Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ọmọ ọdún márùn-ún kan; Memunat AbdulRahman tí ọkùnrin kan jí gbé ní Ejigbo.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Owohunwa Jimoh ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé, bákan náà ló wí pé kí wọn ó tari ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń ṣe ìwádìí ọ̀ràn. Ìrètí ni pé ìwádìí yìí yóò so èso rere.
Àwọn òbí Memunat AbdulRahman náà fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá wá sí ilé wọn àti àdúgbò náà, wọ́n dé ilé ìtajà tí wọ́n ti jí ọmọ náà gbé, wọ́n sì ṣe àwọn ìwádìí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Alimi AbdulRahman; bàbá Memunat rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ owó, ó wí pé gbogbo owó ni òun ti ná lórí wíwá ọmọ náà.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá la mú ìròyìn bí wọ́n ṣe jí ọmọ náà gbé nígbà tí ó ń bọ̀ láti ilé kéú pẹ̀lú ẹ̀gbọ́ rẹ̀ wá fún yín pé ‘Àwọn òbí Memunat AbdulRahman ti ké gbàjarè síta lórí bí afurasí gbọ́mọgbọ́mọ kan ṣe gbé Memunat nígbà tí ó ń bọ̀ láti ilé kéú.
Ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ẹrẹ́nà tó kọjá lọ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ní Ejigbo, ìpínlẹ̀ Èkó. Memunat; ọmọ ọdún márùn-ún ń ti ilé kéú bọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, arákùnrin náà pàdé wọn lọ́nà ó sì ní kí wọ́n má abọ̀ ní ilé ìtajà kan pé òun fẹ́ ra ìpápánu fún wọn. Ẹ̀gbọ́n Memunat ló kọ́kọ́ wọ inú ilé ìtajà náà, ẹ̀yìn tó máa wò báyìí, ọkùnrin náà ló rí tó ń gbé Memunat sá lọ rẹ rẹ rẹ.
Àwọn òbí ọmọ yìí bèèrè fún fọ́nrán ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìtajà yìí, inú rẹ̀ ni wọ́n ti rí ojú ọkùnrin náà kedere, ó wọ inú ilé ìtajà náà pẹ̀lú àwọn ọmọ méjéèjì níwájú rẹ̀, ẹ̀ẹ̀kan náà ló ki Memunat mọ́lẹ̀ tó sì bọ́ síta, ẹ̀rọ tó wà níta ilé ìtajà náà tún káa bí ó ṣe wọ kẹ̀kẹ́ maruwa tó sì lọ.
Àwọn òbí Memunat ti fi àwòrán ọmọ wọn àti ti afurasí náà léde pé ẹni tó bá kófìrí rẹ̀ kó kàn sí àwọn. Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.
Ní báyìí, ọ̀gá ọlọ́pàá ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe iṣẹ́ náà bí iṣẹ́, a gbàá ládùrá pé èsì ayọ̀ la ó gbà lórí ọmọ náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní orílẹ̀-ède wa, àtọmọdé àtàgbà, àti ọba àti ìjòyè tó fi dé orí àwọn ọmọ ológun ni wọ́n ń jí gbé. Nígbà tí wọ́n tilẹ̀ le jí Ọ̀gágun Tsiga gbé, kí ló tún kù?
A mú ìròyìn bí Ọ̀gágun Tsiga ṣe dé láti àkàtà àwọn ajínigbé wá fún yín pé ‘Ọ̀gá àgbà àjọ́ agùnbánirọ̀ NYSC tẹ́lẹ̀rí; Ọ̀gágun Maharazu Tsiga ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí ní àkàtà àwọn ajínigbé, ó kọjá bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni Tsiga lò ní àkàtà àwọn ajínigbé náà kí ó tó dé lỌ́jọ́bọ, ọ̀sẹ̀ yìí. Ó ṣe àlàyé pé àwọn tí wọ́n jí gbé tí àwọn jọ wà níbẹ̀ pọ̀ gan-an, wọ́n kó wọn jọ síbẹ̀ ni.
Ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì ọdún yìí ni wọ́n gbé Tsiga ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori ní ìpínlẹ̀ Kastina. Ó wí pé ‘ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ la ń jẹun, Tuwo dawa náà sì ni wọ́n ń fún wa jẹ. Àkekèé àti èjò kò ṣàjòjì sí wa mọ́ nítorí pé ojoojúmọ́ la ń rí wọn. Àwọn ajínigbé yìí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á ní ká má wulè pe Ọlọ́run pé owó ni ká mú wá. Nǹkan tí wọ́n bẹ̀rù náà ni àwọn jagungagun ojú òfurufú, ẹ̀rù ikú máa ń bà wọ́n ó sì máa ń hàn lójú wọn bí àwọn jagunjagun ojú òfurufú náà bá dé. Bí àwọn ológun ojú òfurufú bá dé, àwa ni wọn yóò kó síta fi borí kó le jẹ́ pé àwa ni ọta yóò bà, Ọlọ́run ló fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ mi láwọn àsìkò náà.
Òpọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló wà ní ibẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn lọ́gàálọ́gàá àti àwọn èèyàn jàkànjàkàn láàrin ìlú ló kún ibẹ̀. Lílù kò tó nínà, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń nà wá nítorí àìrówó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn wa, Èyí mú ìpalára bá ìlera mi nítorí pé mo ní àìsàn ìpayà lára tẹ́lẹ̀, yàtọ̀ sí lílù, oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa jẹ́ kìkí iyọ̀ ní èyí tí kò dáa fún ìlera mi; bí ẹ ṣe ń wò mí yìí, mi ò le gun àtẹ̀gùn rárá’
Tsiga dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ yìí fún akitiyan rẹ̀ láti gba òun sílẹ̀. Ó ní akọ iṣẹ́ ni iṣẹ́ ológun pàápàá dídojú ìjà kọ àwọn ajínigbé. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara, Sokoto, Kastina àti Niger fún ìlàkàkà wọn láti ìgbà tí wọ́n ti gbé òun.
Ṣé ẹ̀yin náà wá ríi pé ọ̀rọ̀ àwọn ajínigbé yìí yẹ kó ti gba oorun lójú ìjọba? Ó yẹ kí ìjọba ti wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdàá lórí ọ̀rọ̀ àwọn ajínigbé yìí nítorí pé àlàbọrùn wọn ti di ẹ̀wù báyìí.
Ẹnu lọ́lọ́ yìí ni wọ́n tún jí àwọn èèyàn gbé ní ìpínlẹ̀ Delta, a gbọ́ pé Inú oṣù Ẹrẹ́nà tó lọ yìí ni àwọn Fulani ajínigbé ikọ̀ ẹni márùn-ún kan lọ gbé ọ̀gbẹ́ni Chibueze ní abúlé Ogwashi-Uku, wọ́n mú un rìn lọ sí abúlé Ubulu-Uku níbi tí wọ́n ti gbé ọ̀gbẹ́ni Afam, Inú oko kan lọ́nà Powerline ní Ubulu-Uku ni wọ́n kó wọn sí fún ọjọ́ díẹ̀ kí wọ́ tó máa pe àwọn ẹbí wọn fún owó.
Oko tí wọ́n kó awọn ẹni yìí sí jẹ́ oko ọ̀gbẹ́ni Godwin, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ẹrẹ́nà kan náà ni ọ̀gbẹ́ni Godwin, ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ló ṣiṣẹ́ lóko, wọn kò mọ̀ pé àwọn Fulani ajínigbé wà nínú oko, àwọn kàn ń ṣiṣẹ́ lọ ni tí wọ́n fi yọ sí wọn gúlẹ́.
Ẹ̀sẹkẹsẹ̀ ni wọ́n kó wọn mọ́ àwọn tí wọ́n jí gbé tẹ́lẹ̀, ìgbà tí àwọn ẹbí wọn kò tètè rówó san ni wọ́n pa ọ̀gbẹ́ni Godwin lójú aya àti àwọn ọmọ rẹ̀, owó rọ̀gùrọ́gún sì ni wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn méjì yòókù kí wọ́n tó fi wọ́n sílẹ̀.
Àwọn ará Ubulu-Uku wí pé àwọn Fulani ti sọ abúlé náà di ilé pàápàá àwọn ikọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún yìí, wọ́n wí pé ojoojúmọ́ ni àwọn ń sọnù ní abúlé náà tó sì jẹ́ pé àwọn márùn-ún yìí ló ń jí wọn gbé. Wọ́n ké sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀.
Bí ìjọba kò bá tètè wá ọ̀nà àbáyọ, bóyá ni àwọn èèyàn máa ṣẹ́kù nílùú.
Discussion about this post