Ọkọ̀ Toyota kan tó kó èèyàn méje láti ìpínlẹ̀ Osun wá sí Èkó pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó ń lọ ní tirẹ̀.
Aago mẹ́sàn-án àárọ̀ ni ìjàmbá yìí wáyé lónìí ọjọ́ àìkú.
Ọ̀gbẹ́ni Sanni Saifullahi ló wa ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà, ọkọ̀ àjàgbé yìí ga tó ìwọ̀n ogójì ẹsẹ̀ bàtà, ilé iṣẹ́ Ay and Rolly’s ventures tó wà ní Magodo, ìpínlẹ̀ Èkó ló ni ọkọ̀ àjàgbé yìí.
Ọgbẹ́ni Sunday Okpe ti ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló wa ọkọ̀ Sienna yìí.
Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ọ̀gbẹ́ni Sunday ti gbéra pẹ̀lú èrò méje, ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ìta Olúwo, Ìkòròdú ni ọkọ̀ yìí ti pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà.
Arábìnrin Miracle Chibuzor tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló jókòó níwájú, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá yìí, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn fara pa yánnayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn pé arábìnrin Miracle pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ló kó àwọn márùn-ún tí wọ́n farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn Falobis tó wà ní Mowe fún ìtọ́jú.
Wọ́n gbé òkú arábìnrin Miracle lọ sí ilé ìgbókùúsí Idera fún àyẹ̀wò àti ìwé ẹ̀rí.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wọ́ àwọn ọkọ̀ méjèèjì náà lọ sí àgọ́ wọn tó wà ní Shagamu kí àwọn òṣìṣẹ́ VIO le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Ìjàmbá ọkọ̀ mìíràn wáyé ní ìta Olúwo yìí kan náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ àárọ̀.
Arábìnrin kan tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ni ó jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ márúwá lẹ́nu tó sì padà gbé ẹ̀mí mìn.
Usman Abdullah; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ló wa kẹ̀kẹ́ TVS náà, obìnrin yìí fẹ́ sọdá títì ló jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ Abdullahi lẹ́nu, orí ló fi ṣèṣe. Àwọn èèyàn ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn Omowunmi tó wà ní Kusela, Ogijo àmọ́ obìnrin yìí padà jẹ́ ìpè Elédùà.
Àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀, wọ́n ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì wọ́ kẹ̀kẹ́ náà lọ sí àgọ́ wọn. Abdullahi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìwádìí lórí bí ìjàmbá náà ṣe wáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kòrò ojú sí ìjàmbá méjèèjì yìí, wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé ní èyí tó le mú kí ìjàmbá ọkọ̀ ó wáyé, bákan náà ni wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti má màa sún mọ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò pẹ́kípẹ́kí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogulowo gba àwọn awakọ̀ níyànjú.
Ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó ti gba ọ̀pọlọpọ̀ ẹ̀mí àwọn èèyàn láìròtẹ́lẹ̀, àkọsílẹ fi hàn pé eré àsápajúdé ló fa èyí tó pọ̀jù nínú àwọn ìjàmbá náà.
Nínú ọdún yìí náà ni awakọ̀ Toyota Highlander kan pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ní ojú ọnà márosẹ̀ Lekki-Epe lọ́sàn-án àná.
Awakọ̀ yìí pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì lọ kọlu ọkọ̀ àjàgbé kan tó ń lọ sí Epe, ọkọ̀ Toyota náà gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó kọlu àjàgbé náà, gbogbo akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí awakọ̀ yìí kò yọrí sí rere.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì; Adebayo Taofiq ló fi ọ̀rọ̀ náà lédè pé àwọn gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí arákùnrin tó wa ọkọ̀ náà àmọ́ ó ti kú kí wọn ó tó ríi yọ wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀.
Àjọ LASTMA gba àwọn awakọ̀ níyànjú láti ṣe pẹ̀lẹ́.
Lórí ọ̀rọ̀ ìjàmbá ọkọ̀ yìí kan náà —
Ọjọ́ mánigbàgbé ni ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Ọ̀pẹ ní ìpínlẹ̀ Abia nígbà tí ìjàmbá ọkọ̀ mú ẹ̀mí àwọn èèyàn mẹ́fà lọ lẹ́ẹ̀kan náà.
Ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan ló mú ọkọ̀ akérò kan gùn, àwọn èèyàn náà kò kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ àwọn mẹ́fà padà kú nígbà tí wọn kò rí wọn yọ lásìkò nígbà tí àwọn yóòkù fara pa yánnayànna.
Òpópónà Mmuri ní ìjọba ìbílẹ̀ Ohafia, ìpínlẹ̀ Abia ni ìjàmbá yìí ti wáyé. Nǹkan bíi aago kan àbọ̀ ọ̀sán ni ìjàmbá náà wáyé . Òpópónà náà kò já geere fún ọkọ̀ láti gbà kọjá ló fa ìjàmbá náà.
Ààrẹ ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè Ohafia; Emeka Mba bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé ó bani lọ́kàn jẹ́ pé ìjàmbá náà mú ẹ̀mí mẹ́fà lọ. Ó bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ẹ̀ka ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì pé wọn kò ní irin iṣẹ́ tí wọ́n le fi wọ́ ọkọ̀ àjàgbé náà kúrò lórí ọkọ̀ akérò náà.
Mba wí pé ó ṣeéṣe kí àwọn èèyàn náà ó má kú bó bá ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì ní irin iṣẹ́ tó kúnjú òṣùwọ̀n ni.
Àjọ tó ń rí sí ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Abia fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ pàjáwìrì, ọkọ̀ awọ́kọ̀ (Towing vehicle) méjì ni wọ́n gbé lọ àmọ́ agbára wọn kò wọ́ ọkọ̀ àjàgbé náà nítorí ẹrù tó kó wúwo.
Ìjàmbá ọkọ̀ náà ló mú ẹ̀mí ọmọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa lọ ní ọdún tó kọjá.
Ọ̀fọ̀ méjì ló ṣe Gómìnà Umar Namadi; Gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa láàrin ọjọ́ méjì síra wọn.
Ọjọ́bọ, ọjọ́ kejì kérésì ni àkọ́bí Gomina Umar Namadi tíí ṣe Gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa; Abdul-wahab Namadi ní ìjàmbá ọkọ̀ tó sì dágbére fáyé.
Ilé Kafin ni Abdulwahab àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti ń bọ̀ lọ́jọ́ náà tí wọ́n sì ń lọ sí Dutse, ọkọ̀ wọn pàdánù ìjánu rẹ̀ ní èyí tó mú kí ó gbókìtì.
Abdulwahab ló wa ọkọ̀ náà, òun nìkàn ló kú nínú ìjàmbá yìí, àwọn ọ̀rẹ́ wà farapa wọ́n sì wà nílé ìwòsàn ìjọba Dutse.
Akọ̀wé àtẹ̀jáde fún Gómìnà Namadi; Hamisu Gumel fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé Gómìnà Namadi ń ṣọ̀fọ̀ ìyá àti ọmọ rẹ̀ tí wọ́n kú ní àárín wákàtí mẹ́rìnlélógún síra wọn.
Òpópónà Dutse sí Kaduna ni Abdulwahab ti ní ìjàmbá ọkọ̀ tó gba ẹ̀mí rẹ̀. Wọ́n ti fi ilẹ̀ bò ó láṣǐrí ní ìlànà ẹ̀sìn mùsùlùmí.
Abdulwahab fi àwọn òbí rẹ̀, ìyàwó rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn àbúrò rẹ̀ sáyé lọ.
Gbogbo Jigawa kan bóbó, wọ́n bá Namadi dárò àwọn tó lọ.
Ìjàmbá ọkọ̀ mélòó la fẹ́ sọ nípa rẹ̀, kí Elédùmarè ó máa dáàbò bo àwa àti ẹ̀yin ní gbogbo ìgbà, a kò ní fọjọ́ ọlọ́jọ́ lọ o, àṣẹ.