ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Ìròyìn Agbègbè

ÌYÀWÓ ILÉ KAN JÍ ARA RẸ̀ GBÉ NÍ ÈKÓ.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
December 21, 2025
in Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
13
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ obìnrin kan tó ṣètò bí ó ṣe jí ara rẹ̀ gbé pẹ̀lú ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sì gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.
Orílẹ̀-èdè South Africa ni ọkọ obìnrin yìí ń gbé, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Bélú ni ó pe ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà pé wọ́n ti jí ìyàwó òun gbé, ó ní òun ti san mílíọ́nù mẹ́ta náírà owó ìtúsílẹ̀ àmọ́ wọn kò fi sílẹ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bá ta mọ́ra, wọ́n kò sí ìwádìí, ṣàdédé ni obìnrin náà dé sílé tó ní wọ́n dá òun sílẹ̀.
Obìnrin yìí ṣe àlàyé pé àwọn ajínigbé dá òun lọ́nà, mẹ́fà ni iye wọn pẹ̀lú ìbọn lọ́wọ́, ó ní wọ́n gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun olówó iyebíye iphone 12promax. Ó ní inú àpò owó òun ni ọkọ òun san owó ìtúsílẹ̀ náà sí tí òun sì tari rẹ̀ sínú àpò owó àwọn ajínigbé.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àlàyé tí obìnrin yìí ṣe kò bára mu, wọ́n ṣe ìwádìí nọ́ḿbà tí wọ́n fi bá ọkọ sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì Whatsapp.
Ẹdẹ ni ẹni tó ni nọ́ḿbà náà wà, àwọn ọlọ́pàá lọ gbé e ó sì jẹ́wọ́ pé ọ̀rẹ́ òun náà tọrọ láti fi nọ́ḿbà òun ṣí ìkànnì Whatsapp òun sì fi òǹkà OTP ránṣẹ́ síi, ó ní òun kò mọ ohun tí ó fẹ́ fi ṣe.
Bákan náà ni wọ́n tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ iphone 12pro max dé ọwọ́ ọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n kan, ó ṣe àlàyé pé òun ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ obìnrin náà ní ọ̀rìnlélọ́ọ̀dúnrún ẹ̀gbẹ̀rún náírà #380,000 pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí òun má tan ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní obìnrin náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí ìwádìí bá parí. Wọ́n rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún ìwà ọ̀daràn.

ỌKỌ̀ TẸ AGBÁLẸ̀ TÍTÌ KAN PA NÍ MEIRAN, ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.

Ọkọ̀ akérù aládàáni kan ti tẹ obìnrin kan tó ń gbá ilẹ̀ ojú títì pa ní ìyànà Ẹkọ̀rọ̀ ní Meiran, ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé obìnrin náà ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ ni ọkọ̀ Ford náà fi ẹ̀yìn rìn tó sì kọlù ú, kò tún dúró lẹ́yìn tó kọlu obìnrin yìí, ó fi ẹ̀yìn gun orí àti apá rẹ̀ mọ́lẹ̀ ó sì ní sá lọ bẹ́ẹ̀.
Àwọn èèyàn ló gbé ọ̀kadà tẹ̀lé e tí wọ́n sì mú un, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ pa á ni àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ló gbà á kalẹ̀ tí wọ́n sì mú un lọ sí àgọ́ wọn.
Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ LASTMA ṣe àlàyé pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ nígbà tí àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà.
Wọ́n pe àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Meiran mọ́ra, wọ́n fa awakọ̀ náà lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ wọ́n sì gbé òkú obìnrin náà lọ sí ilé ìgbókùúsí.
Olalekan Bakare-Oki; ẹni tó jẹ́ adárí àjọ LASTMA bá àwọn ẹbí obìnrin náà kẹ́dùn, ó gbà á ládùúrà kí Ọlọ́run ó fún wọn ní ìlọ́ra lórí ọ̀fọ̀ náà.
Olalekan bu ẹnu àtẹ́ lu fífi ẹ̀yìn ọkọ̀ rìn lójú pópó, ó ní ó lòdì sí òfin ìwakọ̀ tí ìjọba bu ọwọ́ lù lọ́dún 2018.
Bákan náà ló gbé oríyìn fún àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò lórí bí wọ́n ṣe mú awakọ̀ náà.

IGBÁKEJÌ KỌMÍṢỌ́NÀ ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ EBONYI TI DÁGBÉRE FÁYÉ.

Inú ìpàdé ni ọ̀gbẹ́ni Ogbon-inu Taiwo Popoola wà ní Abakaliki tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ebonyi nígbà tó múdìí lọlẹ̀ lójì tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ṣe àlàyé pé Popoola ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ni èémí rẹ̀ ṣàdédé ń lọ sókè sílẹ̀ tó sì múdìí lọ sí ilẹ̀. Wọ́n ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn ọlọ́pàá Abakaliki àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró, eléérú sungi fún ọkùnrin náà.
Ohun tí wọ́ fura pé ó ṣe okùnfà ikú rẹ̀ sí àárẹ̀ ọkàn tó níí ṣe pẹ̀lú ìpayà.
Wọ́n ní Popoola kò ṣe àìsàn ṣáájú ìpádé náà, àárín ìpàdé náà ni ó bẹ̀rẹ̀ tó sì mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ.

AFURASÍ JẸ́WỌ́ ÌDÍ TÓ FI PA ADÁJỌ́ FẸ̀YÌNTÌ IFEOMA OKOGWU.

Afurasí tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ lórí ikú tó pa adájọ́ fẹ̀yìntì Ifeoma Okogwu jẹ́wọ́ pé nítorí ẹ̀rọ ìbanisọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ohun ìní mìíràn ni àwọn ṣe pa Ifeoma.
Godwin Mngumi ṣe àlàyé pé òun pe àwọn méjì mìíràn mọ́ra láti gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Ifeoma, aago ọwọ́, ohun ọ̀ṣọ́ àti ẹ̀rọ agbanápamọ́ rẹ̀. ó ní àwọn kò lérò láti pa obìnrin náà àmọ́ ó kú mọ́ àwọn lọ́wọ́ ni.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Godwin, kò ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ tí Ifeoma gbà á ní aṣọ́gbà ni ó pa á. Ó ṣe àlàyé pé àwọn so ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Ifeoma méjéèjì sẹ́yìn, wọ́n kó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ méjéèjì. Nnaji Obalum ló gba ọ̀kan nínú rẹ̀ sọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ta èkejì.
Obalum; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ṣe àlàyé pé òun fi síìmù òun sínú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà ni wọ́n fi mú òun. Obalum àti Godwin kábàámọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì tọrọ àforíjìn.
Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ló fi fọ́nrán ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àwọn afurasí ọ̀daràn náà léde.

ADVERTISEMENT

ADVERTISEMENT

ỌWỌ́ TẸ ỌKÙNRIN KAN TÓ YÌNBỌN FÚN ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ NÍ IBÙDÓ WỌN.

Mẹ́ta ni àwọn ọkùnrin náà lórí ọ̀kadà, kò sí ẹni tó mọ ibi tí wọ́n ti ń bọ̀ tàbí lọ àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibùdó àyẹ̀wò awọn ọlọ́pàá tó wà ní Ipele, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ní ìpínlẹ̀ Òǹdó, wọ́n síná ìbọn mọ́ àwọn ọlọ́pàá náà àwọn náà sì dá a padà.
Ọlọ́pàá méjì àti obìnrin kan tó ń kọjá lọ ni ìbọn bà, wọ́n ṣe aájò wọn lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tí ọwọ́ tẹ ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nwabali àti ọ̀kadà tí wọ́n lò náà.
Abayomi Jomoh; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ṣe àlàyé pé nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀. Taiwo ni orúkọ obìnrin tí ìbọn bà náa, ó ti wà ní ilé ìwòsàn pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá méjì tí ìbọn bà náà.
Wọ́n ní Nwabali yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́yìn tí iwádìí bá parí.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeedbreaking newsbreakingnewsgoviralÌròyìnÌròyìn Tó GbòdeiroyintogbodeIwe Iroyin Yorubanewsnewsinyorubanewsonlinenewsupdatesharesharenewstredingnewstrendingpostsupdate
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA KÚ SÍNÚ GBỌ̀NGÀN ÌDÁNWÒ.

AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA KÚ SÍNÚ GBỌ̀NGÀN ÌDÁNWÒ.

Recommended

TUFACE RA ÀWỌN AṢỌ TITUN FÚN ÌFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA

TUFACE TI RAWỌ́ Ẹ̀BẸ̀ O, Ẹ JÈBÙRẸ́ Ẹ̀YIN ÈÈYÀN.

11 months ago
Ó TÓ GẸ́Ẹ́, ÈYÍ TÍ NNAMDI KANU ṢE L’Ẹ́WỌ̀N TÓ

Ó TÓ GẸ́Ẹ́, ÈYÍ TÍ NNAMDI KANU ṢE L’Ẹ́WỌ̀N TÓ

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.