Nínú Ìròyìn tó lu jáde ní kàtà àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC kan, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, àwọn kan ti ń kábàámọ̀ lórí òfò ẹ̀mí àti dúkìá tó ṣẹlẹ̀ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Wọn ní gómìnà àná ló ṣì wọ́n lọ́nà lórí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí inú ń bí náà dẹ̀bi gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ru Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Olóyè Adégbóyega Oyetọ́lá ; wón ṣàpèjúwe Oyetọ́lá gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tí kò náání àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ìròyìn tó lu jáde láti inú ẹgbẹ́ APC, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ni wọ́n kẹ́nu bo Oyetọ́lá nípa kíkúnná tó kùnà tó kùnà láti dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀.
Wọ́n tilẹ̀ bínú pé Oyetọ́lá àti àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ kọ̀ láti sọ Òótọ́ àti pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí I gbangba kedere ni pé ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò tilẹ̀ bá ohun tí wọ́n sọ lọ rárá ni. Lára ohun tó lu síta nínú ìjíròrò wọn rèé “ Ẹ̀yin èèyàn mi, a ti dé ìkòríta tó yẹ ká tún èrò wa pa báyìí, kí a fojú sùnnùkùn wo ọjọ́ iwájú wa nínú ètò ìṣèlú pẹ̀lú ọkùnrin tí a ń pè ní aṣáájú wa yìí o. Aṣáájú tó jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀.”
Ó sọ ọ́ débi pé “ Alhaji Oyetọ́lá ti ní ẹ̀mí ìmọtara-eni jù, kò sì wá Ire fún wa rárá “ Wọ́n ní wàhálà tó dé bá wọn lónìí, Oyetọ́lá ló fà á ; tó bá ti jẹ́ kí wọ́n kópa nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀, àwọn ì bá má ti máa sá kijokijo káàkiri báyìí. Wọ́n ní oore-ọ̀fẹ́ bàǹtà-bañta ni ètò ìdìbò náà I bá jẹ́ fún wọn láti mọ ibi tí ó kù sí fún wọn, káwọn sì ṣe àtúnṣe tó yẹ de ìbò gómìnà tó ń bọ̀.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn jàǹdùkú fa wàhálà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí. Ó kọjá bẹ́ẹ̀.
Ohun tó sì fa làásìgbò yìí ni ìgbésẹ̀ tí Olóyè Oyétọ́lá fẹ́ẹ́ gbé láti pàṣẹ fún àwọn alága ijoba ìbílẹ̀ tí wọ́n lé kúrò lórí àlééfà pé kí wọ́n padà sí i iṣẹ́ wọn ní tìpá-tìkúùkù, nítorí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò-tẹ̀-mi-lọ́rùn tí àwọn ẹgbẹ́ APC àti PDP ń lọ́ lọ́rùn mọ́ra wọn lọ́wọ́ .
Olóyè Oyetọ́lá ní kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àná Padà sí orí àga lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù yìí ( 17/02/25. Nínú ìpàdé tí gómìnà Adélékè ṣe pẹ̀lú àwọn oníròhìn ní ọjọ́ Àìkú-16/02/25,ó fẹ̀sùn kan Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Adégbóyega Oyetọ́lá pé ó ń pète-pèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, ó sì fẹ́ lo àwọn agbófinró ṣáájú àti láti ṣe atọ́nà awon alága àti Káńsẹ́lọ́ àná náà lọ sí ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ kálukú.
Gómìnà Adélékè șàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gbẹ́ni Oyetọ́lá jẹ́ ìbátan sí Ààrẹ Tinubu, ìyẹn ò fún un ní agbára kankan láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Adélékè ní ” àwa ò ní í gbà pé kí ẹnikẹ́ni gorí ìjọba ìbílẹ̀ láìjẹ́ pé a bá lo ìlànà ìdájọ́ òdodo tàbí ílànà ìyànsípò tó bófin mu nípa ìlànà ètò ìdìbò”
Ademola Adélékè ní òun ò mọ nǹkan kan nípa lílé tí wọ́n lé àwọn alága àná kúrò lórí àlééfà. Ó ní ilé ẹjọ́ ti yọ ọwọ́ kí-là-ń-kó wọn kúrò kóun tóó dórí oyè. Ó ní ó ṣe òun láàánú láti fi tó Ààrẹ àti àwọn èèyàn àwùjọ létí pé Oyetọ́lá ti parí gbogbo ètò látidá rògbòdìyàn sílẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé – 17/02/25. Pé ó sì ti pàṣẹ oníkùùmọ̀ fún àwọn ẹ̀ka agbófinró láti gbé ìgbésẹ̀ tí kò bójú mú un. Oyetọ́lá ń ṣe èyí nítorí pé ó jẹ́ ìbátan Tinubu, ó sì ń pakuru mọ́ àwọn agbofinro láti tẹ̀ lé àṣẹ oníkùùmọ̀ rẹ̀.
Lẹ́yìn gbogbo rògbòdìyàn náà, àwọn ọmọlẹ́yìn Oyetola wí pé àwọn kábàámọ̀ pé àwọn jẹ́ kí ó ṣi àwọn lọ́nà.