Ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn lọ́gbọ̀njọ́, oṣù Ọ̀wàrà kọjá àfẹnuròyìn.
Ìjàm̀bá náà wáyé láàrin àwọn ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù lórí afárá Kara ní Mowe. Ìjàm̀bá yìí mú kí ọkọ̀ náà ó gbaná tí ó sì dá súnkẹrẹ-fàkẹrẹ sílẹ̀.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ìpínlẹ̀ Èkó kọ ọ́ sí ojú òpó wọn pé ọkọ̀ àjàgbé kan tó kó ẹrù gbaná nígbà tí òmíràn dànù pẹ̀lú ọ̀pọ̀ páálí bisikí, ọkọ̀ àjàgbé mìíràn kọlu kankéré etí afárá náà ó sì ré sínú odò.
Àwọn èèyàn mẹ́jọ ló ti kú nínú ìjàm̀bá yìí nígbà tí iṣẹ́ ń lọ láti dóòlà àwọn yòókù.
Bákan náà ni ná jó ní Abuja.
Ilé ìtajà Jabi Lake tó wà ní Abuja ti múná lọ́gbọ̀njọ́, oṣù Ọ̀wàrà. A gbọ́ pé iná náà sẹ́yọ ní nǹkan bíi aago mẹ́ta òru a kò sì tíì le sọ okùnfà rẹ̀ báyìí.
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ panápaná àti àwọn ọlọ́pàá tara ṣàṣà dé ibẹ̀ láti kojú rẹ̀.
Saliu, olùgbé Jabi bá ikọ̀ akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé wọ́n ti pa iná náà bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Josephine Adeh; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ààbò.
Ọwọ́ àwọn NSCDC ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Anambra ti tẹ àwọn ayédèrú ẹ̀ṣọ́ aláàbò márùn-ún ní ìpínlẹ̀ náà. Ìbọn àgbélẹ̀rọ ni wọ́n bá lọ́wọ́ wọn.
Maku Olatunde; ẹni tó jẹ́ apàṣẹ NSCDC ìpínlẹ̀ náà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ọ̀wàrà nígbà tó ń fi ojú àwọn afurasí náà hàn.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn rí àwọn ẹni náà nígbà tí àwọn ń lọ bọ̀ tí wọ́n sì wọ aṣọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò NSCDC, àwọn èèyàn yìí ń lọ káàkiri gbogbo àdúgbò wọ́n sì ń wọ gbogbo inú agbègbè.
A gbọ́́ pé àwọn olóṣèlú kan ló gba àwọn èèyàn náà sínú àdúgbò ní ìmúrasílẹ̀ ìdìbò sípò Gómìnà tí yòó wáyé lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù tó ń bọ̀. Iṣẹ́́ tí wọ́n gbà wọ́n fún náà ni kí wọn ó rin gbogbo àdúgbò já kí wọn ó sì ṣètò bí wọn yóò ṣe dá wàhálà sílẹ̀ lọ́jọ́ ìdìbò.
Orúkọ àwọn afurasí náà ni Mmeka Ekene, Peter Detuchi, Enemuo Ifeanyichukwu, Akpan Idiong àti Francis Ugochukwu Nwosu.
Olatunde wí pé àwọn afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ lọ́gán tí ìwádìí bá parí.
A ti ní olórí ológun titun o, àwọn agbésùnmọ̀mí dáràn.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti bu ọwọ́ lu Olufemi Oluyede ní ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ológun. Olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin; Goodswill Akpabio wí pé iṣẹ́ àwọn ni láti fi ẹni tó kúnjú òṣùnwọ̀n sípò ní ìbámu pẹ̀lú òfin.
‘Pẹ̀lú ìdùnú ni mo fi kí Oluyede káàbọ̀ sí ipò ọlá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, mo kí ọ kú oríire lórúkọ gbogbo ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, mo sì kí ọ kú iṣẹ́ takuntakun láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.’ Báyìí ni Akpabio ṣe gba Oluyede sí ipò ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ológun.
Bí a bá léégún ẹni ó jòó tí a tún wá ní kò jó mọ́, baba ta ló le múni síi?
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fagi lé ìdáríjì àti ìdásílẹ̀ tó ṣe fún Maryam Sanda àti àwọn ọ̀daràn márùndínlọ́gọ́jọ mìíràn.
Èyí jáde lẹ́yìn tí àwọn aráàlú bu ẹnu àtẹ́ lu ìdáríjì yìí pé ó burú jáì, wọ́n ní àwọn ọ̀daràn paraku bíi apààyàn, olóògùn olóró, adigunjalè, ajínigbé àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ni ààrẹ dá sílẹ̀ nígbà tí àwọn tó jí gààrí nígbà tí ebi fẹ́ pa wọ́n kú ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Ọjọ́ kọkànlá, oṣù Ọ̀wàrà ni orúkọ àwọn ẹni náà jáde tí àwọn aráàlú sì tàbùkù rẹ̀, ní báyìí, ààrẹ ti fagi lé ọ̀pọ̀ àwọn orúkọ náà nínú àtẹ̀jáde tí Bayo Onanaga; ẹni tó jẹ́ olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí gbé jáde.
Nínú rẹ̀ la ti kà pé ààrẹ ti yọ orúkọ àwọn tí wọ́ ní ẹ̀sùn ìpànìyàn, ìdigunjalè, ìgbé-òògùn-olóró àti àwọn ọ̀ràn ńlá mìíràn kúrò nínú àwọn tí yóò dá sílẹ̀ nígbà tí àwọn tó ní ẹ̀sùn kéèkèèké yóò gba ìdásílẹ̀ náà.
Àwọn èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ni yóò gba ìdásílẹ̀ náà báyìí. Wàyí o, Maryam Sanda tí wọ́n ti dájọ́ ikú fún tẹ́lẹ̀ yóò lo ọdún méjìlá lẹ́wọ̀n báyìí.
Kòkòrò kò jẹ́ a gbádùn obì tó gbó:
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ààbò ojú pópó ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ogun ti dágbére fáyé lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́.
Florence Okpe ti wà lórí àìsàn latí ọjọ́ pípẹ́ àmọ́ kìí ṣe pé ó dá a dùbúlẹ̀, wọ́n fún un láàyè níbi iṣẹ́ láti lọ tọ́jú ara rẹ̀, nígbà tí ara rẹ̀ kò dá ni ó lọ sí ìlú rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Cross River fún itọ́jú àmọ́ ó padà kú sí ilé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Ọ̀wàrà.
Àwọn ẹbí Florence ló túfọ̀ rẹ̀ fún ilé iṣẹ́ ààbò ojú pópó tí àwọn sì túfọ̀ rẹ̀ síta.
Ilé iṣẹ́ ààbò ojú pópó ṣe àpèjúwe Florence gẹ́gẹ́ bíi èèkàn ní ilé iṣẹ́ náà, ó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bíi iṣẹ́ ó sì kó ipa rere láwùjọ.
Òṣèlú:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀rí; Yahaya Bello ti ṣe àpèjúwe ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán láti tún Nàìjíríà ṣe.
Yahaya sọ èyí lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùmáwòrán pé bí a bá ń retí kí Ọlọ́run ó sọ áńgẹ́lì kalẹ̀ láti ojú ọ̀run kí ó sì fi ìyẹ́ fò wọ Nàìjíríà, a ó dúró pẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ti sọ áńgẹ́lì náà kalẹ̀ fún wa tipẹ́ àwa la ò kíyèsí. Ta ni áńgẹ́́lì náà? Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ láti tún orílẹ̀-èdè yìí ṣe.
Ó ti pẹ́ tí a ti ń retí olùgbalà tí yóò tún Naìjíríà ṣe, áńgẹ́lì wo ló tún ju Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ? Ó yọ owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ṣètò èyáwó kàwé, ó ṣe àtúntò ẹ̀sẹ́wó owó òkèrè, ó ṣe àwọn òfin tó pawó wọlé sápò ìjọba àti aráàlú, ẹni tó bá ń retí iṣẹ́ ìyanu nìkan ni yóò sọ pé Tinubu kò ṣe tó, ààrẹ kan ò tún gbọdọ̀ ṣe ju báyìí lọ.
Ṣáájú ọdún 2015 ni a ti ń bèèrè fún Nàìjíríà titun ní èyí tí ayé ó dẹ gbogbo èèyàn lọ́rùn, gbogbo ohun tí a ń fẹ́ náà ni ààrẹ ń ṣe lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ kò le retí kí ó ṣe gbogbo rẹ̀ tán lẹ́ẹ̀kan náà nítorí pé ìlú ti bàjẹ́ jìnnà kí Tinubu ó tó gba ìjọba.
Èmi yóò maáa ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Tinubu nítèmi nítorí pé mom ọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe, kò ṣe é ṣe fún ààrẹ láti ṣe gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà mo sì nírètí pé yóò ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.
Ohun tí a ń fẹ́ lọ́jó¸iwájú ni pé nígbà tí ààrẹ ó bá fi parí ìṣejọba ẹlẹ́ẹ̀kejì, yóò fi àwọn ọmọlẹ́yìn rere lélẹ̀ tí yóò máa tọ ipasẹ̀ ààrẹ tí wọn yóò sì má atẹ̀lé ìlànà ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní èyí tí yóò jẹ́ pé irú àwọn èèyàn rere bíi èmi àti àwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-ède Nàìjíríà dénú ni yóò má abọ́ sípò ààrẹ.
Lọ́jọ́ tònìí, inú mi dùn pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Tinubu, ayọ mi kún, bí ẹ bá sì wo ìṣejọba mi nígbà tí mo wà nípò, ẹ ó ríi pé àwọn iṣẹ́ rere tí mo ṣe ń tọ̀ mí lẹ́yìn – èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Yahaya Bello sọ.



