Mínísítà fún ìrìn àjò ojú òfurufú; Festus Keyamo ti kéde pé àwọn ti ṣe àdínkù òfin ìrìnnà tí wọ́n fi de Wasiu Ayinde sí oṣù kan dípò oṣù méjì.
Bákan náà ni ó pàṣẹ kí wọn ó dá awakọ̀ òfurufú náà padà sí ẹnu ìṣẹ́ rẹ̀.
Lẹ́yìn èyí ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yan Wasiu Ayinde ní aṣojú ìwà ọmọlúàbí fún ìrìn àjò ojú òfurufú.
Festus Keyamo wí pé òun yóò ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Wasiu Ayinde láti ṣe ìlanilọ́yẹ lórí ìwà àti ìṣesí tó tọ́ fún ìrìn àjò ojú òfurufú.
Kò tán síbẹ̀ o, ìjọba ti fagi lé gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n pè tako Ọmọ Anífowóṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nínú ìròyìn tí a kọ sẹ́yìn, a bèèrè pé ipa wo ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò kó lórí ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé kòríkòsùn ni òun àti wasiu Ayinde.
Ẹ̀kọ ti fi ojú mímu hán báyìí, oyè titun ló bá dé fún ọmọ wọn ní fidipote.
Kwam1 lápá kan, Kwam2 lápá kejì.
Ìjọba àpapọ̀ ti dá Comfort Emmanson sílẹ̀ báyìí.
Ilé ẹjọ́ tó fìkàlẹ̀ sí Ọgbà, ìpínlẹ̀ Èkó ti dá arábìnrin Comfort Emmanson sílẹ̀ kó máa lọ láyọ̀ àti àlàáfíà lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá fagi lé ẹ̀sùn oníkókó márùn-ún tí wọ́n pè takò ó.
Adájọ́ Olanrewaju Salami pàṣẹ kí Comfort ó máa lọ sí ilé rẹ̀ ó sì fagi lé ẹjọ́ náà.
Festus Keyamo; ẹni tó jẹ́ Mínísítà fún ìrìn àjò ojú òfurufú kéde pé lẹ́yìn ìjíròrò pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn, àwọn fi ẹnu kò síbi pé kí wọn ó fagi lé ẹjọ́ Comfort kí wọn ó sì fagi lé òfin irinna tí wọ́n fi dè é.
Ìdásílẹ̀ yìí wáyé lẹ́yìn tí àwọn èèyàn ti dìde láti jà fún Comfort.
Àjọ CSO kan gan-an ti dìde fún un lánàá.
A gbọ́ pé:
Àjọ CSO kan ti orúkọ wọn ń jẹ́ The Network for Actualisation of Social Growth and Viable Development ṣetán láti gba ẹjọ́ Comfort Emmanson rò níwájú adájọ́. Kódà, wọ́n ní àwọn kò ní gba owó lọ́wọ́ rẹ̀.
Àjọ yìí dá ilé iṣẹ́ Ibom Air lẹ́bi, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ arábìnrin Emmanson mọ́lẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n wí pé ìfìyàjẹni lásán ni bí wọ́n ṣe ti Comfort mọ́ kirikiri.
Àjọ yìí wí pé àwọn ti ṣetán láti gba agbẹjọ́rò fún Comfort lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àwọn ni yóò sì ná gbogbo owó ìdí rẹ̀.
Omoniyi Akingunola; ẹni tó jẹ́ adarí àjọ yìí ṣe àlàyé pé fífi òfin ìrìnnà de Comfort láìgbọ́ ti ẹnu rẹ̀ náà jẹ́ ìtẹ̀tọ́mọnìyàn-lójú-mọ́lẹ̀.
Bákan náà ló dá àwọn ọlọ́pàá lẹ́bi pé wọ́n gbè Comfort lọ sí ilé ẹjọ́ láìṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà.
Akingunola wí pé fọ́nrán tí wọ́n fi léde nìkan ni àwọn ọlọ́pàá mú dání, wọn kò bèèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú bàlúù náà.
Àwọn ọlọ́pàá kò bèèrè ìdí tí obìnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ náà ṣe dínà mọ́ Comfort pé kò ní sọ̀ kalẹ̀.
Àjọ yìí ti ṣètán báyìí láti bá Comfort pe ilé iṣẹ́ Ibom Air lẹ́jọ́.
Ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Akingunola sọ yìí farapẹ́ àlàyé tí Timi Agbaje ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Amòfin ni Timi Agbaje, ó ṣe fọ́nrán kan nínú èyí tó ti ṣe àlàyé àwọn ẹ̀bi Comfort àti ti ilé iṣẹ́ Ibom Air.
Ẹ̀bi Ibom Air ló pọ̀jù nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.
Láti ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Comfort yìí ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí oríṣìí fọ́nrán nínú èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir ti ń ṣe àwọn arìnrìnàjò wọn níṣekúṣe.
Àwọn èèyàn wí pé àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir ṣáájú àsìkò yìí kìí ṣe àwọn arìnrìnàjò wọn dáadáa.
Àṣà Kwam tó gbòde yìí ni àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ká ní Kwam1, Kwam2, Kwam3 tí ó sì ti dé orí Kwam4 báyìí.
Kwam 3 ni ti obìnrin kan pẹ̀lú IbomAir yìí kan náà, a rí obìnrin náà tó ní òun kò ní lọ bí àwọn ẹrù òun kò bá pé. Ó fi ẹ̀sùn kan Ibom Air pé ẹrù òun dín ọ̀kan, wọ́n jọ pò ó, nígbà tó sọ̀ kalẹ̀, ó ní òun yóò gba owó òun padà ní pípé.
Kwam4 ni fọ́nrán ọkùnrin kan tó gbòde pẹ̀lú IbomAir yìí kan náà, a rí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir tí wọ́n ń wọ́ ọkúnrin kan bọ́ sílẹ̀ nínú bàlúù wọn.
Gbogbo àwọn fọ́nrán yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde nigba tí ọ̀rọ̀ Comfort ṣẹlẹ̀.
Ká kúrò lórí ọ̀rọ̀ Kwam, ká yára sọ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní ilé-ifẹ̀.
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo tó wà ní Ilé-ifẹ̀ ti di àwátì báyìí, àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà ké gbájarè síta.
Dorcas Oseghale ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, ẹ̀ka ìmọ̀ kẹ́mísìrì ni ó wà, ó sì ti wà ní ìpele kẹrin.
Ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin báyìí tí wọ́n ti fi ojú kan Dorcas gbẹ̀yìn.
Alukoro fún ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀gbẹ́ni Abiodun Olanrewaju ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ó wí pé àwọn àwọn ará ilé Dorcas ni wọ́n fi sùn pé Dorcas kò padà wọlé lẹ́yìn tó lọ ra oúnjẹ.
Ilé Adesanmi tó wà ní ọ̀nà Ìbàdàn ni Dorcas ń gbé pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, lálẹ́ ọjọ́ náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́, Dorcas jáde lọ ra oúnjẹ ní ‘Student’s village’ tó wà ní ọ̀nà Ẹdẹ.
Nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò ríi kó dé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pe aago rẹ̀ àmọ́ aago rẹ̀ méjèèjì kò lọ.
Wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwé létí wọ́n sì fi sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo; Ọ̀jọ̀gbọ́n Simeon Bamire ti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé ìwé láti sa ipa wọn ó sì tún rọ àwọn ọlọ́pàá láti wá ọmọ náà jáde.




