Ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote àti àjọ NNPC wọ ṣòkòtò kan náà lórí ohun tí àwọn oníbàárà sọ nípa epo bẹntiróòlù tí wọ́n ń tà fún aráàlú.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni pé àwọn èèyàn ti máa ń sọ ọ́ láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn pé epo bẹntiróòlù ti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote dára ju ti àjọ NNPC lọ nìpa pé kìí tètè jó tán. Ibi tí kò bá ti sí ààyè ni wọ́n ti ń jiyàn ẹkẹ, aràkùnrin kan bá gbìyànjú láti fi ẹ̀rí èyí múlẹ̀.
Ọkùnrin yìí lọ sí ilé epo MRS tó wà ní Alápẹ̀rẹ̀, Èkó. Epo láti ilé iṣẹ́ ifọpo Dangote ni wọ́n ń tà níbẹ̀. Ó ra jálá epo kan nílé epo MRS yìí ní okòóléláàdọ́rùn-ún-ó-lé-márùn-ún náírà #925, lẹ́yìn náà ló lọ sí ilé epo NNPC tó wà ní Ojodu-Berger, jálá kan náà ló rà níbẹ̀ ní #945.
Nígbà tó dé ilé, ó da àwọn epo bẹntiróòlù méjéèjì yìí sínú ẹ̀rọ amúnáwá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ó sì tàn wọ́n lásìkò kannáà.
Gbogbo bí ó ṣe ń ṣe èyí ni ó ń ká fọ́nrán rẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ń wòó lórí ìtàkùn ayélujára. Ẹ̀rọ amúnáwá tí ó da epo NNPC sí ló kọ́kọ́ paná lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́tàdìnlógún nígbà tí ẹ̀rọ amúnáwá tó lo epo Dangote paná lẹ́yìn ìṣẹ́jú mẹ́tàlélọ́gbòn. Fọ́nrán yìí ló dúró bíi ẹ̀rí sí ohun tí àwọn èèyàn ti ń sọ tẹ́lẹ̀ pé epo NNPC máa ń yára jó tán.
Ẹ̀sùn yìí gbòdì lára àjọ NNPC, wọ́n yarí kanlẹ̀. Wọ́n ní ìdá àádọ́rùn-ún epo bẹntiróòlù tí àwọn ń tà ló jẹ́ ti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote. Àjọ NNPC ṣe àlàyé pé epo bẹntiróòlù tí ẹni náà rà jẹ́ ti ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote, wọ́n ní ẹ̀ríkẹ́rìí ni arákùnrin yìí fi múlẹ̀ nítorí pé epo bẹntiróòlù tí ilé iṣẹ́ àwọn ń tà jẹ́ ojúlówó.
Kò tán síbẹ̀ o, àjọ NNPC wí pé ẹ̀rí náà kò fìdí múlẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, nítorí náà, òfegèé ni. Wọ́n wá ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo èèyàn láti yàgò fún bíba ọjà ilé iṣẹ́ wọn jẹ́, àjọ NNPC wí pé ẹni tí ó bá sán aṣọ irú rẹ̀ ṣorò yóò fojú winá òfin.
Nígbà tí ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote máà fèsì, ọ̀rọ pèsì jẹ. Wọ́n ní epo tó tètè jó tán náà kìí ṣe ti ilẹ iṣẹ́ àwọn o pé àjọ NNPC ló mọ ibi tó ti rà á.
Ilé iṣẹ́ Dangote wí pé ó ya àwọn lẹ́nu pé àjọ NNPC le sọ pé ọ̀dọ̀ àwọn lọ ti ra epo náà nígbà tó ṣe pé òkè òkun ni wọ́n ti ń ra epo wọn wọlé.
Ilé iṣẹ́ ìfọpo Dangote wí pé àjọ NNPC ń fíràn ni pẹ̀lú irọ́ tí wọ́n pa mọ́ ilé iṣẹ́ àwọn yìí. Wọ́n ní gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé NNPC kìí ra epo lọ́wọ́ àwọn, bá wo ló ṣe wá jẹ́?
****** **** **** **** ***** ***** ***** ***** **** **** ***** ***** ***** ****
Bí a kò bá gbàgbé, kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ilé iṣẹ́ Dangote àti àjọ NNPC yóò gbéná wojụ́ ara wọn lọ́rí ọ̀rọ̀ elépo dé yìí. Àgàgà lásìkò ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiróòlù, àwọn méjéèjì ń nàka síra wọn pé ìwọ lo fàá kìí ṣe èmi.