Ilé ẹjọ́ gíga èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ killaboi – Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ Benjamin Nnayereugo tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Killaboi. Orílẹ̀-ède Qatar ni Benjamin sá lọ lẹ́yìn tó ṣekú pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀; Augusta sí ilé rẹ̀ tó wà ní Ajah, ìpínlẹ̀ Èkó. Àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà ni wọ́n ṣiṣẹ́ takuntakun tí orílẹ̀ ède Qatar fi tari rẹ̀ padà sílé fún ìgbẹ́jọ́.
Ìwé àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn rẹ̀ àti fọ́nrán tó ti ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá mú ní èrí tó dájú.
Benjamin kọ sínú ìwé ẹjọ́ tó fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ pé òun pa Augusta lóòótọ́ ó sì tún fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀ sínú fọ́nrán. – Ilé ẹjọ́ gíga èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ killaboi
Ìyá Augusta ni ẹlẹ́rìí pàtàkì nínú ìgbẹ́jọ́ náà, ó sọ níwájú adájọ́ Harrison pé bí ọmọ ni òun ṣe mú Benjamin, òun kò mọ̀ pé ó le pa èèyàn. Cordelia Onuwabhagbe; ìyá Augusta wí pé Benjamin yóò jẹ nílé òun, yóò mu yóò sì tún sùn pẹ̀lú.
Cordelia wí pé Benjamin kò le má dé ilé òun gẹ́gẹ́ bíi àfẹ́sọ́nà ọmọ òun; Augusta. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún àti oṣù márùn-ún ni Augusta lásìkò ikú rẹ̀. Cordelia tẹ̀síwájú pé òun kò mọ̀ pé Benjamin ń jẹ́ killaboi nígboro títí di ìgbà tó pa ọmọ rẹ̀ yìí, kódà, ẹ̀ẹ̀mejì ló ti tẹ̀lé òun lọ sí ilé ìjọsìn tí òun kò sì fura pé ẹ̀ẹ̀dẹ ni.
Agbẹ̀jọ́rò bèèrè lọ́wọ́ Cordelia bóyá Benjamin ti gbé Augusta lọ sí òkè òkun rí?
Èsì Cordelia ni bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti jọ lọ sí Mauritius ní ọdún 2021 àti Seychelles ní 2022. Ọdún 2023 ni ó pa ọmọ náà tó sì fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. – Ilé ẹjọ́ gíga èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ killaboi
Wọ́n ní kí Cordelia ṣe àlàyé ohun tó mọ̀ nípa ìrìn àjọ 2021 àti 2022 yìí. Ó wí pé Augusta sọ fún òun pé Benjamin bá òun jà ní Seychelles, ó wí pé òun fi fọ́nrán ìhòhò òun sí orí ìtàkùn ayélujára ó sì fọ́ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀. Benjamin wá fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tirẹ̀ ká Augusta ní ìhòhò fi ránṣẹ́ sí Cordelia pé kí ó wo nǹkan tí ọmọ rẹ̀ ń ṣe. Bákan náà ló fi ẹ̀sùn kan Augusta pé ó ń dá ìfẹ́ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn.
Cordelia tako ẹ̀sùn tí Benjamin fi kan ọmọ rẹ̀ pé ó ba ǹǹkan olówó iyebíye jẹ́ nílé ìtura tí wọ́n gbà ní Seychelles, ó ní kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ nínú fọ́nrán tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí òun. – Ilé ẹjọ́ gíga èkó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ killaboi
Bákan náà ni ó wí pé òun kò gbà pé Augusta gún Benjamin lápá nígbà tí wọ́n ja ìjà tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ yìí, ó wí pé Benjamin fi ara pa níbi tó ti ń gún ọmọ òun lọ́bẹ níkùn léraléra ni.
Agbẹjọ́rò Benjamin wí pé àkóbá lásán ni èyí jẹ́ fún un, ó wí pé Benjamin kò le pa Augusta nítorí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, mílíọ́nù mẹ́wàá náírà ni o fi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí fún un tó sì tún ra ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn olówó iyebíye bíi aṣọ, báàgì, ọ̀ṣọ́ àti ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ iphone.
Cordelia jẹ́rìí pé ó ná owó náà lóòótọ́ àmọ́ ó gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ iphone rẹ̀ padà lẹ́yìn tó pa á. Cordelia ṣe àlàyé síwájú síi pé òun kò mọ̀ pé ìbáṣepọ̀ Benjamin àti ọmọ rẹ̀ ti dópin ti pẹ́ tipẹ́, òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ pé wọn kò fẹ́ra mọ́ pé ó ń gbé Augusta fún àwọn ọkùnrin ni.
Agbẹjọ́rò náà bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé ó mọ Marvin àti pé ṣé ó mọ̀ pé nítorí Augusta ń kó ọkùnrin ni Marvin ṣe fi sílẹ̀. Cordelia wí pé òun mọ Marvin àmọ́ òun kò mọ̀ bóyá ó fẹ́ Augusta rí. Agbẹjọ́rò náà wí pé Augusta parọ́ fún Marvin pé òun ń kàwé ní Ìbàdàn àmọ́ Marvin ká a mọ́ ilé ìtura pẹ̀lú ọkùnrin ni ó fi kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Wọ́n tún ní kí Cordelia ó ṣe àlàyé owó tí Benjamin máa ń fún un, ó wí pé ó fún òun ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún kan, àádọ́ta ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún kan àti mílíọ́nù kan. Ó ní òun kò gba owó mìíràn lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn àwọn èyí ati pé òun ti ná mílíọ́nù kan náírà náà nínú ìtọpinpin Benjamin nígbà tó sá lọ sí Sierra leone.
Adájọ́ Harrison sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́bọ, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Èbìbí.
Ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Agẹmọ, ọdún 2023 ni Benjamin ṣekú pa Augusta ní ilé rẹ̀ tó wà ní Ajah, láti ìgbà náà ni ó ti na pápá bora. Sierra Leone ni wọ́n kọ́ gbúròó rẹ̀ sí tí wọ́n sì lọ gbé e amọ́ ó sá kúrò lẹ́wọ̀n nínú oṣù Belo, ọdún 2023.
Benjamin pààrọ̀ orúkọ ó sì ń sá kiri àwọn orílẹ̀-èdè láàrín 2023 sí 2025. Inú oṣù kẹfà, ọdún 2025 ni wọ́n tọpinpin ìka ọwọ́ rẹ̀ dé Dohar ní Qatar, bí ó tilẹ̀ ti pààrọ̀ orúkọ, àmì ìka ọwọ́ rẹ̀ kò yí padà. Wọ́n kàn sí ìjọba Qatar àwọn ìyẹn sì tari rẹ̀ wálé.
Ẹ̀sùn oníkókó méjì ni ìjọba fi kan Benjamin, ó sì ní òun kò jẹ̀bi ọ̀kankan nínú àwọn ẹ̀sùn náà.
Bákan náà ni ìròyìn mìíràn tó fara pẹ́ èyí tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Imo:
Akẹ́kọ̀ọ́ obìnrin kan ní ilé ìwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó tó wà ní Umuadara Umulogho ni wón dédé bá òkú rẹ̀ nínú ilé rẹ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀ nílẹ̀.
Wendy Achumba ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, àwọn ará ilé rẹ̀ ni wọ́n kófìrí pé wọn kò rí i kí ó jáde síta bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò gbúròó rẹ̀ nínú ilé. Nígbà tó pẹ́ títí tí wọn kò rí i ni wọ́n já ilẹ̀kùn rẹ̀ wọlé, òkú Wendy ni wọ́n bá tí wọ́n ti bẹ́ orí rẹ̀ sílẹ̀.
Wendy ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó, iṣẹ́ àṣèwò àṣekágbá ló ń ṣe nílé ìwòsàn kan ṣaájú ikú rẹ̀ yìí.
Ọmọ bíbí Ngwa ní ìpínlẹ̀ Abia ni Wendy, ìpínlẹ̀ Imo ni ó ti kàwé tí kò sì láǹfààní àti padà sílé mọ́.
Ẹnìkan tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ló ṣe àlàyé pé nígbà tí wọn kò gbúròó Wendy tí kò sì gbé aago rẹ̀ ni wọ́n bá fi ipá já ilẹ̀kùn rẹ̀ wọlé, orí rẹ̀ ló pàdé wọn lẹ́nu ọ̀nà tí wọ́n ti bẹ́ kalẹ̀.
Ike náà ṣe àlàyé pé wọ́n ṣì rí Wendy ní alẹ́ ó-kọ̀la tí wọ́n pa á, títì ni ilẹ̀kùn rẹ̀ wà láti inú, kọ́kọ́rọ́ ni wọ́n sì fi tìí, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò rí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ ìlú fa ìbínú yọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n kojú àwọn ọlọ́pàá tó wá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n fi ẹ̀sùn ìdágunlá kan àwọn ọlọ́pàá pé wọn kò ṣètò bí wọn yóò ṣe gbé òkú náà lọ sí ilé ìgbókùúsí, wọn kò sì ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Henry Okoye pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó ní àwọn ti ṣètò gbígbé òkú náà lọ sí ilé ìgbókùúsí.
Henry rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé Wendy láti ṣe sùúrù kí ìwádìí fi parí, wọ́n ṣe ìlérí láti mú àwọn tó ṣe iṣẹ́ ibi náà.
