Ilé ẹjọ́ tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ekiti ti pàṣẹ kí Joy Ikoja ó lọ rọ́kún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó fa ẹpọ̀n ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Ẹni ọgún ọdún ni Joy Ikoja, a kò tíì le sọ pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀; Ibrahim Usman tó fi fi abẹ fa ẹpọ̀n rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Ọjọ́ ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí ni Joy fi ojú ba ilé ẹjọ́, ẹjọ́ náà kò le parí lánàá náà fún àwọn ìdí tó pọ̀ ni adájọ́ bá pàṣẹ kí wọn ó fi Joy sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Ado-Ekiti títí di ọjọ́ kejìlélógún, oṣùn yìí.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ gbìyànjú láti rọ ilé ẹjọ́ pé kí wọn ó gba onídùúró rẹ̀ kí ó le máa gba ilé wá jẹ́jọ́, ó wí pé afurasí náà kò mọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn náà.
Adájọ́ Olatomiwa Daramola fagi lé ẹ̀bẹ̀ agbẹjọ́rò Joy ó sì pàṣẹ kí wọn ó mú un lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ado-Ekiti títí di ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀.
LÁÀFIN ỌYỌ́:
ALÁÀFIN YAN OSUNTOLA NÍ OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ.
Aláàfin Ọ̀yọ́; Ọba Akeem Abimbola Owoade ti yan olùbádámọ̀ràn p̀àtàkì àti olórí òṣìṣẹ́ titun.
Rotimi Osuntola; ẹni tó jẹ́ olórí òṣìṣẹ́ fún Aláàfin Owoade tẹ́lẹ̀ ló fi àtẹ̀jáde kan léde láàárọ̀ àná. Nínú ẹ̀ la ti kà á pé Aláàfin Owoade ti ṣe àgbéga fún Osuntola láti ipò olórí òṣìṣẹ́ sí ipò olùbádámọ̀ràn pàtàkì nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Bayo Ajibade yóò di ipò olórí òṣìṣẹ́ mú báyìí.
LÁTI ILÉ IṢẸ́ ỌLỌ́PÀÁ:
A TI ṢE ÌDÁMỌ̀ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TÓ GBA OWÓ LỌ́WỌ́ ARÁ CHINA NÁÀ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìdójútì tí àwọn ọlọ́pàá kan hù nínú fọ́nrán kan tó gbòde ní èyí tí ọmọ orílẹ̀-èdè China kan ti ń há owó fún wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé gbogbo àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n hàn nínú fọ́nrán náà ni àwọn ti ṣe ìdámọ̀ wọn lọ́kọ̀ọ̀kan tí àwọn yóò sì ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí; Olumuyiwa Adejobi bu ọwọ́ lù la ti kàá pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ́ ẹ̀ka kan tó ní iyì àti òtítọ́, wọ́n ní àwọn kìí ṣe alábòsí tàbí alábọ̀dè, ìgbẹ̀kẹ̀lé tí àwọn èèyàn ní nínú àwọn kò gbọdọ̀ já sófo.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ọlọ́pàá tí a rí nínu fọ́nrán náà ti lòdì sí ohun tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wà fún, ìwà náà jẹ́ ìwà ìdójútì ńlá nítorí náà, wọn yóò jẹ́ jìyà ohun tí wọ́n ṣe yìí.
Wọ́n ní àwọn ti kó àwọn ọlọ́pàá náà lọ fún ìjìyà wọn báyìí pé èyí yóò jẹ́ kí wọn ó mọ̀ pé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ṣe é tàbùkù. Wọ́n kọ láti sọ irú ìjìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn ọlọ́pàá náà nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bèèrè.
NÍ OLÚ ILÚ WA ABUJA:
ỌMỌ ÒÒJỌ́ NI WỌ́N GBÉ JÙNÙ NÍ ABUJA.
Níbi tí àwọn kan ti ń fojú ṣògbérè àìríbí àti àìrípọ̀n ni ẹni kan ti bí tirẹ̀ tán tó sì gbé e jùnù.
Ọmọ titun jòjòló kan kódà ìwọ́ rẹ̀ ṣì tùtù mìnì jọ̀jọ̀ síbẹ̀ ni wọ́n ri nínú páálí níbi tí ẹni náà gbé e jùnù sí.
Agbègbè Jikoko ní Mpape, Abuja ni wọ́n ti jí rí ọmọ náà láàárọ̀ yìí. Àwọn abiyamọ wí pé ọmọ náà kò tíì lo tó odidi ọjọ́ kan láyé, àṣẹ̀ṣẹ̀bí titun ni.
Aliyu, ọ̀kan nínú àwọn ará àdúgbò náà wí pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí ọmọ náà nínú páálí nígbà tí àwọn jí láàárọ̀ ọjọ́ Ajé.
Ojú ọ̀ná ilé ọ̀sìn adìyẹ tó wà ní Jikoko ni wọ́n gbé ọmọ náà sí. Àwọn ará àdúgbò kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kí wọ́n tó gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ ẹni tó bí ọmọ náà àti ẹni tó gbé e jùnù.
NÍPA INÁ ỌBA I:
Ó TI LÉ NÍ ỌDÚN MẸ́TA TÍ A TI GBÁDÙN INÁ ỌBA GBẸ̀YÌN – ÀWỌN ARÁ APẸTẸ.
Àwọn ará Apẹtẹ ní Ibadan tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti tú jáde láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí iná mọ̀nàmọ́ná tó ń fòní kú fọ̀la dìde bíi ti akúwárápá.
Wọ́n ní ọdún kẹta rèé tí àwọn ti gbádùn iná ọba gbẹ̀yìn. Oríṣìí àkọlé ni wọ́n gbé lọ́wọ́ ní èyí tí wọ́n fi kọ ẹ̀dùn ọkàn wọn sí.
Ọ̀kan lára wọn tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Victor bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ni àwọn máa ń ní iná kìí sì í lò ju ìṣẹ́jú márùndínláàdọ́ta lọ, ó tún di ọ̀sẹ̀ míì. Dimeji náà wí pé ṣégeṣège iná yìí kò dí owó gọbọi tí wọ́n ń mú wá fún wọn lọ́wọ́, oṣooṣù ni wọ́n gbé ìwé owó iná ká wọn mọ́lé. Dimeji wí pé ìyànjẹ gbáà ni èyí.
Dimeji tẹ̀síwájú pé àwọn apá ibìkan ní Apẹtẹ máa ń ní iná déédéé nígbà tí àwọn apá yòókù kìí ní iná rárá.
Ọ̀gá ọlọ́pàá Apẹtẹ; Ọ̀gbẹ́ni Hakeem Ayodeji fèsì pẹ̀lú fọ́nrán kan tó fi léde pé kí àwọn èèyàn náà ó ṣe ìwọ́de náà ní ìrọwọ́rọsẹ̀ kí wọ́n má jẹ́ kí àwọn jàǹdùkú ó já a gbà mọ́ wọn lọ́wọ́.
NÍPA INÁ ỌBA II:
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé éégún ló ṣaájú ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara lọ́sẹ̀ yìí.
Àwọn ará Omu-Aran ní ìjọba ìbílẹ̀ Irepodun, ìpínlẹ̀ Kwara ni wọ́n tú yáyá tú yàyà jáde láti ṣe ìwọ́de tako iná ọba tó gbówó lérí geregere.
Oríṣìí akọ́lé ló wà lọ́wọ́ wọn, lára àwọn tí a rí kà ni pé kí ilé iṣẹ́ IBEDC ó dá àwọn padà sí ìpele C, wọ́n láwọn ò fẹ́ ìpele A mọ́.
Wọ́n ní iye tí wọ́n mú wá fún ilé kọ̀ọ̀kan bíi owó iná oṣù Ẹrẹ́nà lé ní ẹgbẹ́rùn lọ́nà ọgọ́rùn-ún náírà láti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà tí àwọn ń san tẹ́lẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n kọ àwọn ọlọ́pàá tó fẹ́ tẹ̀lé wọn, wọ́n láwọn ò nílò ààbò ọlọ́pàá níbi ìwọ́de náà.
Discussion about this post