Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tó ń jà rànìnrànìn lórí ìtàkùn ayélujára pé agùnbánirọ̀ kan kú sí àgọ́ àwọn agùnbánirọ̀ látàrí ààrùn ibà lasa.
Akọ̀wé àtẹ̀jáde fún ẹ̀ka ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà; Saad Hamdalat ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé àhésọ ọ̀rọ̀ lásán ni ohun tí àwọn èèyàn ń gbé pòòyì ẹnu yìí, wọ́n ní kò sí koro kòkòrò ibà lasa ní ìpínlẹ̀ náà o kí àwọn èèyàn ó dẹ́kun àhésọ.
Wọ́n ní àwọn ti lọ ṣe àyẹ̀wò àyẹ̀wò àgọ́ náà fínní kò sì sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ àmọ́ ìyẹn kò ní kí àwọn ó má ṣe ètò rẹ̀ kalẹ̀. Wọ́n ní àwọn ti ṣe gbogbo ètò àti gbógun ti ibà náà bí ó bá tilẹ̀ yọjú àmọ́ ní báyìí ná, kò sí ohun tó jọ ọ́.
Ẹ̀ka ètò ìlera ṣe àlàyé pé agùnbánirọ̀ tó kú náà ní àìsàn nínú ara rẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni.
Wàyí o, ó ti ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Edo:
Ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ibà lasa ti bá àwọn lálejò báyìí ó sì ti mú àwọn èèyàn mẹ́fà lọ fọnná-fọnṣu.
Kọ́míṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà; Dọ́kítà Cyril Oshiomhole ló sọ èyí di mímọ̀ pé àwọn èèyàn mẹ́fà ló ti kú báyìí nípasẹ̀ ibà lasa. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ìwọ̀ òòrùn àti Estako àti ìwọ̀ òòrùn Esan ni àìsàn náà ti burẹ́kẹ.
Oshiomole ní àwọn ti ṣètò gbogbo àlàkalẹ̀ láti kojú àìsàn náà kí ó tó tàn kálùú. Ó fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò kojú rẹ̀ yóò si di ohun ìgbàgbé.
Ibà lasa yìí ń dá ẹ̀rù ba ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀, ìpínlẹ̀ Nasarawa ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ́ nínú hílàhílo àjákálẹ̀ rẹ̀ ni nígbà tó pa àwọn èèyàn mẹ́rin. A mú ìròyìn náà wá pé:
Kò dín ní àwọn èèyàn mẹ́rin tí wọ́n ti kú ní ìpínlẹ̀ Nasarawa pẹ̀lú àwọn àmì tó jọ ti ibà Lassa.
A gbọ́ pé ìjọba ti ti ilé ìwòsàn Awe wọ́n sì ti fi àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sí yàrá ìyàsọ́tọ̀ láti mọ̀ bí wọ́n bá ti kó ààrùn náà.
Ìdí ni pé ilé ìwòsàn náà ni àwọn ará àdúgbò gbé obìnrin kan lọ tó sì kú lẹ́yìn wákàtí díẹ̀. Àwọn àmì tí obìnrin yìí fi hàn fi ara pẹ́ ti ibà Lassa, èyí wọ́n ń gbìyànjú àti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ tí ọkọ rẹ̀ náà fi kú lọ́jọ́ kẹta pẹ̀lú àmì kan náà.
Adarí ẹ̀ka àjàkálẹ̀ ààrùn ní ìpínlẹ̀ náà; Ahmad Abdullahi bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà pé wọ́n fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ náà ni ó ṣe ń tàn báyìí.
Abdullahi wí pé àwọn fi ọkọ̀ ránṣẹ́ sí Awe láti kó àwọn mẹ́fà wá sí Lafia kí wọn ó fi wọ́n sí yàrá ìyàsọ́tọ̀ àmọ́ wọ́n sá lọ mọ́ wọn lọ́wọ́, èyí yóò mú kí ààrùn náà ó tàn kálẹ̀ báyìí.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà; Dọ́kítà Peter Awe ṣe àlàyé pé èsì àyèwò obìnrin tó kú náà fi hàn pé ó ní ààrùn ibà Lassa, yàtọ̀ sí ọkọ rẹ̀, àwọn méjì mìíràn ló tún kú tí àyẹ̀wò wọn sì fi hàn pé wọ́n ní ààrùn náà lára.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti wà ní Awe báyìí láti máa mú gbogbo ẹni tó bá fi àmì ààrùn náa hàn lọ sí yàrá ìyàsọ́tọ̀, àwọn mẹ́fà tí wọ́n sá lọ náà ni ó ń ba ìjọba lẹ́rù báyìí.
Ibà lasa ti ṣọṣẹ́ sẹ́yìn tó sì ti gba ọ̀pọ̀ ẹ̀mí, ìpínlẹ̀ Ondo kò le gbàgbé bọ̀rọ̀ ọṣẹ́ tí ibà náà ṣe níbẹ̀ lọ́dún 2025. Ìròyìn náà kà pé:
Kò din ni èèyàn méjìlá tí ibà LÁSÀ ti rán lọ sọ́run àpàpàǹdodo ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Èèyàn bíi mejìléláàádọ́fà ni ìjọba ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti lùgbàdì àìsàn náà, nígbà tí nnkan bí ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín méje èèyàn ló wà lórí akete àìsàn yíi.
Alábòójútó ètò ìsìrò bí nǹkan ṣe rí ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ nígbà tó ń bá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bójú tó Ìmọ́tótó ìlú, ní Akúrẹ́. Arákùnrin Àjàyí rọ àwọn òșìșẹ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò ìlera láti jẹ́ kí ayikà wọn mọ́ tónítóní láti lè kápá ìtànkálẹ̀ àrùn náà.
Ó fi yé wọn pé ìgbésẹ̀ kánkán gbọ́dọ̀ di gbígbé ní kíákíá. Bákan náà, alákòóso ètò ìlera ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó Ọ̀mọ̀wé Adenran Ikúòmọ̀la fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ bíi irínwó ni wọn ti fetí àwọn kọ́ látìgbà tí àìsàn yìí ti gbòde.
Ibà lasa ń gbérí lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ ààrùn onígbáméjì ṣọṣẹ́ tirẹ̀ darí, ìpínlẹ̀ Sokoto kò le gbàgbé bọ̀rọ̀ ọṣẹ́ tí ààrùn náà ṣe níbẹ̀ lọ́dún 2025. Ìròyìn náà kà pé:
Ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba Sokoto pawọ́pọ̀ láti dojú ìjà kọ ààrùn yìí kó le tètè kógbá wọlé.
Asabe kò ṣe aláìmámẹ́nuba àwọn àdojúkọ ẹ̀kà ètò ìlera. Lára àwọn àdojúkọ náà ni ipò tí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba wà, gbogbo ògiri ló ti dẹnu kọlẹ̀. Yàtọ̀ sí pé kò sí iná ọba láwọn ilé ìwòsàn náà, omi tí aláìsàn ó mu gan-an kò sí dépo ibùsùn tí yóò sùn lé. Èyí kò mọ́ pé àwọn nọ́ọ̀sì àti dọ́kítà kò pọ̀ tó, omi aláìsàn pọ̀ ju ọkà wọn lọ.
Pẹ̀lú gbogbo àwọn àdojúkọ yìí, Asabe ṣe ìlérí láti gbógun ti ààrùn onígbáméjì tó gbòde yìí ó sì rọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto láti wá nǹkan ṣe sí ipò àti àwọn àdojúkọ ilé ìwòsàn ìjọba gbogbo.
Gbogbo wa la mọ̀ pé ìmọ́tótó ló le ṣẹ́gun ààrùn gbogbo, ìjọba náà ní díẹ̀ nínú àwọn ààrùn tó gbòde yìí pàápàá ààrùn onígbáméjì.
Láti ìparí ọdún tó kọjá ni àwọn ará Èkó ti ń ké gbàjarè sí àjọ LAWMA láti wá nǹkan ṣe sí ilẹ̀ tó kún ojú pópó gèlètè:
Àwọn olùgbé àwọn agbègbè bíi Iyana-ipaja, Abule egba, Oṣodi, Iṣeri, Agege àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ti ké sí ilé iṣẹ́ kólẹ̀kódọ̀tí LAWMA láti wá kó àwọn ilẹ̀ tó ti di ẹ̀rìmọ̀ sí àwọn agbègbè náà. Wọ́n wí pé èyí le fa àjàkálẹ̀ ààrùn nítorí pé ó léwu fún ìlera.
Kunle Ayeni; ẹni tó jẹ́ olùgbé Igando wí pé ó ti lé ní oṣù mẹ́ta tí wọ́n ti wá kó ilẹ̀ agbègbè náà, gbogbo rẹ̀ ni ó ń mú òórùn burúkú jáde.
Yàtọ̀ sí pé ilẹ̀ ti gba ìdajì ọ̀nà, òórùn rẹ̀ kò sùnwọ̀n bí òjò bá rọ̀. Àwọn ará Igando kò le ṣí fèrèsé wọn, eeṣin ọdẹ ni yóò bá wọn lálejò. A ti sọ fún ọ̀gá LAWMA agbègbè wa àmọ́ wọn kò ṣe nǹkankan síi.
Deola Davies tí òun náà ń gbé ní Ìṣẹri ṣe àlàyé pé àwọn LAWMA kò wá gbé ilẹ̀ àwọn èèyàn ò sì yé da ilẹ̀ jọ síbẹ̀, àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ni yóò máa jẹ òórùn.
Funmi Adagba náà fi ẹjọ́ sùn pé ilẹ̀ ń bá ọkọ̀ du títì ni lágbègbè tirẹ̀ pẹ̀lú òórùn burúkú.
Àwọn èèyàn yìí wí pé oṣooṣù ni àwọn ń san owó ilẹ̀ fún ìjọba àmọ́ wọn kò wá kó ilẹ̀ náà mọ́. Bí àwọn bá fi le pa oṣù kan jẹ, wọn yóò wá ti ilé náà ni.
Esther Owobayi náà ṣe àlàyé pé ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ni wọ́n ń wá kó ilẹ̀ àdúgbò rẹ̀ báyìí n ígbà mìíràn oṣù méjì àmọ́ èyí kò dí owó wọn lọ́wọ́.
Funmilayo náà dá síi pé àwọn àjọ LAWMA náà ń hu ìwà ta ni yóò mú mi? wọn yóò há ìwé owó ilẹ̀ àmọ́ wọn kò ní wákó ilẹ̀ bí àwọn kò bá sì sanwo kíá ni wọn yóò wá ti ilé náà.
Wọ́n rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí èyí nítorí pé ó le fa àjàkálẹ̀ ààrùn.
Lóòótọ́ ni pé ààrùn náà kò tíì dé ìpínlẹ̀ Èkó, àmọ́ ó di dandan kí ìjọba ó wá ojútùú sí èyí kí ó má baà padà bẹ́ sílẹ̀.




