Ògbójú lọ́ọ́yà nì, akọ níwájú adájọ́ àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn-annì, Fẹ́mi Fálànà ti gbá ogun jọ láti gbé Babangida relé ẹjọ fún ìwà ìkà àti ìwà òdóró tó hù sí wọn nígbà tí Babangida fi jẹ́ olórí ìjọba ológun. Tí a ò bá gbàgbé, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí ìjọba ológun ìgbà náà, lábẹ́ ìdarí Ibrahim Babangida, tí wọ́n fagi lé ìbò ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà ọdún 1993 tó gbé M. K. O. Abíọ́lá wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tí a dìbò yàn nígbà náà. Lójijì ni ìjọba ológun fagi lé èsì ìbò náà.
Àwọn ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn lóókọ-lóókọ ; àwọn Amòfin tí wọ́n tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, ló gbójú agan sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Lára wọn ni Fẹ́mi Fálànà ; Olóyè Gani Fawehinmi; Sẹnetọ Bọ́lá Tinubu ( tó ti di Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí báyìí). Kí a tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́ nígbà náà, ìjọba ológun ti fi pańpẹ́ ọba gbé àwọn márùn-ún kan. Nínú wọn ni Fẹ́mi Fálànà àti Gàní Fawehinmi wà.
Ìjọba ológun ìgbà náà fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ta ko ìjọba , wọ́n sì ń gbó ìjọba lẹ́nu lórí ìpinnu ìjọba láti fagi lé ìbò náà tí Olóyè MKO Abíọ́lá ti jáwé olúboorí.
Fálànà sọ pé mímú tí ìjọba mú wọn, tó tì wọ́n mọ́lé lòdì sí òfin, ó ní èyí jẹ́ jẹ́ ọ̀nà láti pòkóò mọ́ wọn lẹ́nu. Șé wọ́n ní abòkò ìrẹ̀ kì í ráhùn pẹ́ títí, bó bá yá, yóò donígba aṣọ. Báyìí òún( Fẹ́mi Fálànà) ti ṣe tán, òún sì ti kó àwọn Ògbójú lọ́ọ́yà tí wọ́n dá lẹ́nu, dá létè, tí wọ́n sì dá nitọ́ jọ láti béèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ìwà ọ̀dàlẹ̀, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìpani-lẹ́nu-mọ́ tí Babangida hù nígbà náà.
Nígbà tí onípañla Babangida sì ti wáá jẹ́wọ́ báyìí pé òún rò pé èèpo igi ni, tó sì lóun kábàámọ̀, ni Fálànà ní kí aráyé wo ọsẹ́ àti ìdààmú, ìjákulẹ̀ àti ìfòòró-ẹ̀mí táwọn ní láti bí ọdún mejìlélọ́gbọ̀n sẹ́yìn.
Ó rántí bí Babangida ṣe kó òun àti àwọn akẹgbẹ́ òun lọ sí kóòtù ní Gwagwalada, tí wọ́n sì fẹ̀sùn ìdìtẹ̀ kàn wọ́n. Wọn ò tún jẹ́ kí wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba agbẹjọ́rò tó lè jà fún wọn, ìjọba ológun ìgbà náà ní káwọn fúnra wọn máa gbẹ́ èèkù ìdí ara wọn.
Àmọ́ ní báyìí, Kannakánná ti na ọmọ ẹ̀gà, ìjá ń bọ̀, ìjá náà ti dé báyìí. Àwọn tọ́rọ̀ọ́ kàn ti tutọ́ sókè, wọ́n yarí pé àkókò tàwọn rèé láti béèrè ikú tó pa bàbá wọn lọ́wọ́ oníkùùmọ̀ ìkà.
Láti ìgbà tí Babangida ti gbé ìwé náà jáde ni onírúurú àwọn èèyàn àti ikọ̀ ti ń sọ èrò wọn, àwọn tó tàbùkù Babangida lórí àwọn ìwà tó hù nígbà náà pọ̀ ju àwọn tó gbé oriyin fún un lọ.
Àjọ MURIC gan-an ganu sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n wí pé Ọ̀gágun IBRAHIM BABANGIDA ló gba adé ìdàború ti ọdún JUNE 12 1993. Bí ẹ ò bá gbàgbé, ọjọ kejilá, oṣù kẹfà ọdún 1993 ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ètò ìdìbò tó yanrantí jùlọ, gbogbo ọmọ Nàìjírà ló pawọ́pọ̀ dìbò yan Olóyè MOSHOOD KÁṢÌMAAWÒÓ ABÍỌ́LÁ lọ́dún náà lọ́hùn-ún sí ipò Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà.
Inú gbogbo ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà dùn yùngbà pé ìdẹ̀ra dé é , a bọ́ lóko ẹrú ológun.
Abẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú SDP; ìyẹn ẹgbẹ́ ẹlẹ́ṣin ni Olóyè Moshood Káṣìmáàwòó Abiola ti jáwé olùborí. Orín ẹ̀yẹ orílẹ̀ èdè wa ló dédé gbòde kan lórí rédíò àti ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Págà! Ìlù yí padà, orin ọ̀tẹ̀ bẹ̀rẹ̀, Ìjọba ológún IBRAHIM BABANGIDA ti dójú ìbò délẹ̀, ó fagilé ibò JUNE 12 1993, ni yánpọnyánrin bá bẹ̀rẹ̀. Ààrẹ SANNI ABACHA dìtẹ̀ gba ìjọba, Olóyè MOSHOOD KAṢIMAWÒÓ ABIOLA dèrò ẹ̀wọn, Akínkanjú Ayà rẹ̀, KUDI ABIOLA dolóògbé látàrí ìjà-n-gbara pé kí ọkọ rẹ̀ le è dórí alééfà tí gbogbo ìlú fọwọ́ sí fún un.
Lẹ́yìn ikú Ààrẹ SANNI ABACHA lọ́dún 1998 ni MKO náà di olóògbé tí àlá rẹ̀ kò si fi bẹ́ẹ̀ wá sí ìmúṣẹ. Ní báyìí, Ààrẹ àná, IBRAHIM BABANGIDA ti gbé ìwé kan jáde lẹ́yìn ọgbọ̀n ọdún lé méjì tí ó fi lọ́lẹ̀ lọ́jọ́ kọkànlélógún oṣù yìí, Àkọ́lé ìwé náà ni: ÌRÌNÀJÒ MI LẸ́NU IṢẸ́. TRANSCORP HILTON tó wà ní olú ìlú ilẹ̀ Nàìjíríà ni àwọn ọ̀tọ̀kùlú ilẹ̀ wa péjú-pésẹ̀ sí fún ìfilọ́lẹ̀ ìwé Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA lọ́jọ́bọ ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Bílíọ́nù mẹ́tàdínlógún ni wọ́n fi ṣíde ìwé náà. Gbogbo àwọn èèyàn jànkànjànkàn, olóṣèlú àti ọ̀tọ̀kùlú ló wà ní ìkàlẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá. Ibi ayẹyẹ ìfisọrí ìwé ni Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA ti jẹ́wọ́ pé òun ló ṣe atọ́nà àti màdàrú bí àjọ ètò ìdìbò ìgbà náà, FEDECO fi fagilé ìbò tí gbogbo ọmọ Nàìjíríà gbà pé ó yanrantí jùlọ nílẹ̀ yìí, IBRAHIM BABANGIDA kò fa ẹni tá a fìbò yàn kalẹ̀, ìyẹn Olóyè MOSHOOD ABÍỌ́LÁ KÁṢÌMAWÒÓ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ titun nígbà náà, ó dojú ìbò ọdún JUNE 12 1993 dé porongodo.
Lọ́jọ́ ìsinmi tó kọjá, ọjọ́ kẹtàlá oṣù yìí ni ọ̀gá àgbà àti olùdarí ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn Mùsùlùmí ilẹ̀ Nàìjíríà, Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA kéde pé òun tako bí Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA ti jẹ́wọ́ ìfagílé ìdìbò JUNE 12 1993.
Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní kí IBRAHIM BABANGIDA má fi búrẹ́dì kówa lọ́bẹ̀ jẹ nítorí ẹni tí adé ìwà ìbàjẹ́ náà ṣímọ́ lórí jù ni ọ̀gágun SANNI ABACHA fún ìfagilé ètò ìdìbò JUNE 12 1993.Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOL
A ní kí gbogbo ọmọ ilẹ̀ yìí máa ṣe ìrántí Akọni olóyè MKO ABIOLA, aya rẹ̀; KUDIRAT ABIOLA àti ALFRED REWANE. Ọ̀jọ́gbọ́n tún ké tantan sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti má ṣe gbàgbé ọgbẹ́ ọkàn àti ìfẹ̀tọ́-ẹni-dunni tí ètò ìdìbò JUNE 12 1993 dá sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní àṣìṣe ìtàn ni èyí àti pé Ààrẹ BABANGIDA IBRAHIM ń gé ìka àbámọ̀ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìdìbó JUNE 12 1993, Ó ní SANNI ABACHA ló lo ọwọ́ agbára gẹ́gẹ́ bí ipò rẹ nígbà náà láti dojú ìbò JUNE 12 1993 bolẹ̀. Àwọn èrò wọnyìí ló mú Ọ̀jọ̀gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA rú láti fẹ́ tún ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ kọ, ọ̀jọ̀gbọ́n ní ọgbọ́n àrékérekè láti wẹ ara rẹ̀ mọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ ọjọ́ pípẹ́ náà ni èyí. Ọ̀jọ̀gbọ́n nà ìka àbùkù sí Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA fún dída omi àlàáfíà ilẹ̀ Nàìjíríà rú láti ọjọ́ pípẹ́, Ó ní Ààrẹ kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ní àlá rere sí ètò ìdìbò ilẹ̀ yìí mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti fojú winá ìfagilẹ́ ètò ìdìbò JUNE 12 1993 tí gbogbo àwọn ènìyàn gbà pé òunni ètò ìdìbò tó yanrantí tó sì pegedé jùlọ, Olóyè MKO ABIOLA ló jáwé olúborí ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe màdàrú rẹ̀, wọ́n fi ọwọ́ ọlá gbá ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà lójú, wọ́n sì da ètò ìdìbò JUNE 12 1993 rú porongodo.
Ẹgbẹ́ MURIC tún bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ọ̀tọ̀kùlú èèyàn jànkànjànkàn ilẹ̀ yìí ti ṣùgbá ìwà láabi àti ìdọ̀tí tó kún inú ìwé náà, tí wọ́n sì ń gbé e gẹ̀gẹ̀ bí ohun rere kan báyìí. Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu tó fi igi gún egbò ọjọ́ pípé àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùfọkànsìn ilẹ̀ yìí nítorí ṣe là ń gbé ẹni ibi gẹ̀gẹ̀ tá a wá sọ ọ́ di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ.
Àjọ MURIC na ìkà àbùkù bá Ààrẹ IBRAHIM BABANGIDA nítorí ìjọba rẹ̀ ló fi ilẹ̀ Nàìjíríà sí oko gbèsè ọdúnmọ́dún, ìjínigbé, ìpayínkeke, ìdàrúdàpọ̀, ìfẹ̀tọ́ọ́mọnìyàn-dunni, ìjíàpótí-ìdìbò-gbé, ikú oró, dídu oyè olóṣèlú tí kò tọ́ sí ni, fífi ìyà jẹ àwọn aláìṣẹ̀ lọ́nà àìtọ́ abbl.
Ọ̀jọ́gbọ́n ISIAQ AKINTOLA ní kí gbogbo ọmọ ilẹ̀ yìí máa ṣe ìrántí Akọni olóyè MKO ABIOLA, aya rẹ̀; KUDIRAT ABIOLA àti ALFRED REWANE. Ọ̀jọ́gbọ́n tún ké tantan sí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti máa ṣe gbàgbé ọgbẹ́ ọkàn àti ìfẹ̀tọ́-ẹni-dunni tí ètò ìdìbò JUNE 12 1993 dá sílẹ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ní báyìí, Falana ṣetán láti gbé Babangida relé ẹjọ́, àjọ MURIC ṣetán láti gbógun tíì, ẹ̀yin ọmọ Nàìjíría, kí lẹ máa ṣe sí èyí?