àti ọ̀gá àgbà àkọ́kọ́ ní ilé ìwé gíga Kwara.
Lẹ́yìn ikú bàbá, Kemi wí pé kí ẹnikẹ́ni má kí òun kú arafẹ́rakù nítorí pé òun kò fẹ́ ẹnìkankan kù. Ó tún júwe ojú òpó olóògbé pé kí àwọn èèyàn ó fi àwọn ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ṣọwọ́ síbẹ̀.
Kemi Olunloyo wí pé òun ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun kò ní wá sí orílẹ̀-ède Nàìjíríà bí bàbá òun bá kú. Ó wí pé abara méjì ni bàbá òun; ọ̀tọ̀ ni Olunloyo tí àwọn èèyàn mọ̀, ọ̀tọ̀ ni Olunloyo tí àwọn ń bá gbélé.
Àlàyé ẹ̀sùn tí Kemi fi kan bàbá rẹ̀ lẹ́kùnúnrẹ́rẹ́ ni pé bàbá náà fi ìyà gidi jẹ àwọn ọmọ rẹ̀ ní kékeré. Ó wí pé Olunloyo ṣe àwọn ọmọ rẹ̀ báṣabàṣa, ó sì já okùn ẹbí náà.
Ó wí pé òun Kemi ni bàbá òun fi hàn ayé bíi ààyò ọkàn rẹ̀ àmọ́ ohun tí ó fojú òun rí jìnnà réré sí ohun tó sọ fáyé. Ó wí pé bàbá òun lo òun bí omi òjò.
Kemi tẹ̀síwájú pé bàbá òun ṣe òògùn àfi bí Ẹ̀gbẹ̀jí, nígbà tí òun kojú rẹ̀ nígbà tí ó pé ẹni ọgọ́rin ọdún ni ó lọ sí ọ̀dọ Pásítọ̀ Adeboye pé òun fẹ́ yí padà.
Kemi wí pé gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1983 nígbà tí Victor Olunloyo pàdé Aderonke Omololu tí orúkọ bàbá rẹ̀ ń jẹ́ Sonaike níbi ìpolongo ìbò. Victor padà fẹ́ Ronke lé ìyá òun ní èyí tó mú kí ìyá òun ó bínú. Kemi fi ẹ̀sùn kan Ronke pé òun ló mú bàbá àwọn rin àwọn ìrìn òkùnkùn ní èyí tó fi bẹ̀rẹ̀ sí lo àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yọkọ̀ọ̀kan.
Títí di àsìkò yìí, àwọn ẹbí Olunloyo kò tíì fèsì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Kemi sọ yìí.
Nínú ọ̀sẹ̀ yìí kan náà ká gbọ́ pé olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ Diamond dágbére fáyé.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé: gPascal Dozie; ẹni tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ Diamond ti rèwàlẹ̀ àṣà. Ẹni ọdún márùndínláàdọ́rùn-ún ni Pascal lásìkò ikú rẹ̀.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ló túfọ̀ ikú rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtù, ọmọ Pascal tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Uzoma Dozie ló bu ọwọ́ lu ìwé ìtúfọ̀ náà. Ó kà báyìí pé ‘Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn àti ọpẹ́ fún Ọlọ́run la fi kéde ikú bàbá wa; Pascal Gabriel Dozie tó di olóògbé lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù Igbe, ọdún 2025.
Bàbá dáadáa ni bàbá wa, ó jẹ́ ọkọ rere, bàbá rere àti bàbá àgbà rere tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run, aya, àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ ló gbẹ̀yìn olóògbé’
Ó ṣe pàtàkì láti fi kún un pé Pascal ti fìgbà kan jẹ́ Alága ilé iṣẹ́ MTN.
Ìgbé ayé Pascal Dozie
Ọdún 1939 ni a bí Pascal ní abúlé Egbu, Owerri ní ìpínlẹ̀ Imo. Ìdílé ìjọ Àgùdà ni a bí Alùfáà Pascal sí, bàbá rẹ̀; Charles Dozie jẹ́ Àlùfáà ìjọ Àgùdà.
Ilé ìwé Our Ladies tó wà ní Emekuku ni Pascal ti kàwé, ọpọlọ rẹ̀ tó jí pépé ló jẹ́ kó ní àǹfààní àti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní London.
Àti London ló ti lọ sí UK lọ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, kò tán síbẹ̀ o, Pascal gba àwọn ìwé ẹ̀rí ní àwọn ilé ìwé gíga káàkiri.
Ìròyìn mìíràn tó tún ń jà ràìnràìn lórí afẹ́fẹ́ ni ti ìyá kan tí wọ́n pa ní ìpínlẹ̀ Anambra. A gbọ́ pé méjì nínú awon tó ṣe iṣẹ́ ibi náà ni ọwọ́ ti bà báyìí.
Arábìnrin ẹni àádọ́rin ọdún kan ni àwọn kan pa nípakúpa sórí oko rẹ̀ ní abúlé Ihiala, ìpínlẹ̀ Anambra.
Afurasí méjì ló ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ọjọ́ kejì, oṣù Igbe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí a rí gbà, àwọn ọ̀daràn náà so ìyá yìí lọ́wọ́ àti ẹ̀sẹ̀, wọ́n fi aṣọ díi lẹ́nu kí wọ́n tó pa á, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé ọ̀kadà rẹ̀ lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Anambra; Tochukwu Ikenga ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé ọmọ ìyá yìí rí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà pẹ̀lú ọ̀kadà ìyá rẹ̀ tó gùn ún kọjá lọ lọ́jọ́ náà gan-an, nígbà tó wá ríi pé wọ́n ti pa ìyá rẹ̀ ló fi dárúkọ ẹni tó rí náà bíi afurasí.
Ọmọ abulé Ihiala kan náà ni àwọn afurasí méjéèjì náà. Ọ̀kan ń jẹ́ Chidiebere Igboanugo nígbà tí èkejì ń jẹ́ Umunwaji Ogboro. Ọ̀kadà náà ṣì wà ní àkàtà Chidiebere tó ń gùn kiri. Nínú ìwádìí ni wọ́n ti dárúkọ Emmanuel Ibeabuchi, Alla àti Emeka pé àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni. Alla àti Emeka ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ nígbà tí Emmanuel náà ti wà nínú àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Ikenga wí pé àwọn afurasí náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́ láìpẹ́.
Discussion about this post