Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti jẹ gbèsè igba mílíọ́nù náírà lẹ́yìn tí adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó san iye náà fún ìyàwó awakọ̀ tí wọ́n pa.
Kabiru baibai ni orúkọ awakọ̀ yìí, ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù ni ó n wà, ọdún 2021 ni ọlọ́pàá kan yìnbọn pa á ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Adájọ́ Peter Lifu wí pé Moses Samuel jẹ̀bi gbígba ẹ̀mí èèyàn lọ́nà ti kò bá òfin mu, èyí sì lòdì sí òfin orílẹ̀-èdè wa
-Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ gbèsè.
Bákan náà ni adájọ́ pàṣẹ kí ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà àti kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ó fa Moses náà kalẹ̀ fún ìgbẹ́jọ́ ìpànìyàn.
Balikisu ni orúkọ ìyàwó Kabiru, ọdún 2021 náà ló pe ọ̀gá ọlọ́pàá àgbà àti kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lẹ́jọ́ pé ọlọ́pàá kan ṣekú pa ọkọ rẹ̀ lọ́nà àìtọ́, bílíọ́nù méjì náírà ló bèèrè lọ́wọ́ ìjọba ní owó gbà-má-bínú àmọ́ lẹ́yìn tí ìgbẹ́jọ́ parí, igba mílíọ́nù náírà ni adájọ́ fi òǹtẹ̀ lù.
Ìwé ìpẹ̀jọ́ náà kà pé lọ́jọ́ kẹta, oṣù Ọ̀pẹ, ọdún 2021, Kabiru wà ní abẹ́ ọkọ̀ rẹ̀ tó takú sí Ota-Efun ní Òṣogbo, ibi tó ti ń tún ọkọ̀ náà ṣe ni àwọn ọlọ́pàá dé bá a, wọ́n dojú ìjà kọ àwọn ọmọṣẹ́ rẹ̀ tó wà nínú ọkọ̀ pé kín ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀? Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, wọ́n yìnbọn fún ọ̀kan nínú wọn lápá-Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ gbèsè.
Kabiru jáde lábẹ́ ọkọ̀ pé kín ni ìdí tí wọn fi yìnbọn fún ọmọṣẹ́ òun? Kíá ni Moses ti jan ṣọ́bìrì mọ́ ọn láyà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní lù ú, wọ́n lu Kabiru bí aṣọ òfì tí Moses sì tún ta á níbọn láyà, Kabiru kú lójú ẹsẹ̀.
Adájọ́ Peter wí pé agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ láìní àní-àní pé Moses ló pa Kabiru, ó wí pé ìwà yìí lòdì sí òfin ó sì pàṣẹ kí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ó fa Moses kalẹ̀ fún ìgbẹ́jọ́ -Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá jẹ gbèsè.
Ìpànìyàn mìíràn ní ìpínlẹ̀ Ogun:
Lórí ikú Oyesiku, àwọn afurasí mẹ́ta fi ojú ba ilé ẹjọ́.
Lórí ikú tó pa arábìnrin Kiitan Oyesiku, ilé ẹjọ́ ti sọ àwọn afurasí mẹ́ta sí gbaga.
Ilé ẹjọ́ májí tó wà ní Isabo, Abeokuta, ìpínlẹ̀ Ogun ti pàṣẹ kí àwọn afurasí mẹ́ta kan ó lọ máa gba atẹ́gùn ná ní ọgbà àtúnṣe ìwà tó wà ní Oba fún ọgọ́ta ọjọ́ gbáko.
Orúkọ àwọn afurasí náà ni Sodeinde Olajunwon Phillip, Sobu Obafunsho àti Shakirudeen Ayoola. Adájọ́ O.T Odunbanjo pàṣẹ kí wọn ó wà ní àtìmọ́lé fún ọgọ́ta ọjọ́ ná títí ìgbẹ́jọ́ yóò fi bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù Ọ̀wẹ̀wẹ̀, ọdún yìí.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan àwọn mẹ́ta náà ni pé wọ́n ṣekú pa Kiitan Oyesiku; ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ní ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán OGTV. Inú oṣù kẹfà ni won kan òkú Oyesiku àti aṣọ́gbà rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adetayo Pelumi nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ – Lórí ikú Oyesiku
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun sọ̀rọ̀ lábẹ àṣẹ kọmíṣọ́nà wọn; Bode Ojajuni pé ìwádìí fínní ni yóò wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wọn kò sì ní fi igbá kan bọ̀kan nínú.
Báyìí ni a ṣe mú ìròyìn ikú Oyesiku wà lákọ̀ọ́kọ́: – Lórí ikú Oyesiku
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú tó pa arábìnrin Kitan Oyesiku sínú ilé rẹ̀ àti aṣógbà rẹ̀.
Nínú ilé rẹ̀ tó wà ní iyana Agodo ní Owode Egba, ìpínlẹ̀ Ogun ni wọ́n ti bá òkú Oyesiku.
Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí a gbà láti ẹnu Babaseyi Oluseyi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; àwon ará ilé Oyesiku kófìrí ìrìn gbéregbère ní àyíká ilé rẹ̀, wọ́n kàn sí àwọn ọlọ́pàá, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, òkú aṣọ́gbà rẹ̀ ni wọ́n bá ní àbáwọlé kí wọ́n tó wá kan òkú Oyesiku nínú yàrá rẹ̀.
Àyẹ̀wò fi hàn pé àwọn ẹni náà já ilèkùn wọlé ni wọ́n sì tún wa ọkọ̀ rẹ̀ lọ.
Bí ìwádìí náà ṣe ń lọ:
Bode Ojajuni; kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá àṣẹ̀ṣẹ̀yàn ní ìpínlẹ̀ Ogun gbé oríyìn fún ikọ̀ ọlọ́pàá tó ṣe ìwádìí náà. Iṣẹ́ takuntakun ni wọ́n ṣe tí wọ́n fi rí ìwé pélébé kan nínú ọkọ̀ tí wọ́n jí gbé náà, ìwé yìí ni wọ́n mú lọ fún àyẹ̀wò fínní ní ẹ̀ka tí ó ń fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣe àyẹ̀wò. Èsì àyẹ̀wò ló tọ́ka sí afurasí kan gbòógì tí orúkọ rẹ̀ ní jẹ́ Shodeinde Olajuwon Philip.
Ẹni ọdún méjìlélógún ni Philip, ibara ní Abeokuta ni wọ́n ti lo gbé e lọ́jọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Okúdù níbi tó ti ń ṣe iṣẹ́ lébìrà.
Philip ló tóka àwọn méjì yòókù, orúkọ wọn ni Sakirudeen Abdulraheem Ayoola; ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, àti Sobu Obafunsho; ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì. Aṣọ́gbà ni Ayoola nígbà tí Sobu jẹ́ mọlémọle – Lórí ikú Oyesiku
Gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ Ojajuni, Philip jẹ́wọ́ pé òun ṣekú pa Oyesiku láti gbẹ̀san ìwà tó hù sí òun nígbà tí òun fi ń ṣe aṣọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.
Aṣọ́gbà rẹ̀ titun; Adetayo ni wọ́n kọ́ mú lẹ́nu ọ̀nà àbáwọ́lé, òun ni wọ́n tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lọ kan ilẹ̀kùn Oyesiku tí wọ́n fi pa àwọn méjéèjì.
Onikoloo ni àwọn ọlọ́pàá ti lọ gbé ọkọ̀ Oyesiku tí wọ́n wà lọ, ìwé pélébé inú rẹ̀ ló tọ́ka Philip tí wọ́n fi mú un. Ó wí pé òun fi ikú náà kọ́ Oyesiku lẹ́kọ̀ọ́ ni.
Àwọn nǹkan bíi àdá, òkúta ńlá, ọ̀bẹ ni wọ́n bá ní ilé Philip ní èyí tí yóò jẹ́ ẹ̀rí nílé ẹjọ́.
Ìgbẹ́jọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù Ọ̀wẹ̀wẹ̀, ọdún yìí, a ó ní jẹ́ kí etí yín ó di sí bí ó bá ṣe lọ- Lórí ikú Oyesiku Kiitan 
