Lilian; ẹni ọdún mọ́kànlélógún tó sì jẹ́ ìyá àwọn ọmọ méjì ti gún ọkọ rẹ̀ pa nígbà tí wọ́n ń jà.
Òpópónà ijanpa ni Lilian ń gbé pẹ̀lú ọkọ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ọdún kẹrin rèé tó ti wà nílé ọkọ rẹ̀. Ọmọ méjì ni ó bí fún un.
Àlàyé tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé lọ́jọ́ náà, Lilian àti ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìjà, Lilian wí pé ọkọ òun ní òun kò fẹ́ òun mọ́ kí òun máa lọ tó sì tún fi ẹgba na òun, ìgbà náà ni òun wọ ilé ìdáná lọ mú ọ̀bẹ tí òun sì gún un pa.
Lilian ní òun fi ọ̀bẹ náà gbèjà ara òun nígbà tó ní kí òun máa lọ. Ó ní ọdún kẹrin rèé tí òun ti ń bá a gbé, ọkùnrin méjì ló bí fún un, àkọ́bí jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta nígbà tí èkejì jẹ́ ọmọ ọdún méjì.
Lọ́jọ́ Ajé tí ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀, Lilian wí pé ọkọ òun yan òun lódì, nígbà tó yá, ó ní kí òun ó máa lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀ òun pé òun kò fẹ́ ẹ mọ́, ọ̀rọ̀ náà di ìjà láàrin wọn, ó fi ẹgba na òun ó sì tún fọ́ orí òun mọ́ ògiri.
Ìbínú èyí ni òun fi lọ yọ ọ̀bẹ òun kò gbèrò láti pa á.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn tọkọtaya láti máa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó mú ìròyìn wá nípa irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí.
Ṣé ẹ rántí ọkúnrin kan tí wọ́n ń pè ní Doctor tó gún olólùfẹ́ rẹ̀ pa nítorí pé ó fura pé ó ní ọ̀rẹ́kùnrin mìíràn?
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ọkùnrin kan tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Doctor ni ó ti fi ọ̀bẹ gún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ pa nítorí pé ó fura pé ó ní ọ̀rẹ́kùnrin mìíràn.
Ima ni orúkọ ọ̀rẹ́bìnrin Doctor, ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ bíi ìjà nígbà tí Doctor kojú Ima pé ó ní ọ̀rẹ́kùnrin mìíràn, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà le tó fi di pé Doctor yọ ọ̀bẹ tó sì kì í bọ Ima níkùn.
Àwọn ará ilé wọn péjọ láti wo ìran ni kò sí ẹni tó gbìyànjú àti gbé Ima lọ sí ilé ìwòsàn títí tó fi da gbogbo ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ tán.
Alámòójútó ilé náà ló lọ fi tó àwọn ọlọ́pàá létí tí wọ́n sì wá mú afurasí ọ̀daràn náà.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers; Grace Iringe-Koko fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bright Edafe sọ, tọkọtaya ní láti kún fún sùúrù kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ó má bàa wáyé.
Ìjà lọ́kọláya náà ló ṣẹlẹ̀ láàrín tọkọtaya kan ní Èkìtì tí àwọn méjèèjì sì dèrò ọ̀run.
Báyìí ni ìròyìn náà ṣe lọ:
Tọkọtaya kan tí wọ́n ń gbé ní Ita-Eku ní igirigiri, Ado Ekiti tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ekiti ni wọ́n ṣá ara wọn ládàá pa ní òru ọjọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yìí.
Ọ̀rọ̀ náà ṣe àwọn ọmọ wọn gan-an ní kàyéfì, kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ó ṣe ṣẹ̀lẹ̀ nítorí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí.
Àkọ́bí wọn lọ́kùnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà pé bàbá àwọn dé ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́, ó ní òun kò le jẹun àyàfi bí ìyá àwọn bá dé.
Nígbà tí ìyá wọn dé, gbogbo wọn jọ jẹun, wọ́n gbàdúrà, bàbá wọn ka bíbélì sí wọn létí, gbogbo wọn sì wọ yàrá wọn lọ sùn.
Nígbà tó di òru ni àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró àdá láti inú yàrá bàbá wọn, títì láti inú ni ìlẹ̀kùn wọn wà, àwọn ọmọ bá lọ pe awon ará àdúgbò, nígbà tí wọn yóò fi dé, wẹ́lo ni yàrá náà kò sí ariwo kankan mọ́.
Àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò já ìlẹ̀kùn yàrá náà, òkú tọkọtaya ni wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpá àdá tó jinú lára wọn. Kódà, nǹkan ọmọkùnrin bàbá ti dá dúrò nílẹ̀; kò sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́.
Ohun tí wọ́n le sọ nípa ipò tí wọ́n bá wọn náà ni pé bóyá ìyàwó gé okó ọkọ rẹ̀ ni ọkọ náà bá kó àdá bò ó ni wọ́n bá ṣá ara wọn pa. Èrò lásán ni èyí, kò ṣojú ẹnìkankan.
Àwọn akọ̀ròyìn bi ọmọ náà léèrè pé ṣé àwọn òbí wọn máa ń jà tẹ́lẹ̀.
Ọmọ yìí fèsì pé ìjà kìí ṣe ohun titun nílé àwọn nítorí pé gbogbo ìgbà ni ìyá àwọn máa ń bá bàbá àwọn jà lórí ẹ̀sùn pé bàbá àwọn ń yan àlè.
Ó wí pé bàbá àwọn máa ń bá àwọn ṣeré dáadáa àmọ́ tí ìyá awo bá ti dé ni àyà rẹ̀ ó máa já. Ọmọ yìí wí pé bàbá òun sọ fún òun lọ́jọ́ kan pé ẹ̀rù ìyá òun ń ba òun.
Àmọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, ìjà ni àwọn ń retí bí ìyá àwọn ṣe dé àmọ́ ẹ̀rín àti ọ̀yàyà ni ìyá wọn bá wọlé, inú gbogbo wọn dùn láìmọ̀ pé gbẹgẹdẹ ó padà gbiná lóru.
Ọmọ mẹ́rin ló wà láàárín tọkọtaya yìí, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni àkọ́bí wọn, kò sí èyí tó tójú bọ́ nínú wọn.
Àwọn ará àdúgbò náà kín àlàyé tí ọmọ yìí ṣe lẹ́yìn. Wọ́n ní fádèyí olóró àdúgbò ni arábìnrin náà, gbogbo ìgbà ni ó máa ń bá ọkọ rẹ̀ jà, á wí pé ọkọ òun ń yan àlè.
Wọ́n ní ohun tó ṣẹlẹ̀ lóru ọjọ́ náà gan-an kò yé ẹnikẹ́ni tààrà nítorí pé wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí. Àwọn ará àdúgbò tilẹ̀ ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ̀ngbọ̀n nítorí pé ọlọ́pàá ni ọkùnrin náà kó tó kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.



