Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Ibom Airlines ti fi òfin de arábìnrin Comfort Emmanson lẹ́yìn ìtakàngbà tó wáyé láàárín òun àti àwon òṣìṣẹ́ rẹ̀.
Títí ayérayé ni Comfort ò ní le lo ọkọ̀ òfurufú Ibom Air mọ́.
Nínú fọ́nrán tó gbòde kan ni a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir tí wọ́n ń wọ́ arábìnrin Emmanson bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ bàlúù ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Ibom Air ṣe ni pé Emmanson gbá etí òṣìṣẹ́ wọn, ó sì tún gbìyànjú àtifọ́ nǹkan mọ́ ọn lórí.
Ṣáájú kí bàlúù náà tó gbéra ní Uyo, wọ́n ní kí Emmanson ó pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ àmọ́ ó kọ̀, awakọ̀ bàlúù náà kéde pé kí gbogbo ènìyàn ó pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn, síbẹ̀ Emmanson kọ̀, ẹni tó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gba ẹ̀rọ náà lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì pa á.
Ọ̀rọ̀ náà dìjà láàrin wọn àmọ́ wọ́n parí ẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé Ikeja ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed, Comfort ṣe ìkọlù sí òṣìṣẹ́ obìnrin tó ní kó pa ẹ̀rọ rẹ̀ ní Uyo, ó mú un láti ẹ̀yìn, ó yọ irun orí rẹ̀, ó gbá etí rẹ̀ ó sì gbìyànjú àtifọ́ panápaná mọ́ ọn lórí.
Awakọ̀ òfurufú ló ké sí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, wọ́k gbìyànjú àti jẹ́ kó sọ̀ kalẹ̀ àmọ́ níṣe ni Emmanson ṣe ìkọlù sí àwọn náà, mi ni wọ́n bá fi agídí tìpǎtìkûkú wọ́ ọ bọ́ sílẹ̀.
Níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ni aṣọ rẹ̀ ti ya tí gbogbo ọmú rẹ̀ sì wà ní ìta gedegbe.
Nígbà tí wọ́n tún wọ́ ọ bọ́ sílẹ̀ tán, Emmanson tún mú gbogbo wọn bú ó sì tún gbá ọ̀kan létí.
Ilé iṣẹ́ Ibom Air wí pé àwọn ti fa Comfort Emmanson lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ àwọn sì ti kọ ìwé sí àjọ tó ń mójútó ìrìn àjò ojú òfurufú.
Èyí ni àlàyé tí ilé iṣẹ́ Ibom Air ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì fi òfin de arábìnrin Emmanson títí ayé, kò tún le lo bàlúù ilé iṣẹ́ wọn mọ́.
Àwọn èèyàn ti sọ arábìnrin Emmanson lórúkọ titun lórí ìtàkùn ayélujára báyìí, Kwam 2 ni orúkọ tí wọ́n Yàn fún un báyìí.
Ìdí ni pé Wasiu Ayinde tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Kwam1 ló kọ́kọ́ ní irú ìtakàngbà báyìí pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ ValueJet lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Ìròyìn nípa ti Wasiu Ayinde ni èyí:
Àjọ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ òfurufú ilẹ̀ yìí NCAA ti fi òfin de olórí ọmọ ọba Akile Ìjẹ̀bú tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Kwam1 fún oṣù mẹ́fà gbáko lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrín òun àti àwon òṣìṣẹ́ ValueJet ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikiwe ní Abuja.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde ni a ti rí Mayegun Marshall tó ń ṣe fàǹfà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ValueJet tí ó sì tún gbìyànjú àti dá ọkọ̀ òfurufú náà dúró nípa dídúró sí iwájú rẹ̀.
Awakọ̀ òfurufú náà kò torí náà má gbéra, díẹ̀ ló kù kí ìyẹ́ ọkọ̀ náà ó gbá Wasiu lórí.
Àlàyé tí àwọn aláṣẹ ValueJet ṣe ni pé Wasiu kọ̀ láti tẹ̀lé òfin ìrìnnà nípa pé ó kọ̀ láti gbé ike ọtí ọwọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
ValueJet wí pé òfin ni, ẹnikẹ́ni kò le wọ inú ọkọ̀ òfurufú pẹ̀lú ohun mímu, nítorí pé ó kọ̀ láti gbé e sílẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́ náà kò ṣe gbà á láàyè àti wọ inú ọkọ̀ tó fi di ohun tí wọ́n jọ ń fà.
Ilé iṣẹ́ ValueJet ti dá àwọn awakọ̀ òfurufú náà méjì dúró náà nítori pé wọ́n rú òfin tó sọ pé àyíká gbọdọ̀ wà ní àlàáfíà kí wọ́n tó gbéra.
Fọ́nrán yìí ti tàn kálé káko, àwọn èèyàn sì ké sí ìjọba láti gbé e yẹ̀wò.
Ẹni tó jẹ́ adarí ọ̀rọ̀ àwọn aráàlú ẹ̀ka NCAA; Micheal Achimigu ti sọ wí pé kò sí èyí tí yóò mú un jẹ nínú Wasiu Ayinde àti àwọn òṣìṣẹ́ ValueJet, ó wí pé àwọn ti fi òfin de Wasiu báyìí fún oṣù mẹ́fà gbáko, kò ní ní anfààní àti rin ìrìn àjò pẹ̀lú ọkọ̀ òfurufú.
Bákan náà ló wí pé àwọn ti kọ̀wé sí ọ̀gá ọlọ́pàá pátápátá láti fi òfin gbé Wasiu lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Festus Keyamo; ẹni tó jẹ́ mínísítà fún ìrìn àjò ojú òfurufú náà fèsì pé àwọn kò ní fi ààyè gba irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, ẹni tó wù kó jẹ́. Ó pàṣẹ kí wọn ó fi òfin de Wasiu títí ìwádìí ó fi parí.
Nígbà tí àwọn èèyàn bèèrè lọ́wọ́ Achimigu pé ǹjẹ́ yóó ṣe é ṣe láti fi òfin gbé Wasiu tàbí fi ìyà jẹ ẹ́ lábẹ́ òfin nítorí pé ọ̀rẹ́ ni òun àti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Èsì tí Achimigu fọ̀ náà ni pé ààrẹ gan-an kò ní lọ́wọ́ sí rírú òfin nítorí pé òtítọ́ àti òdodo ni ààrẹ dúró fún.
Titi di àsìkò yìí, Wasiu Ayinde Marshall, Mayegun, ẹni tó tún jẹ́ olórí ọmọ ọba Akile Ìjẹ̀bú wà ní ilé rẹ̀, kò tíì sí ìgbésẹ̀ òfin kankan tó wáyé lórí ọ̀rọ̀ náà.
Lóòótọ́ ni pé Wasiu Ayinde ṣe fọ́nrán kan nínú èyí tó ti tọrọ àforíjì, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló sì ti bá a bẹ̀bẹ̀ tó fi dé orí Musiliu Akinsanya tí àwọn èèyàn mọ̀ sí MC oluomo, wọ́n ní kí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ó ṣe ìdáríjì fún Wasiu Ayinde lórí ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́yìn gbogbo èyí ni fọ́nrán kan tún jáde nínú èyí tí Wasiu Ayinde ti ń lérí léka pé Soname; ẹni tó ni ValueJet yóò ní ìmọ̀lára òun nínú ọrọ̀ ajé rẹ̀.
Èyí ló tún fàá tí àwọn èèyàn fi sọ pé ẹ̀bẹ̀ orí ahọ́n ni ó bẹ̀ pé kò dé inú rẹ̀.
Ó ṣe pàtàkì láti mẹ́nuba pé àjọ àwọn awakọ̀ ojú òfurufú ti rọ àjọ ọkọ̀ òfurufú láti pe awakọ̀ òfurufú tí wọ́n dá dúró náà padà sí ẹnu ìṣẹ́.
Ní báyìí, Kwam 1 wà nílé, Kwam 2 wà ní kirikiri, ta ni yóò ṣe Kwam 3 báyìí o?



