ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ètò ẹ̀kọ́

ÌJỌBA TI FI ÒFIN GBÉ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ IGBINEDION TÍ WỌ́N ṢE AKẸGBẸ́ WỌN MỌ́KUMỌ̀KU.

Wọn yóò fi jú ba ilé ẹjọ́ àwọn èwe.

by Adeola Olanrewaju
March 21, 2026
in Ètò ẹ̀kọ́, Ìgbé-Ayé, Ìlera, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè
0
MỌ̀LẸ́BÍ ASORO TỌRỌ ÀFORÍJÌ LÓRÍ ÌWÀ ÌFÌYÀJẸNI TÍ ỌMỌ WỌN HÙ SÍ AKẸ́GBẸ́ RẸ̀.
0
SHARES
3
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Lẹ́yìn ìfẹ̀hónúhàn tó gba iwájú ilé ìwé Igbinedion kan ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ìjọba ti gba èrò àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn, àwọn òbí àti àwọn mìíràn tí wọ́n ké tantan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìṣenimọ́kumọ̀ku tó wáyé nílé ìwé náà wọ́n sì ti ṣetán àti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tọ́rọ̀ kàn ṣe ẹjọ́ nílé ẹjọ́ àwọn èwe.
Ohun tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà náà ṣe ni pẹ́ wọ́n dá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kékéré kúnlẹ̀ wọ́n sì fín wọn ní àtòrì gidi, wọ́n ré wọn nípàá wọ́n sì tún kó ìbóm̀bó bo àwọn ọmọ náà. Kò sí ẹni tó wo fọ́nrán náà tí ara kò ta pé àwọn ọmọ náà le ṣe bẹ́ẹ̀ kú, nígbà tí ariwo pọ̀ lórí ìtàkùn ayélujára ni ilé ìwé Igbinedion lé àwọn ọmọ náà kúrò nílé ìwé náà. A rí àwọn èrò tí wọ́n ń ké lé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà àti bàbá rẹ̀ nígbà tí ó wá mú un lọ sí ilé.
Ní báyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Edo ti fèsì pé àwọn ti mú àwọn ọmọ tọ́rọ̀ kàn náà sí àhámọ́ àwọn yóò sì bá wọn ṣe ẹjọ́ nílé ẹjọ́ àwọn èwe.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ ọ̀rọ̀ yìí láti ẹnu ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn; Eno Ikoedem pé lẹ́yìn ìwádìí ni àwọn mú àwọn ọmọ náà sí àhámọ́ wọn yóò sì fi ojú ba ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ ti àwọn ògo wẹẹrẹ.
Eno ṣe àlàyé pé ọjọ́ karùn-ún, oṣù Ẹrẹ́nà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí àwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ní gbólóhùn asọ̀ pẹ̀lú akẹgbẹ́ wọn kan, akẹgbẹ́ wọn náà wá fèsì pé Ògún yóò pa bàbá wọn. Èyí bí àwọn ọmọbìnrin yìí nínú wọ́n sì sọ ọ́ di ijà.
Nígbà tí wọ́n jáde ilé ìwé, àwọn ọmọbìnrin yìí dènà akẹgbẹ́ wọn náà wọ́n sì dojú ìjà kọ̀ ọ́, òbí kan tó wá mú ọmọ rẹ̀ gbìyànjú àti dá wọn lẹ́kun àmọ́ wọ́n lu obìnrin náà wọ́n sì fa aṣọ rẹ̀ ya. Ìwà tí wọ́n hù yìí ni àwọn adarí ilé ìwé náà fi lé wọn kúrò pé wọ́n hu ìwà ìpáǹle.
Nígbà tó di ọjọ́ kejì, ọmọkùnrin tí wọ́n lu ìyá rẹ̀ náà ṣe ìkọlù sí ẹ̀gbọ́n àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n lu ìyá rẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló ká fọ́nrán rẹ̀ tó sì fi sí orí ìtàkùn ayélujára.
Ọ̀rọ̀ yìí ká kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo lára, ó pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka ààbò ilé ìwé ó karí gbogbo àwọn ilé ìwé ní ìpínlẹ̀ náà kí wọ́n sì ríi pé ètò ààbò tó péye wà ní ilé ìwé gbogbo. Bákan náà ni ó yan àwọn ọlọ́pàá àti ẹ̀ka tó ń gbógun ti ẹgbẹ́ òkùnkùn láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn adarí ilé ìwé gbogbo ní ìpínlẹ̀ náà.
Kò tán síbẹ̀ o, Gómìnà rọ àwọn òbí láti ṣe àmójútó àwọn ọmọ wọn ó sì tún rọ àwọn èwe láti yàgò fún ìwà ìpáǹle.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ ìlú náà láti fi ààyè gba àlàáfíà pé àwọn yóò ríi dájú pé gbogbo àwọn ọmọ tó jẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà fi ojú winá òfin.
Ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Edo náà dá sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní ìwà náà kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà àwọn kò sì ní jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀. Wọ́n lu àwọn ọlọ́pàá lọ́gọ ẹnu lórí ipa wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì ní àwọn fi ọwọ́ síi kí àwọn ọmọ náà ó fi ojú ba ilé ẹjọ́ àwọn èwe.
Lọ́gán tí ọ̀rọ̀ yìí lu síta ni mọ̀lẹ́bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà ti fi ìwé ìtọrọ àforíjìn léde, Choice ni orúkọ ọmọ wọn ní ìdílé Asoro nígbà tí bàbá rẹ̀ ń jẹ́ Tim.
Choice ni ó dàbí ẹni ṣaájú ogun náà nínú fọ́nrán náà bí ó ṣe ń darí àwọn yòókù nígbà tí wọ́n ń lu akẹ́kọ̀ọ́ náà. Àfi bí ìgba tí Choice ti fìgbà kan bá wọn lu òfi rí tàbí lu bàrà láyé àkọ́wá rẹ̀, ó lu ọmọ náà bíi bẹ̀m̀bẹ́ àfi bíi kí ó kú, bó ṣe ń lù ú ló ṣe ń dá a wọ́nlẹ̀.
Bàbá rẹ̀ fi ìwé ìtọrọ àforíjìn léde lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí pé:
Tim Asoro; bàba Choice Asoro ló bu ọwọ́ lu ìwé ìtọrọ àforíjìn náà. Ẹbí Asoro ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ya àwọn lẹ́nu ó sì tún bàwọ́n lọ́kàn jẹ́, fọ́nrán náà jẹ́ ohun kan tó ba àwọn nínú jẹ́ jù láyé yìí gẹ́gẹ́ bíi òbí, ohun ìdòjútì ni fún àwọn pé ọmọ wọn le hu ìwà tó mú ìpalára bá akẹgbẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ tí wọ́n lù náà, àwọn ẹbí rẹ̀ àti iléèwé náà lápapọ̀. Dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà wà ní àlàáfíà àmọ́ ipò ìmọ̀lára ọmọ náà kò dára to.
Àwọn ẹbí Asoro ní èyí fi àwọn lọ́kàn balẹ̀ díẹ̀ àwọn sì ṣetán láti ṣe ìrànwọ́ lórí ìmọ̀lára ọmọ náà. Bákan náà ni wọ́n tọrọ àforíjì lọ́wọ́ iléèwé Igbinedion lórí àbùkù tí ó bá orúkọ wọn látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ wọn tẹ̀síwájú pé àwọn ti bá Choice sọ̀rọ̀ gidi ó sì ti ronú pìwàdà lórí ìwà tó hù náà, ó sì ti mọ ohun tó le tẹ̀yìn rẹ̀ yọ fún òun alára, ọmọ tí wọ́n lù náà àti ilé ìwé náà.
Wọ́n ní àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ lórí bí yóò ṣe di àtúnbí tí yóò rí olùgbaninímọ̀ràn tí yóò sì yí padà di ọmọ rere bíi iyán.
‘Lẹ́ẹ̀kan síi, a tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ tí wọ́n lù yìí a sì ṣe ìlérí pé gbogbo ẹni tí ó fi ara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni yóò rí ìwòsàn’ Tim Asoro
Bí bàbá Choice tilẹ̀ tọrọ àforíjìn, ojú àpá kò le e jọ ojú ara, Choice ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí tí yóò sì fi ojú ba ilé ẹjọ́.

Facebook Comments Box
ADVERTISEMENT

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#newsfeedassaultbullybullyingbullyingvictimschildbullyIwe Iroyin Yorubanewsinyorubanewsonlinenewsupdatephysicalassault
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÌDÍ TÍ OMIDAN KÒ FI GBỌDỌ̀ JÁDE LÁSÌKÒ ORÒ ALUE-DO NÍ OZORO – ÀÀRẸ ẸGBẸ́ ÌTẸ̀SÍWÁJÚ OZORO ṢÀLÀYÉ.

ÌDÍ TÍ OMIDAN KÒ FI GBỌDỌ̀ JÁDE LÁSÌKÒ ORÒ ALUE-DO NÍ OZORO – ÀÀRẸ ẸGBẸ́ ÌTẸ̀SÍWÁJÚ OZORO ṢÀLÀYÉ.

Recommended

ABUCHI PA ÌYÀWÓ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS

ABUCHI PA ÌYÀWÓ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS

3 months ago
Mudashiru Obasa

Ẹ̀KỌ̀ ẸLẸ́KỌ̀ NI Ẹ̀GBÀ ẸLẸ́GBÀ. ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PDP ṢETÁN LÁTI GBA OBASA MỌ́RA.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.