Ilé ìwé gíga Usman Dan Fodiyo tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Sokoto ti fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún àwọn olùkọ́ rẹ̀ mẹ́ta kan. Bí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ́ kúmólú, àwọn aláṣẹ kò le déédéé dá àwọn olùkọ́ náà dúró bí wọn kò bá rú òfin.
Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n náà ni yíyí èsì ìdánwò akẹ́kọ̀ọ́, bíbá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lò àti sísá lẹ́nu iṣẹ́.
Ìpinnu yìí jẹ́ mímọ̀ nínú ìkéde tí adarí àtẹ̀jáde ilé ìwé náà; Ismail Yauri bu ọwọ́ lù.
Nínú rẹ̀ ni wọ́n ti wí pé ilé ìwé náà kò fi ààyè gba ìwà pálapàla, wọ́n ní ìgbésẹ̀ yìí yóò mú kí àwọn olùkọ́ yòókù ó ki ọwọ́ ọmọ wọn bọ aṣọ wọn yóò sì yẹra fún ìwàkiwà. Bákan náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò le kàwé wọn pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbóríyìn fún àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà, wọ́n ní èyí yóò mú kí àwọn olùkọ́ yòókù ó tú èèkànná kúrò lẹ́yìn ọrùn àwọn.
Nígbà tí àwọn kan kín ìpinnu ilé ìwé lẹ́yìn, àwọn kan bèèrè fún pé kí àwọn aláṣẹ ó máa ṣe ìwádìí tó jinlẹ̀ lórí irú àwọn ẹ̀sùn báyìí nítorí àkóbá.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ilé ìwé yóò dá olùkọ́ dúró nítorí irú ìwà báyìí. Ṣebí wọ́n ní Erin kìí jẹ oko abẹ́ rẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ yìí kò rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ejò ni jíjẹ lọ́dọ̀ tiwọn. Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́bìnrin wọn ni wọ́n fẹ́ ṣí láṣọ wò, èyí tó bá wá kò yóò máa tún iṣẹ́ wọn kà ní ìpele sí ìpele ni.
Bí wọ́n ti ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lò nílé ìwé gíga ni wọ́n ń kì wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìpele girama. Kí ló dé tí ọmọbìnrin kò níbi ààbò mọ́? Àwọn tó yẹ kó tọ́ wọn sọ́nà ló ń sọ wọ́n di ajádìí apẹ̀rẹ̀, kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ wo ni ìjọba ṣì gbaṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ ilé ìwé girama kan ná? Tí wọ́n tún rẹ́wọ̀n he lórí rẹ̀, lórí ìbánilòpọ̀ yìí náà mà ni. A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Àwọn olùkọ́ ilé ìwé ìjọba kan ní ìpínlẹ̀ Èkìtì ni ilé ẹjọ́ gíga ti fi téèbù wọn ẹ̀wọ̀n fún bíi ẹni wọn gààrí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n fipá bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn lò pọ̀. Ohun tó so okùn ọ̀ràn yìí mọ́ wọn lọ́run daindain ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ ọmọdé lábẹ́ òfin nítorí wọn kò tíì pé ọmọ ọdún méjìdínlọgún.
Àwọn olùkọ́ náà ni: Gbenga Ajibola; ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti Ayodele Olaofe: ẹni ọdún méjìléláàdọ́ta. Ẹ̀sùn oníkókó mẹ́ta ni wọ́n fi kan àwọn olùkọ́ méjì yìí, ìfipábánilò ni olúborí àwọn ẹ̀sùn náà. Àwọn olùkọ́ náà wí pé àwọn kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀sùn yìí.
Ẹni máa parọ́ lá ní ẹlẹ́rìí òun wà lọ́run, àwọn ọmọbìnrin yìí jẹ́rìí níwajú adájọ́ Adeniyi Familoni ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ekiti. Ọ̀kan nínú wọn ṣe àlàyé pé ìmọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ni ọ̀gbéni Ajibola ń kọ́ òun nílé ìwé náà, ó ní lọ́jọ́ náà, ọ̀gbéni Ajibola wí pé kí òun ó wọ aṣọ ilé wá ó sì fún òun ní igba náírà pé kí òun ó lọ dúró de òun ní iwájú ilé epo kan ní òpópòná ilé ìfowópamọ́ kan ní Ado-Ekiti.
Ọmọ yìí wí pé nígbà tí òun dé ibẹ̀, ọmọ kíláàsì òun kan náà dé bá òun níbẹ̀ ó sì wí pé ọ̀gbẹ́ni Olaofe ló ní kí òun ó wá dúró de òun níbẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn olùkọ́ méjéèjì yìí dé wọ́n sì kó wọn lọ sí ilé ìtura kan tó wà ní Oke-Ila, Ado-Ekiti. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n mú àwọn ọmọ náà lọ́kọ́ọ̀kan lọ sí yàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ́n sì fi okó ba abẹ́ wọn jẹ́.
Ọmọ yìí wí pé láti ìgbà náà ni ọ̀gbẹ́ni Ajibola ti ń da òun láàmú pé kí àwọn ó tún lọ ṣe síi, nígbà tí ara rẹ̀ kò gbà á mọ́ ló sọ fún ìyá rẹ̀ tí àwọn ìyá méjéèjì sì fi tó àwọn agbófinró létí.
Agbẹ̀jọ́rò àwọn olùkọ́ yìí gbìyànjú tirẹ̀, àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́fà ló kó wá sílé ẹjọ́ tí wọ́n wá tako ẹ̀sùn náà, ó wí pé àwọn ọ̀tá àwọn olùkọ́ yìí ló fi ìtàn náà sí àwọn ọmọ náà lẹ́nu pé irọ́ ni wọ́n ń pa.
Adájọ́ Adeniyi ṣe àyèwò àwọn ẹ̀rí àwọn ọmọ náà láti orí ìwé àyẹwò dọ́kítà nílé ìwòsàn tó fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọmọ náà gba kùmọ̀ sára tó fi dé orí ìwé ìforúkọsílẹ̀ ilé ìtura náà, Adájọ́ wí pé àwọn olùkọ́ yìí jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
Ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún ló wọ̀n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ìdí nip é àwọn ọmọ náà jẹ́ màjèsín, ẹ̀kejì ni pé òṣìṣẹ́ ìjọba ni àwọn olùkọ́ yìí àti pé wọ́n gbọ́dọ̀ jìyà lábẹ́ òfin kí àwọn yóòkù ó le fi tiwọn kọ́gbọ́n’
Gbogbo bí ìjọba ṣe ń gbìyànjú àti dẹ́kun ìwà ìbàjẹ́ yìí ló tún ń gbilẹ̀ síi, àwọn olùkọ́ yìí kò ṣetán láti ki ọwọ́ ìwà burukú yìí bọlẹ̀ rárá, àfi bíi àfiṣe.
Àsìkò ti tó fún ìjọba láti gbé ìgbésẹ̀ tó nípọn lórí ìfipábánilò yìí, gbobo ọmọbìnrin ni wọ́n ti sọ di apẹ̀rẹ̀ àjàṣẹ́ tán. Ìjìyà tó nípọn gbọdọ̀ wà fún ẹni tó bá ṣe irú rẹ̀ pàápàá sí màjèsín nítorí ìpalára tí irú ìwà báyìí mú lọ́wọ́.
Ọmọ tí wọ́n bá fipá bálò le kó ààrùn ìbálòpọ̀, ó le ṣèṣe lábẹ́ àti nínú ara. Yàtọ̀ sí èyí, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ kò ní bẹ́gbẹ́ pé; yóò máa kárí bọ́nú tí kò sì ní ní ìgboyà mọ́.
Ọmọ mìíràn le ṣe bẹ́ẹ̀ máa wá ọkùnrin kiri nítorí pé ara rẹ̀ yóò máà bèèrè fún ìbálòpọ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni a ti rí àwọn ọmọ tó ti kú látàrí ìfipábánilò yìí.
Ẹ̀yin òbí àti alágbàtọ́, ẹ má dúró de ìjọba kẹ́ẹ tó mójútó àwọn ọmọ yín, bí ìjọba tilẹ̀ fi ìyà jẹ ọkùnrin náà, ojú àpá kò le jọ ojú ara.