Kayode Egbetokun; ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí ti kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Èrèlé.
Ilé iṣẹ́ ààrẹ ló fi èyí léde láti ẹnu olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí; Bayo Onanuga pé Kayode ọmọ Egbetokun kọ ìwé fipò rẹ̀ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀gá àgbà fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí nítorí pé ó nílò àkókò fún ètò ẹbí rẹ̀. Ó wí pé inú ilé Egbetokun kò tòrò lásìkò yìí ó sì nílò ọ̀pọ̀ àkókò láti tún inú ilé rẹ̀ ṣe ni ó fi fipò náà sílẹ̀.
Ohun tí Bayo Onanuga sọ yìí tako ọ̀rọ̀ tó lu síta lánàá pé ààrẹ ló pàṣẹ kí ó fipò náà sílẹ̀ níbi ìpàdé tó wáyé ní bùba ààrẹ lÁbùújá.
A yọ́ ọ gbọ́ níbi tí wọ́n ti ń yọ́ sọ ọ́ pé ààrẹ dìídì pe Egbetokun sí ìpàdé ní bùba rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé ni pẹ̀lú àwọn àṣàyàn Gómìnà lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ, níbi ìpàdé náà ni ààrẹ ti pàṣẹ kí Egbetokun ó fi ipò rẹ̀ sílẹ̀ kí ó máa lọ ná.
Nígbà tí yóò kúrò ní ilé ààrẹ lánàá, àwọn ẹ̀ṣọ́ DSS tú ọkọ̀ rẹ̀ fínnífínní, wọ́n yẹ̀ ẹ́ wò tónítóní kí ó tó lọ.
Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Egbetokun náà ni pé ètò ààbò ìlú yìí ti bàjẹ́ kọjá ààlà, ìpànìyàn lọ́tùn-ún, ìjínigbé lósì, wọ́n pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní Kwara, wọ́n kó àwọn ọmọ lọ ní Gombe àti Niger, ọ̀pọ̀ ló wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé tí wọ́n ń jìyà níbẹ̀, síbẹ̀ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò rí nǹkankan ṣe síi.
Ẹni tó joyè àwòdì yẹ kí ó le gbé adìyẹ ni ààrẹ fi ọ̀rọ̀ náà ṣe tó fi yọ ọ́ nípò.
Àmọ́ Bayo Onanuga wí pé Egbetokun fipò sílẹ̀ ni wọn kò yọ ọ́, ta ni kí a gbàgbọ́?

EDWARD LU ÒRẸ́BÌNRIN RẸ̀ PA NÍ ABIA.
Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Edward Okorie ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Edward àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ Sophy Chika ní gbólóhùn asọ̀, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń fà lọ́wọ́ mú inú bí Edward tó fi bẹ̀rẹ̀ sí ní lu Sophy tó sì lù ú pa.
ó ti lé ní ọdún mẹ́ta tí Sophy àti Edward ti jọ ń gbé ní ilé Edwad tó wà ní Isiugwu Ohafia, olólùfẹ́ ni àwọn méjéèjì, ìfẹ́ wọn sì lárinrin. Nọ́ọ̀sì ni Sophy, bó bá lọ sí ilé ìwòsàn tó bá dé, ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ni yóò darí sí.
Òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé tí Sophy ń múra ibi iṣẹ́ lọ́wọ́ ni òun àti Edward ní gbólóhùn asọ̀, ni Edward bá kìí mọ́lẹ̀ tó sì lù ú pa.
Edward ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí títí yóò fi fi ojú ba ilé ẹjọ́.
ÀWỌN GÉŃDÉ ỌKÙNRIN MẸ́TA KÚ SÍNÚ KÀNǸGA NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS.
Àwọn géńdé ọkùnrin mẹ́ta ni wọ́n kú sínú kànǹga kan ní ìlú Aminigboko níjọba ìbílẹ̀ Abua, ìpínlẹ̀ Rivers.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ni pé ẹni tó ni ilé náà ló gba àwọn mẹ́ta náà láti tún kànǹga ilé rẹ̀ gbẹ́ kí omi rẹ̀ le ṣe é mu.
Ẹni kìíní ló kọ́ fi okùn wọ inú kànǹga náà, nígbà tí wọn kò gbúròó rẹ̀ ni ẹnìkejì wọ inú kànǹga láti mú un jáde, ẹnìkejì náà kò jáde ni ẹnìkẹta náà bá kó sínú kànǹga láti wo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀.
Kò sí ẹni tó mọ̀ pé wọ́n ti kú sínú kànǹga náà títí ọjọ́ kẹrin lẹ́yìn tí òórùn gbalẹ̀ kan. Ìdí ni pé kò sí ẹni tó ń gbé ilé náà, wọ́n ti pa á tì tipẹ́ ẹni tó sì gbéṣẹ́ fún wọn náà kò sí níbẹ̀, ó kàn rán wọn lọ ṣe é ni.
Àwọn ará àdúgbò tí wọ́n ń gbọ́ òórùn ni wọ́n ké sí ilé iṣẹ́ panápaná, wàhálà díẹ̀ kọ́ ni wọ́n ṣe kí wọ́n tó rí àwọn mẹ́ta náà yọ.
Àyẹ̀wò fi hàn pé afẹ́fẹ́ gáàsì ń tú jáde nínú ilẹ̀ kànǹga náà, òun ni wọ́n fín símú tó ṣekú pa wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ilẹ̀ agbègbè náà kún fún afẹ́fẹ́ gáàsì àti epo rọ̀bì, ó rọ àwọn onílé láti máa gbé irú iṣẹ́ báyìí fún àwọn akẹ́ṣẹ́mọṣẹ́.

ÀWỌN PÁSÍTỌ̀ MẸ́FÀ ṢE AYÉDÈRÚ IṢẸ́ ÌYANU NÍ IDANRE, ONDO.
Àwọn pásítọ̀ mẹ́fà kan ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń fi ayédèrú iṣẹ́ ìyanu gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn ní Idanre, ìpínlẹ̀ Ondo.
Orúkọ wọn ni Fadahunsi, Kolade, Tijani, Iyanuoluwa, Arijesulola àti Ademola. Wọn yóò wọ àárín ìlú lọ tàbí àárín ọjà gẹ́gẹ́ bíi Òjíṣẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á ṣe ayédèrú iṣẹ́ ìyanu le.́yìn náà ni wọn yóò sọ fún àwọn èrò tó wá wòran wọn pé àwọn le tán gbogbo ìṣòro wọn.
Bí àwọn èèyàn bá ti wá lọ bá wọn ní bùba wọn, owó ribiribi ni wọ́n ń gbà lọ́wọ́ wọn tí ìṣòro wọn kò sì ní tán àfi bí yóò bá tún pọ̀ síi.
Àwọn kan nínú ìlú náà ni wọ́n ta àwọn ọlọ́pàá lólóbó pé gbọnmọgbọnmọ àwọn èèyàn náà ń pọ̀ jù, gbogbo ará Idanre ló ń kó owó lọ fún wọn láìní ìdí kan pàtó. Èyí làwọn ọlọ́pàá gbọ́ tí wọ́n fi lọ kó wọn ní pápámọ́ra, wọ́n fi èsùn jìbìtì lílù kàn wọ́n àti ìtannijẹ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń ṣe ìwádìí iye àwọn èèyàn tó ti lùgbàdì wọn àti iye tí wọ́n ti pàdánù sí ọwọ́ wọn kí àwọn ẹni náà tó fi ojú ba ilé ẹjọ́.




