Lẹ́yìn gbogbo ìpàdé àti ìfikùnlukùn tó wáyé lórí fàǹfà tó wáyé nílé ìgbìmọ̀ aṣofin, àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti àwọn májẹ́óbàjẹ́ fẹnukò síbi pé kí Meranda ó fi ipò náà sílẹ̀. Mojisola Meranda gbà sí àwọn àgbà yìí lẹ́nu ó sì ti kọ̀wé fipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà sílẹ̀ báyìí.
Ọbasa kò yọjú síbi ìjọ́kòó náà àmọ́ ohun tí a ń gbọ́ ni pé òun ni yóò padà sí ipò náà.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin kan sárá sí Meranda fún ìwà akin yìí, wọ́n ní àkókò rẹ̀ kéré lóòótọ́ àmọ́ ó tu àwọn lára.
Aro Moshood; ẹni tó ń ṣojú ẹ̀kun Oṣòdì-Ìsọlọ̀ ló ṣíde oríyìn náà pé àsìkò Meranda gẹ́gẹ́ bíi agbẹnusọ jẹ́ àwòkọ́ṣe rere, ó wí pé Meranda kò woe ̣nu àáké rárá nígbà tí àwọn ogun náà dìde lọ́tùn-ún àti lósì.
Kehinde Joseph; ẹni tó ń ṣojú Alimosho apá kejì kín ọ̀rọ̀ Aro lẹ́yìn pé bí àsìkò rẹ̀ tilẹ̀ kéré, ipa tó kó kò ṣe é yára gbàgbé. Ó ṣe àpèjúwe Meranda gẹ́gẹ́ bíi akin lóbìnrìn, ó wí pé àwòkọ́ṣe ni ìṣe rẹ̀ jẹ́ fún àwọn tó ń bọ̀ lẹ́yìn.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ yóòkù náà ganu sí oríyìn yìí, wọ́n ní ó dàbí kó má kúrò nípò náà ni àmọ́ ẹgbẹ́ ló ṣe pàtàkì jùlọ.
Ajá kìí lọ kí kolokolo rẹ̀ ó gbélẹ̀, igbákejí Meranda; Mojeed Fatai àti ọlọ́pàá ilé náà; Sanni Okanlawon ti kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀ lónìí kan náà. Gbogbo àwọn tí wọ́n yàn pẹ̀lú rẹ̀ náà ti kọ̀wé fipò sílẹ̀.
Ṣé òótọ́ kọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Obasa sọ níjọ́ kìíní àná báyìí? Ṣé ẹ rántí pé ó sọ pé aṣọ tí Ìpìn bá bọ́ sílẹ̀, kò sí ẹni tó le gbé e wọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló wí pé láìkú ẹ̀gìrì, kò sí ẹni tó tó bẹ́ẹ̀ láti fi awọ rẹ̀ rán gbẹ̀du. Obasa tẹnumọ́ ọn nígbà náà pé òun ni agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ náà pé wọn ò tó òun yọ nípò náà.
Ó ti rí bẹ́ẹ̀ báyìí nítorí pé ní kété tí Meranda fi ipò agbẹnusọ sílẹ̀ tán ni Mudashiru Obasa wọlé, ojú ẹsẹ̀ náà ni wọ́n yàn án sípò agbẹnusọ padà tí wọ́n sì tún yan Meranda bíi igbákejì rẹ̀.
Meranda gbà láti jẹ igbákejì agbẹnusọ ilé, ó ṣe ìlérí pé òun yóò ṣe ojúṣe òun tọkàntọkàn láì figba kan bọ̀kan nínú.
Gbogbo wàhálà yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Meranda gorí àléèfà agbẹnusọ ilé ní ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Ṣẹẹrẹ, ọdún yìí. A mú ìròyìn náà wá fún yín pé
‘Agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Èkó; Mudashiru Obasa sọ̀rọ̀ ilẹ̀ kún lórí ìyọnípò rẹ̀.
Bí ẹ bá ń fọkàn bá wa lọ, ọ̀sẹ̀ tó kọjá la mú ìròyìn wá fún yín pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó yọ agbẹnusọ nípò wọ́n sì yan igbákejì rẹ̀ ní agbẹnusọ titun.
Mudashiru ti gbé ẹnu sí máíkì lórí ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó sọ náà ni pé òun ṣì ni agbẹnusọ ilé aṣòfin lábẹ́ òfin o, bí wọn ó bá tilẹ̀ yọ òun nípò, wọ́n gbọdọ̀ ti ẹsẹ̀ òfin bọ̀ ọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwàdà lásán ni wọ́n ń ṣe.
Obasa wí pé lábẹ́ òfin, dandan ni kí òun ó wà lórí ìjokòó bí wọ́n bá fẹ́ yọ òun nípò àbí ojú àwo ṣá ni àwo fi ń gba ọbẹ̀, ẹnìkan kìí sì fárí lẹ́yìn olórí, ó ṣe jẹ́ ìgbà tí òun lọ ìrìn àjò ni wọ́n yọ òun? Kò le ṣe é ṣe o.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀sùn tí ilé aṣòfin fi kan òun kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, òfûtùfẹ́tẹ̀ ásà tí ò ní káún nínú ni. Wọ́n ní òun fi bílíọ̀nù mérìndínlógún ṣe géètì, Obasa wí pé ṣé géètì Jẹ́ríkò ni géètì náà ni?
Wọ́n tún ní òun fi ogójì bílíọ̀nù ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì, Obasa wí pé kí ẹ má dá wọn lóhùn o, àwáwí ni wọ́n ń wá kiri.
Òní ni gbangba yóò dẹkùn tí kedere ó sì bẹ̀ẹ́ wò ní ilé aṣòfin Èkó, àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó yóò dìbò yọ Obasa nípò lónìí tàbí kí wọn ó dìbò yàn án sípò náà padà.
ÈTÒ ÀBÒ.
Àwọn akọ̀ròyìn kàn sí ọ̀gá ọlọ́pàá Èkó láti bèèrè àlàkalẹ̀ tó wà fún ìdìbò tí yóò wáyé ní ilé aṣòfin Èkó lónìí.
Ìdí ni pé àwọn olólùfẹ́ Obasa ti kóra jọ láti ṣe ègbè fún èèyàn wọn, bí ọ̀rọ̀ bá wá bẹ́yìn yọ, ṣé kò ní di rògbòdìyàn?
Ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Ishola Olawale ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá yóò fọ́n síta láti pa iná wàhálà, ó fi wá lọkàn balẹ̀ pé àwọn ọmọ ita tàbí àwọn jàǹdùkú kò le ṣe nǹkankan nítorí pé àwọn ọlọ́pàá yóò ká wọn lọ́wọ́ kò.
Olawale ṣe àfikún pé kò sí ohun tí kò le ṣẹlẹ̀ nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin o, nítorí pé àwọn kò lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ ibẹ̀ àmọ́ kò le sí rògbòdìyàn kankan ní ìgboro’
Lóòótọ́ lọ́jọ́ náà, kò sí wàhálà kankan nílùú, kódà gan-an lónìí tí wọ́n ṣe ìṣípòpadà náà, àwọn èèyàn ti rò pé kò ní rọgbọ àmọ́ wọ́rọ́wọ́ ni gbogbo rẹ̀ lọ létòlétò.
Lọ́jọ́ tí Obasa lọ kojú Meranda nílé ìgbìmọ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá náà kò mú wàhálà dání, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kó àwọn ẹ̀ṣọ́ Meranda kúrò lẹ́yìn rẹ̀ nígbà náà, síbẹ̀ kò jampata, kò bínú bẹ́ẹ̀ ni kò jà, oníwà tútù bí àdàbà.
Ṣé ẹ̀yin náà wá rí i báyìí pé àtàrí àjànàkú ni ẹrù ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin Èkó, kìí ṣe ẹrù tí Meranda le rù?
Obasa ti jéwọ́ ọ pé ẹ̀yìn òṣùgbó làá gbọ́kú Ẹdan. Ó di kóró, oyè náà kóólé Mudashiru ọmọ Obasa, tọ̀, oyè á mọ́rí o, àjẹgbó, àjẹtọ́!