Ọkọ̀ akérò kan tó kó àwọn èèyàn mẹ́rìndínlógún ló lọ kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò Daf kan ní ojú ọ̀nà ibùdókọ̀ Atura tó wà ní Badagry.
Àwọn èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn yòókù farapa yánnayànna.
Adebayo Taofiq; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fụn ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ LASTMA ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé àwọn èèyàn mẹ́jọ ni wọ́n gbé ẹ̀mí mìn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nínú ìjàm̀bá náà.
Ohun tó ṣe okùnfà ìjàm̀bá náà gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé awakọ̀ ọkọ̀ akérò náà sá eré àsápajúdé ló fà á tó fi lọ kó sí abẹ́ ọ̀kọ̀ tírélà iwájú rẹ̀.
Ilé ìwòsàn ìjọba Badagru ni wọ́n kó àwọn tó kú àti àwọn tó farapa náà lọ.
ÌJÀM̀BÁ ỌKỌ̀ GBA Ẹ̀MÍ ÀWỌN ÈÈYÀN MẸ́TA LÓJÚ Ọ̀NÀ MÁROSẸ̀ ÈKÓ SÍ ÌBÀDÀN.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ kan tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn ti mú ẹ̀mí àwọn èèyàn mẹ́ta lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ogun; Babatunde Akinbiyi ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé ìjàmbá náà wáyé ní Ogere.
Ọkọ̀ mẹ́rin ló forígbarí nínú ìjàm̀bá náà, ọkọ̀ àjàgbé kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì wọ́ àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́rin pọ̀ mọ́ ara wọn.
Àwọn èèyàn mẹ́ta ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí a kò tíì le sọ pàtó iye àwọn èèyàn tó farapa.
Ìjàmbá iná:
INÁ JÓ ILÉ IṢẸ́ IYABO OJO TÓ WÀ NÍ ÈKÓ.
Iná sẹ́yọ ní ilé iṣẹ́ gbajúgbajà òṣèrébìnrin ilẹ̀ yìí, ìyá ìyàwó tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iyabo Ojo.
Nínú fọ́nrán kan tó fi sí ojú òpó Instagram rẹ̀ ni Iyabo Ojo ti ṣe àlàyé pé aago méje ìrọ̀lẹ́ àná, ọjọ́ ìṣẹ́gun ni iná náà sẹ́yọ, kò sí ẹni tó fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Iyabo Ojo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ta mọ́ra àti ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó kú àgbàálẹ̀ òun.
Ó wí pé pẹ̀lú àtìlẹyìn Ọlọ́run, òun yóò bọ́ sípò padà lákọ̀tun.
Ìròyìn òkèrè:
ÌJỌBA ORÍLẸ̀-ÈDE AMẸ́RÍKÀ ṢE ÀGÉKÚRÚ GBÈDÉKE ÌWÉ ÌRÌNNÀ SÍ OṢÙ MẸ́TA.
Ìròyìn tó gbóná fẹli láàárọ̀ òní ni ìgbésẹ̀ tí ìjọba orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà gbé lórí ìwé ìrìnnà àwọn ọmọ orílẹ-ède Nàìjíríà.
Ìgbésẹ̀ náà ni pé àṣẹ ìwé ìrìnnà fún àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà kò ju oṣù mẹ́ta lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí àǹfààní àti lọ lẹ́ẹ̀mejì.
Ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà tí ó bá fẹ́ lọ sí Amẹríkà kò ní lò ju oṣù mẹ́ta lọ tí ìwé ìrìnnà rẹ̀ ó fi parí iṣẹ́.
Àwọn aláṣẹ náà wí pé gbogbo ìwé ìrìnnà tí wọ́n ti fi orúkọ sílẹ̀ fún ṣáájú ọjọ́ kẹjọ, oṣù Agẹmọ yìí kò ní ìpín nínú òfin titun yìí.
Ìjọba Amẹ́ríkà ṣe àlàyé pé àwọn kò fẹ́ kí ìlú àwọn ó di irú wá ògìrì wá ni àwọn ṣe gbé òfin titun yìí kalẹ̀.
Ní ìpínlẹ̀ Anambra:
ỌMÚ OBÌNRIN NI WỌ́N KÁ MỌ́ SAMUEL LỌ́WỌ́ NÍ ANAMBRA.
Arákùnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Samuel Eze ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tí wọ́n bá odidi ọmú obìnrin kan lọ́wọ́ rẹ̀.
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá ojú pópó tí wọ́n ń yẹ ẹrù àwọn èèyàn wò ló dá Samuel dúró ní ojú ọ̀nà Jude Onyekwere, Awada ní Obosi ìpínlẹ̀ Anambra. Wọ́n tú ẹrù rẹ̀ wọ́n sì bá odidi ọmú òbìnrin kan tó ṣì tutù mini nínú ẹrù rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Samuel, kò rí àlàyé kan ṣe ní pàtó, ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí.
Tochuku Ikenga; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀.
Ètò ẹ̀kọ́:
ỌDÚN MẸ́RÌNDÍNLÓGÚN NI GBÈDEKE ỌJỌ́ ORÍ TITUN FÚN ÌWỌLÉ-Ẹ̀KỌ́ GÍGA.
Ìjọba àpapọ̀ ti dá gbèdéke ọjọ́ orí titun fún àtiwọ ilé ìwé gíga báyìí. Akẹ́kọ̀ọ́ tí yóò wọ ilé ìwé gíga gbọdọ̀ pé ọmọ́ ọdún mẹ́rìndínlógún.
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́; Dọ́kítà Tunji Alausa ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ níbi àpéjọ àjọ JAMB tó wáyé ní Abuja.
Bákan náà ló wí pé àwọn adarí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ tó bá ṣe màdàrú ọjọ́ orí yóò fi ojú winá òfin.
Osá já!
OLÚBÀDÀN TI ÌBÀDÀN; ỌBA OLAKULEHIN TI WÀJÀ.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ báyìí ni pé Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn; Ọba Owolabi Olakulehin ti wàjà ní ẹni àádọ́rùn-ún ọdún.
Ọba Olakulehin ni Olúbàdàn ẹlẹ́ẹ̀kẹtàlélọ́gọ́rin. Ọjọ́ kejìlạ́, oṣù Agẹmọ, ọdún tó kọjá ni Ọba Olakulehin gorí àpèrè gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn, ó ku ọjọ́ péréte kí Ọba pé ọdún kan lórí ìtẹ́ ni ọba wàjà yìí.
Gómìnà Seyi Makinde ló gbé ọ̀pá àṣẹ lé Ọbá Olakulehin lọ́wó lọ́jọ́ náà, gbogbo àwọn ọ̀tọ̀kùùlù ìlú ni wọ́n péjúpésẹ̀ sí gbọ̀gán Mapo níbi tí ìwúyè náà ti wáyé.
Lẹ́yìn Olúbàdàn Yesufu Oloyede Asanike, Ọba Olakulehin ni Olúbàdàn tó gbé ní ààfin tó rẹwà tí wọ́n ṣe lọ́jọ̀.
Ní báyìí, ọba ti wàjà, ipò Olúbàdàn ti ṣí sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún kan tí a jẹ oyè náà.
TA NI IPÒ OLÚBÀDÀN TỌ SÍ LẸ́YÌN TÍ ỌBA OLAKULEHIN WÀJÀ?
Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ pé ètò àti àlàkalẹ̀ wà fún jíjẹ oyè Olúbàdàn, ẹni tó kàn náà ni Rasheed Ladoja; ẹni tó ti fi ìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ gẹ́gẹ́ bíi ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́.
Ẹni tí yóò jẹ Olúbàdàn gbọdọ̀ wà ní orí ìtò ipò Balógun àti Ọ̀tún Ìbàdàn.
Níwọ̀n ìgbà tó ti jẹ́ pé orí ìtò Balógun ni Olúbàdàn Olakulehin ti wá, ìtò Ọ̀tún ni ipò náà kàn báyìí. A gbọ́ pé Rasheed Ladoja ni àgbà ní ipò yìí nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé òun ló kàn láti jẹ́ Olúbàdàn báyìí.



