Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti pàṣẹ kí wọn ó ti ilé ìtura Signatious tó wà ní Ajah látàrí ikú Mattias tí wọn kò le ṣe àlàyé rẹ̀.
Mattias kú sí ilé ìtura Signatious àwọn òṣìṣẹ́ sì ń tẹ́wọ́ pẹ̀ẹ́ pé àwọn kò mọ bí ó ṣe kú.
Bàbá rẹ̀ ló ké gbàjarè síta pé láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lọ́rí ikú tó pa ọmọ rẹ̀ sí ilé ìtura Signatious tó wà ní Ajah, ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé tí bàbá Mattias ṣe náà ni pé Mattias lọ sí ilé ìtura náà fún àríyá etí odò ni wọ́n bá ní ó kó sínú odò ìwẹ̀ ilé ìtura náà kí àwọn wá pàdé rẹ̀ nílé ìwòsàn.
Ẹ̀yìn ọkọ̀ tí wọ́n fi gbé e ló sí ilé ìwòsàn ìjọba Isolo náà ni àwọn ẹbí rẹ̀ bá a, wọ̀n kò gbé wọ inú ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú rárá, bàbá Mattias ní òun kò gbà pé ọmọ náà kú sínú odò ìwẹ̀ ni nítorí àwọn àpá tó wà lára òkú rẹ̀ tí kò sì ní nígbà tó wà láyé.
Yàtọ̀ sí àpá ara rẹ̀, bàbá Mattias ní ẹnìkan pe ọmọ náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà gan-an lórí aago pé kí ni kí àwọn fi yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtura náà ṣe àlàyé fún bàbá Mattias pé Mattias àti obìnrin kan ni wọ́n jókòó sí etí odò ìwẹ̀ náà níbi àríyá náà, ṣàdédé ni àwọn kò rí Mattias mọ́, wọ́n bèèrè rẹ̀ ọmọbìnrin náà sì dáhùn pé ó ti lọ, wọ́n ní àwọn fèsì pé kò le tíì ló nítorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó wà lórí àga tó fi jókòó náà ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ní wá a, wọ́n wá a títí wọ́n sì ríi nínú odò ìwẹ̀ ilé ìtura náà. Bàbá Mattias ní òun kò gba àlàyé yìí wọlé pé ejò lọ́wọ́ nínú ikú ọmọ rẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá dé ilé ìtura náà, wọ́n ṣe àkíyèsí pé ibẹ̀ ní àwọn kọ́lọ́fín tó yàtọ̀ sí gbàgede tí àwọn èèyàn ti ń gbafẹ́, àwọn kọ́lọ́fín yìí kún fún àwọn nǹkan tó jọ eegun àti àwọn nǹkan mìíràn tí kò yéni tààrà, àwọn òṣìṣẹ́ ní alámòójútó ilé ìtura náà ló le ṣe àlàyé, wọ́n ní àwọn kò mọ nǹkankan nípa àwọn yàrá kọ́lọ́fín náà.
Wọ́n gbé alámòójútó ilé ìtura yìí wọ́n sì ní kó mú fọ́nrán ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìtura náà jáde. Obìnrin tó jẹ́ alámòójútó yìí ní oun ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ náà ni pé òun kò mọ̀ nípa ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀.
ní báyìí, ìjọba ti pàṣẹ kí wọn ó ti ilé ìtura náà pa.
Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí ìjọba yóò ti ilé ìtura nítorí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí, àwọn ilé ìtura mìíràn gan-an ní odò ẹran èèyàn nínú kọ́lọ́fín wọn. Ṣé ẹ rántí èyí tó wáyé ní Imo?
Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo ti gbé ilé ìtura àti itẹ́ òkú kan tì pa ní agbègbè Umuhu, Ngor-Okpalar, ìpínlẹ̀ Imo. Ilé ìtura àti itẹ́ òkú náà jẹ́ ti aládàáni, ẹnìkan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Stanley Morocco Oparaugo ló ni méjéèjì.
Àwọn ọlọ́pàá ya bo ilé itẹ́ náà nígbà tí ìròyìn kàn wọ́n lára pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi ní ilé ìtura àti itẹ́ náà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ohun tí wọ́n bá kọjá àfẹnuròyìn, nígbà tí wọ́n tún lọ tú ilé àwọn afurasí tí wọ́n gbá mú, ó burú jáì.
Òkú àwọn èèyàn kún ilẹ̀ pẹ̀lú ojú àpá bi tí wọ́n ti yọ àwọn ẹ̀yà ara wọn, kò sí ìtọ́jú fún àwọn òkú náà bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí èyí tí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ pé nínú àwọn òkú náà.
Bákan náà ni wọ́n fura pé yàtọ̀ sí yíyọ ẹ̀yà òkú ara tà, ó ṣe é ṣe kí wọn ó máa jí àwọn èèyàn gbé wá síbẹ̀ láàyè. Ìdí ni pé gbogbo ìgbà ni ìjínigbé ń wáyé ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Owerri sí Aba, èyí ló mú kí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Aboki Danjuma ó ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé láti ṣe àwárí ibi tí àwọn tí wọ́n ń jí gbé náà le máa wọlẹ̀ sí.
Okoye Henry; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo ṣe àlàyé pé ẹni tó ni ilé ìtura àti itẹ́ náà; Stanley Morocco Oparaugo ti na pápá bora báyìí.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sọ wí pé àwọn ọ̀dájú ọ̀daràn ni àwọn ẹni tó ń lo itẹ́ náà, òkú àwọn èèyàn kúnlẹ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ní ipò tí kò bá ojú mu, gbogbo ẹ̀yà ara wọn sì ni wọ́n ti yọ yán.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo ti pàṣẹ kí wọn ó gbé àti ilé ìtura àti itẹ́ náà tì pa báyìí. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi ní ibẹ̀ ni àwọn yóò mú, wọ́n ní ẹni bá mọ ohunkóhun nípa bí àwọn ṣe le rí Stanley Morocco mú kó kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá tó bá sún mọ́ ọn jùlọ.
Ní báyìí, wọ́n ti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá ojú ọ̀nà mároṣẹ̀ Owerri sí Aba.

Golden point hotel náà súnmọ́ odò ẹran èèyàn ó jìnnà sí ilé ìtura:
Ilé ìtura ni àwọn èèyàn ń wò lórí ilẹ̀ náà, àmọ́ abattoir èèyàn ni ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
Udoka Golden point hotel tí wọ́n tún dà pè sí La Cruise hotel ni àsìrí rẹ̀ lu síta lónìí.
Ó lé ní ọgbọ̀n sàrê tó wà ní ìsàlẹ̀ ilé náà, ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró, oògùn dúdú, igbá ẹbọ àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló farasin sí abẹ́ ilé ìtura yìí.
Omi gbígbóná kò gbọdọ̀ pẹ́ lẹ́nu, ọwọ́ kò gbọdọ̀ pẹ́ nísà akekě, ìjọba ti da ilé náà wó.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Onitsha sí Owerri ní ìpínlẹ̀ Anambra ni ilé ìtura yìí wà, àwọn ajinigbe àti agbénipa ló tẹ̀dó sí ibẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi ilé ìtura ni wọ́n fi bo ojú ilé náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ló fúnra rẹ̀ kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lójú òpó X rẹ̀ pé àwọn da ilé ìtura là cruise wó nítorí àwọn èèyàn ni wọ́n ń pa tà ní ibẹ̀.




