Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti dá sí ọ̀rọ̀ tó wà láàrin Chimamanda àti ilé ìwòsàn Euracare, Gómìnà Babajide Sanwoolu gan-an ló fi léde pé àwọn ti dá dọ́kítà tó ṣe ìtọ́jú ọmọ náà dúró ná, àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní èyí tí wọn kò ní fi igbá kan bọ̀kan nínú.
Ilé ìwòsàn tọ́rọ̀ kàn náà sọ̀rọ̀, wọ́n ní àwọn ń fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí náà àwọn sì ń ṣe ìwádìí tiwọn náà lábẹ́lé. Wàyí o, wọ́n tako ẹ̀sùn pé àwọn kò tẹ́lè ìlànà iṣẹ́ wọn, ilé ìwòsàn Euracare ní àwọn mú iṣẹ́ àwọn lọ́kùnkúndùn àwọn sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà nínú títọ́jú ọmọ náà.
Àlàyé wọn lọ báyìí pé ọmọ náà ti wà ní orí àárẹ̀ náà ó sì ti lo ọ̀sẹ̀ kan nílé ìwòsàn méjì kí wọ́n tó gbé e dé ọ̀dọ àwọn, wọ́n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn dọ́kítà ìlú òyìnbó tí àwọn ẹbí rẹ̀ mú wọn mọ̀, gbogbo nǹkan tó yẹ kí àwọn ṣe ni àwọn ṣe létòlétò. Àmọ́ ó bani lọ́kàn jẹ́ pé ọmọ náà padà kú lẹ́yìn gbogbo ipa wọn.
Bí ilé ìwòsàn ṣe fi èsì tirẹ̀ léde ni ẹnìkan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera tó ní ìrírí ọgbọ̀n ọdún nílẹ̀ yìí àti lókè òkun fèsì padà. Nwandu jẹ́ ọ̀kan lára àwọn dọ́kítà tí ẹbí Adichie pè kí ó wádìí ikú Nkanu. Nwandu wí pé ilé ìwòsàn kan ni Nkanu ti lọ kí wọ́n tó gbé e lọ sí Euracare.
Ó ṣe àlàyé pé òun ti lọ sí ilé ìwòsàn náà fúnra òun láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí òun sì le fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọn kò ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ìlànà iṣẹ́ wọn ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ de ẹ̀rọ èémí mọ́ imú ẹni tí wọ́n bà kùn lóorun títí wọn yóò fi ṣetán àmọ́ ilé ìwòsàn Euracare yọ ẹ̀rọ náà nímú ọmọ náà nígbà tí wọ́n gbé e láti ibìkan síbìkan.
Ilànà sọ pé kí wọn ó máa ṣe àyẹ̀wò bí èémí ṣe ń wọ inú ẹ̀jẹ̀ ọmọ tí wọ́n bá ṣe irú ìtọ́jú yìí fún, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìlànà sọ pé bí wọ́n bá ń gbé irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti ibìkan lọ sí ibòmíràn, kí wọn ó gbé agolo èémí dání nítorí bí èémí rẹ̀ bá dúró, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ìlànà tún ní kí wọn ó máa ṣe àyẹ̀wò irú ẹni bẹ́ẹ̀ lóòrèkóòrè, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Nwandu ní èyí tó burú jù ni gbígbé tí dọ́kítà náà gbé ọmọ náà lé èjìká lọ sí yàrá tí yóò ti ya àwòrán ọkàn, gbígbé yìí kò jẹ́ kó rí ọmọ náà bí ó ṣe ń ṣe sí ní èyí tó lòdì sì òfin, nípa báyìí, Nwandu ní ilé ìwòsàn Euracare lọ́wọ́ nínú ikú Nkanu Nnamdi.
Nwandu wí pé ọmọ náà wà dáadáa kí ó tó lọ ṣe àwọn àyẹ̀wò náà tí àwọn dọ́kítà ilé ìwòsàn John Hopkins ní Baltimore bèèrè fún kí ó tó di pé wọ́n fi àìmọṣẹ́ wọn gba ẹ̀mí ọmọ náà. Ó ní irọ́ pátá ní Euracare gbé jáde wọn kò tẹ̀lé ìlànà iṣẹ́ wọn nínú ìtọ́jú ọmọ náà.
Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe bẹ̀rẹ̀:
Chimamanda ṣe àlàyé pé àwọn wá ṣe ọdún kérésì ní Èkó ni ọmọ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nkanu bẹ̀rẹ̀ àìsàn, wọ́n kọ́ rò pé otútù ni àmọ́ àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fi hàn pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ló fà á, wọ́n ṣètò àti gbé e lọ sí orílẹ̀-ède United Kingdom fún ìtọ́jú, gbogbo ètò ti tò àmọ́ àwọn dọ́kítà lọ́hùn-ún bèèrè fún àwọn àyẹ̀wò kan kí ó tó lọ sí ọ̀hún.
Ó ku ọ̀la tó máa lọ sí UK ni wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Euracare fún àwọn àyẹ̀wò ara náà. Àyẹ̀wò náà gba kí ọmọ náà ó wọ inú ẹ̀rọ wọn kò sì fẹ́ kí ó mira, wọ́n sọ fún ìyá rẹ̀ pé àwọn yóò pa iyè Nkanu ní ráńpẹ́ kí ó má baà mira nínú ẹ̀rọ náà, nígbà tó yá ni dọ́kítà gbé e ní pàjáwìrì lọ sí ẹ̀ka pàjáwìrì tí àwọn nọ́ọ̀sì sì ń sáré kiri, ìgbà náà ni Ngozi mọ̀ pé nǹkan ti yíwọ́.
Chimamanda ní dọ́kítà tó kun ọmọ náà lóorun fún un ní àpọ̀jù òògun apaniníyè tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní propofol wọn kò tún yẹ ọmọ náà wò títí tó fi di pé èémí rẹ̀ lọ sílẹ̀.
Wọ́n de ẹ̀rọ ìmí mọ́ ọn nímú, wọ́n sì gbìyànjú àti jíi sáyé. Ọmọ náà jí sáyé padà ó sì nílò àti lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní dọ́kítà náà yọ ẹ̀rọ tí ọmọ náà fi ń mí ó sì gbé e lé èjìká láti yàrá iṣẹ́ abẹ lọ sí yàrá pàjáwìrì, nígbà tí yóò fi dé ibẹ̀, èémí rẹ̀ ti lọ sílẹ́ pátápátá, ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní sẹ́ gìrì ọkàn rẹ̀ sì da iṣẹ́ sílẹ̀. Bí ọmọ náà ṣe kú nìyẹn.
Chimamanda Adichie fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn Euracare pé wọ́n fún ọmọ òun ní àpọ̀jù òògun propofol wọn kò sì tún yẹ ọmọ náà wò, nígbà tó tún jí sáyé, dọ́kítà náà tún yọ ẹ̀rọ èémí nímú rẹ̀ ó sì gbé e bẹ́ẹ̀ lọ sí yàrá pàjáwìrì. Ngozi ní ìwà ọ̀daràn gbáà ni dọ́kítà náà hù.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn èèyàn méjì ló ti fi ẹjọ́ sùn báyìí nípa dọ́kítà kan náà, wọ́n ní bí ó ṣe máa ń fún àwọn ọmọdé ní àpọ̀jù òògùn nìyẹn, kìí ṣe ti Nkanu làkọ́kọ́.
Ngozi bèèrè ìdí tí ilé ìwòsàn Euracare fi gbà á láàyè láti máa ṣiṣẹ́ lọ? Ó ṣe ìlèrí láti fa ẹjọ́ náà, ó ní òun yóò ríi dájú pé ọmọ mìíràn kò ṣe àgbákò dọ́kítà yìí.




