Ìyá ọmọ titun bu dọ́kítà so lórí ọmọ ìbejì; Fọ́nrán kan ti gba orí ìtàkùn ayélujára kan nínú èyí tí a ti rí obìnrin kan tó bímọ àti àwọn ẹbí rẹ̀ tí wọ́n bu dọ́kítà tó gbẹ̀bí so pé kí ó gbé ọmọ kejì kalẹ̀. Ẹ̀sùn tí obìnrin yìí àti àwọn ẹbí rẹ̀ fi kan dọ́kítà náà ni pé ó jí ọ̀kan gbé nínú ọmọ ìbejì tí obìnrin náà bí ó sì gbé ọ̀kan kalẹ̀.
Obìnrin yìí dúró lórí pé ọmọ méjì ni ó wà nínú ikùn òun nígbà tí òun ya àwòrán oyún náà àmọ́ ọmọ kan ni dọ́kítà gbé kalẹ̀ nígbà tó bímó tán.
Ọ̀rọ̀ náà ti dé etí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, àlàyé tí a rí gbà ni pé ilé ìwòsàn Tip Top ní Ikotun ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹ̀, ìyá ọmọ titun; Blessing Isioma David takú pé àwòrán oyún tí òun yà fi hàn pé ọmọ méjì ló wà nínú ikùn òun, ọmọ kan wà nípò tó dára nígbà tí èkejì dùbúlẹ̀. Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ni àwọn ọmọ náà bí àwòrán náà ṣe fi hàn.
Blessing fi ẹ̀sùn kan dọ́kítà tó gbẹ̀bí rẹ̀ pé ó jí ọ̀kan gbé nínú àwọn ọmọ náà pé kí ó gbé e jáde.
Wàyí o, dọ́kítà àgbà ilé ìwòsàn Tip Top; Sunday Babajide ṣe àlàyé pé ọmọ kan ṣoṣo ni àwọn gbé jáde nínú Blessing, ó wí pé ọkọ rẹ̀ gan-an wà níbẹ̀ nígbà tí àwọn ṣe iṣẹ́ abẹ náà.
Dọ́kítà Babajide ṣe àlàyé pé àwòrán oyún tí Blessing yà kùnà láti rí ohun gbogbo dájú, ó wí pé ó ṣeéṣe kí àwòrán oyún ó ṣe àṣìṣe àmọ́ àṣìṣẹ tiwọn ni pé àwọn kò ní kí ó tún àwòrán náà yà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó rọ àwọn èèyàn láti mú sùúrù pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.ÌYÁ ỌMỌ TITUN BU DỌ́KÍTÀ SO LÓRÍ ỌMỌ ÌBEJÌ.

DỌ́KÍTÀ OGBACHI PAPÒDÀ LẸ́YÌN TÓ BÍ ÌBẸTA.
Dọ́kítà Ere Ogbachi ti dágbére fáyé lẹ́yìn tó bí ọmọ ìbẹta. Ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ti ilé ìwé gíga Delta ni dọ́kítà Ere bímọ ìbẹta sí láyọ̀ àti lálàáfíà.
Kò pẹ́ tí ó bímọ tán ni nǹkan yí padà, Ere fi ìnira tó nípọn hàn ni wọ́n bá sáré tari rẹ̀ lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Yenagoa. Aago méjì ọ̀sán ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Igbe ni Ere dáké sílé ìwòsàn náà.
Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe àlàyé pé àwọn dọ́kítà du ẹ̀mí Ere, wọ́n sá sọ́tùn-ún sósì àmọ́ pàbó ni gbogbo rẹ̀ já sí. Ó ní òun ríi bí Ere ṣe ń jẹ̀rora tí kò sì le mí dáadáa títí tó fi papòdà.
Ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń wọn èémí rẹ̀ já wálẹ̀ láti àádọ́rin dé àádọ́tà, láti orí àádọ́ta ló ti já sí òdo ti Ere sì kú.
Ẹ̀gbọ́n Ere ṣe àpèjúwe àbúrò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí dọ́kítà tó dágáńjíá, ó ṣe ìgbéyàwó, ìbẹta yìí náà ni àkọ́bí rẹ̀ tó gba ẹ̀mí rẹ̀ yìí.

IKÚ YẸ̀ LÓRÍ ROTIMI SALAMI.
Ikú ti ré kété lórí òṣèré ilẹ̀ wa Rotimi Salami lẹ́yìn tó balẹ̀ sílé ìwòsàn àmọ́ tí Ọlọ́run mú un lára dá.
Rotimi fúnra rẹ̀ ló kọ̀ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé ọjọ́ méjì ni òun fi wà ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run nílé ìwòsàn. Ó wí pé Ọlọ́run kò ṣetán àti pa òun ni òun fi ye àìsàn náà nítorí ó le gan-an.
Kò sọ pàtó irú àìsàn tó jẹ́, ohun tó kàn jẹ́ kí a mọ̀ ni pé ó ti wà lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀ tó sì ń mójútó o àmọ́ sinimá titun Kilanko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ló wú àìsàn náà sílẹ̀.
Rotimi wí pé òun ṣe wàhálà gan-an nínú àgbéjáde sinimá ọ̀ún nítorí eré náà jẹ́ eré sinimá àkọ́kọ́ ti Allwell Ademola ṣe tó fi jáde láyé.
Gbogbo èyí ni ó wú àìsàn ara rẹ̀ jáde àmọ́ ara rẹ̀ ti balẹ̀ báyìí, ọpẹ́ ni fún Olúwa.

KELECHI PA AWAKỌ̀ KOROPE, Ó TÚN TA ỌKỌ̀ RẸ̀ NÍ RIVERS.
Kelechi Wufurum ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ẹnu Grace Iringe Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ni pé awakọ̀ korope náà àti Kelechi ní ìjà tì tẹ́lẹ̀. Ọkùnrin náà kò fura nígbà tí Kelechi dá ọkọ̀ rẹ̀ dúró tó sì wọlé jókòó bíi èrò.
Orí ìrìn ni wọ́n wà tí Kelechi fi fọ́ nǹkan mọ́ awakọ̀ yìí lórí, ó tún fi àdá ṣá a lórí pẹ́tẹpẹ̀tẹ. Lẹ́yìn náà ló gbé ọkọ̀ korope náà lọ àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.
Mílíọ́nù méjì náírà ó lé ni Kelechi ta ọkọ̀ korope tó gbé yìí, ó sì tún ta ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò sí ìwádìí, wọ́n gbé Kelechi, àwọn tó ra ọkọ̀ àti àwọn tó ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀.
Kelechi ṣe àlàyé bí ó ṣe wọ inú ọkọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà pé kí ó gbé òun dé ibi iṣẹ́ àti bí ó ṣe ṣekú pa á tó sì gbé ọkọ̀ rẹ̀ lọ tà. Àwọn tó ra ọkọ̀ náà jẹ́wọ́ ohun tó pa wọ́n pọ̀ àti ẹni tó mú ojú ajé kan onísọ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ugo Ikenna.
ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ ṢEKÚ PA Ọ̀GÁGUN ILẸ̀ WA.
Àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe ìkọlù sí ibùdó àwọn ológun ilẹ̀ wà tó wà ní Benisheikh ní ìtòsí Maiduguri. Wọ́n ṣekú pa ọ̀gágun àti àwọn ọmọ ogun méjìdínlógún wọ́n sì tún dáná sun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀.
O.O. Braimah ni orúkọ ọ̀gágun yìí, ọ̀gá ló jẹ́ sí Ọ̀gágun Musa Uba tí wọ́n pa níjọ̀sí òun sì ni ipò rẹ̀ ga jù láti ìgbà tí wọ́n ti ń pa ológun.
Àwọn tí wọ́n fimú fínlẹ̀ fi yé àwọn akọ̀ròyìn pé méjìdínlógún ni àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ṣekú pa nígbà tí ọ̀pọ̀ farapa. Wọ́n dáná sun gbogbo ọkọ̀ àwọn ológun wọ́n sì tún sun àwọn ilé tó wà nítòsí.
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa kò tíì wí nǹkankan lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.




