Ìjọba ìpínlẹ̀ èkó ti dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀ o. Àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé wọ́n ṣekú pa àwọn oníṣòwò ní Owode onirin ti gba ìtúsílẹ̀. Àwọn oníṣòwò mẹ́fà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ṣekú pa. Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ náà ti wà nílé ẹjọ́. Wọ́n ti dá wọn sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ àmọ́ àwọn ẹ̀ka kàn bèèrè fún àtúnṣe ẹjọ́ náà wọ́n sì tún dá wọ́n sílẹ̀.
Ẹ̀ka ètò ìdájọ́ ìpínlẹ̀ Èkó ló pàṣẹ kí wọn ó dá àwọn afurasí náà sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn olùbádámọ̀ràn Gómínà wí pé àwọn ọlọ́pàá náà gba ara wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ náà ni. Wọ́n ní àwọn tó pe ẹjọ́ náà kò ní ẹ̀rí àrídájú pé àwọn ọlọ́pàá náà ló ṣekú pa àwọn ẹni náà.
Lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà; Ariori tó jẹ́ aṣojú àwọn ẹbí tó ní àwọn ló ni ilẹ̀ ọjà náà ló kó àwọn ọlọ́pàá wá láti Nasarawa. Ọ̀rọ̀ di wàhálà ni wọ́n bá yìnbọn pa àwọn oníṣòwò mẹ́fà. Láti ìgbà náà ni ẹjọ́ ti bẹ̀rẹ̀. Ilé ẹjọ́ dá Ariori sílẹ̀ pé ara rẹ̀ kò yá nígbà tí àwọn ọlọ́pàá náà wà ní àhámọ́.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni ilé ẹjọ́ dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀ pé wọn kò jẹ̀bi. Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn àti Falana ló dìde tako ìdájọ́ yìí. Falana bèèrè fún kí wọn ó tún ẹjọ́ náà ṣe pé ejò lọ́wọ́ nínú.
Wọ́n ti tún ẹjọ́ ṣe báyìí o, ilé ẹjọ́ sì ti pàṣẹ kí wọn ó dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀. Ìdí ni pé kò sí àrídájú ẹ̀rí pé àwọn ọlọ́pàá náà ló ṣekú pa àwọn ẹni náà.
Wàyí o, èsì àyẹ̀wò òkú àwọn ẹni náà fi hàn pé ọta ìbọn ló pa wọ́n. Falana ti yarí lórí ìdájọ́ yìí, ó ní òun yóò tún ẹjọ́ náà pè nítorí ejò lọ́wọ́ nínú ìdájọ́ náà.
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé rèé – Ìjọba ìpínlẹ̀ èkó ti dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀.
A gbọ́ pé ẹnìkan tó jẹ́ ajagungbalẹ̀ ló kó àwọn ọlọ́pàá náà wá láti ìpínlẹ̀ Nasarawa wá ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó. Lọ́jọ́ náà, wọ́n yìnbọn pa àwọn èèyàn mẹ́fà ní ọjà Owódé onírin wọ́n sì tún dáná sun ọkọ̀ bíi àádọ́ta.
Ẹni tó ṣe àlàyé náà wí pé lọ́gbọ̀njọ́, oṣu Ògún ni ẹni náà kó awọn ọlọ́pàá náà dé láti ipínlẹ̀ Nasaraa tí wọ́n sì ṣe awọn èèyàn báṣubàṣu.
Ó wí pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá náà ó jẹ́jọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó tí wọ́n ti ṣẹ̀. Abuja ni wọ́n kó wọn lọ, ibẹ̀ ni ẹjọ́ wọ́n ti ṣe mọ̀dàrú ẹjọ́ náà tí wọ́n sì dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá dá wọn sílẹ̀ lórí àre pé wọ́n gba ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n ń pè ní self defence ni wọ́n fi pa àwọn ẹni náà.
Bákan náà ni ẹni náà wí pé ọ̀rẹ́ tímọ́ ni ajagungbalẹ̀ náà àti kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa.
Femi Falana; ẹni tó jẹ́ agbẹjọ́rò ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ìdásílẹ̀ awọn ọlọ́pàá yìí, ó wí pé bí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò bá sṣe ẹjọ́ náà, òun ṣetán àti ṣe ẹjọ́ náà.
Bí wọ́n bá ní ìgbara-ẹni-sílẹ̀ làwọn fi pa èèyàn méje, kí wọ́n wá sọ ọ́ níwájú adájọ́.
Àwọn ẹbí àwọn tó ṣe àgbákò náà fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n ṣe màgòmágó ẹjọ́ náà wọ́n sì tún lọ́ àwọn lọ́wọ́ gbà.
Wọ́n wí pé àwọn ọlọ́pàá sọ fún àwọn pé ẹgbẹ̀ta òkú ni àwọn ṣì fẹ́ ṣe àyẹ̀wò rẹ̀ kí wọ́n tó le ṣe àyẹ̀wò òkú wọn àti pé wọ́n ní láti san owó àyẹ̀wò.
Nígbà tí òkú Akinboye Oluaseyi ṣì wà nílé ìgbókùúsí, àwọn ọlọ́pàá ti dá àwọn tó pa á sílẹ̀. Ọmọ mẹ́ta ni Akinboye fi sáyé lọ – Moruf Olayemi; mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ṣàlàyé.
Moruf wí pé kò sí òfin mọ́ ní ìlú yìí, ẹni bá ti lówó lọ́wọ́ le ṣe ohun tó wù ú.
Owolabi Ganiu; ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ Wale Adebayo náà fi ẹ̀sùn kan àwọn olọ́pàá pé wọ́n kàn ń gba owọ́ lọ́wọ́ àwọn ni, ó ké sí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí.
Ọmọ ọdún mẹ́ta ni Adebayo fi sáyé lọ tí ìyá ìyàwó rẹ̀ sì ní ààrùn rọpárọsẹ̀ nígbà tó gbọ́ ikú rẹ̀.
Abiodun Babalola; ẹni tí ọmọ rẹ̀ Abraham náà kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe àlàyé pé owó tí àwọn ọlọ́pàá ń bèèrè fún ayẹ̀wò òkú náà ti pọ̀ ju ohun tí òun le rí lọ, ó rọ̀ wọ́n láti gbé òkú Abraham fún òun bí wọn kò bá le ṣe àyẹ̀wò náà.
Bákan náà ni Bàbá Akeem Adeoye fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé ìwà ìkà ni kí wọ́n bèèrè ẹgbèlẹ́gbẹ̀ owó kí wọ́n tó le ṣe ẹjọ́ ìpànìyàn náà.
Bàbá ọjà Owóde onírin; Abiodun Ahmed rọ àwọn mọ̀lẹ́bí náà láti ṣe sùúrù pé ìjọba ni yóò san owó àyẹ̀wò àwọn òkú náà.
Abiodun wí pé lóòótọ́ ni àwọn olọ́pàá ti dá àwọn afurasí náà sílẹ̀ wọ́n sì tún wí pé ara ajagungbalẹ̀ náà kò dá ni àwọn ṣe dáa sílẹ̀.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Abimbola Adebisi ní òun ṣẹ̀ ń gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni, Benjamin Hundeyin tí ó jẹ́ agbẹnusọ àgbà náà kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
Wàyí o, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Moshood Jimoh ti pàṣẹ kí wọn ó tún ẹjọ́ náà ṣí.
Wọ́n tún ẹjọ́ náà ṣí lóòótọ́, àmọ́ ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọn ó dá wọn sílẹ̀. Ìdí ni pé àwọn èèyàn náà ṣe ìkọlù sí àwọn ọlọ́pàá náà ni wọ́n ṣe yìnbọn láti gba ara wọn kalẹ̀. Àti pé kò sí ẹ̀rí àrídájú pé ìbọn tí wọ́n yìn ló pa àwọn ẹni náà ni ijọba ìpínlẹ̀ èkó ba dá àwọn ọlọ́pàá náà sílẹ̀. – ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI DÁ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ NÁÀ SÍLẸ̀



