Ọ̀sẹ̀ kẹta rèé tí tọkọ-tayà ṣègbéyàwó, tí wọ́n filé pọn ọtí, fi ọ̀nà rokà; tí inú ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ n dùn ṣìkìn fún wọn, tí ẹbí àti ará n wúre pé ọkọ yóò gbó, ìyáwó yóò kùtà, pé ẹ̀yìn ìyàwó kò ní mẹní, pé lẹ́yìn oṣù mésàn án, a ó wá b’áwọn gbọ́wọ́ ṣíbí ìbejì lẹ́yìn ti ìyàwó ti finúṣoyún yóò fẹ̀yìn gbọ́mọ pọ̀n, pé tọkọ tayà yóò gbó kùjẹ́-kùjẹ́ ṣùgbọ́n ikú dóró, ikú ṣebí, ikú kò gbowó,ikú kò gbobì, ikú kọ̀ kò ṣe é tù lójú, ikú wólé ọlá, ikú sọ ilé ọlá di ahoro.
Ìjàmba iná yìí tún dá ẹ̀mí Mẹkáníìkì Olóòtú ìwé Ìròyìn EAGLE légbodò lọ́jọ́ yìí. DOTUN OLADAPO n fi tomi ojú-tomi ojú sọ lórí TVC NEWS bí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣe banilọ́kànjẹ́ gidigidi, nítorí ṣe ni ROTIMI ADELEYE ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọkọ̀ TOYOTA ìyàwó mi tán ni, Ó sì sọ pé kí n wá yẹ̀ ẹ́ wó pé ó ti n ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mò n gbọ́ tí Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ náà n kígbe ‘Ọkọ̀ yìí kò ní ìjánu!’ a ò tilẹ̀ tètè gbọ́ nítorí fèrèsé wà ní títì pa ṣùgbọ́n nígbà tí a máa fi gbọ́, ó ti pẹ́ jù , ní mo bá n ké tantan fún ROTIMI ADELEYE kó kúrò lójú ọ̀nà àmọ́ kò gbọ́, àṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rin ìhòhò wọ ọjà.
Ní bàyìí, àwọn Aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ kàn ti n ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. A gbọ́ pé ènìyàn márùn-ún ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èrò tètè dù ẹ̀mí wọn lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Gbàgádà ṣùgbọ́n àìsàn ni a rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe.
Èlòmìíràn tó tún bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná náà lọ ní ọ̀gbẹ́ni AKINTAYO AKINJOYE. Kí Olúwa bá wa dáwọ́ ibi dúró nílẹ̀ yìí.
Ọ̀sẹ̀ kẹta rèé tí tọkọ-tayà ṣègbéyàwó, tí wọ́n filé pọn ọtí, fi ọ̀nà rokà; tí inú ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ n dùn ṣìkìn fún wọn, tí ẹbí àti ará n wúre pé ọkọ yóò gbó, ìyáwó yóò kùtà, pé ẹ̀yìn ìyàwó kò ní mẹní, pé lẹ́yìn oṣù mésàn án, a ó wá b’áwọn gbọ́wọ́ ṣíbí ìbejì lẹ́yìn ti ìyàwó ti finúṣoyún yóò fẹ̀yìn gbọ́mọ pọ̀n, pé tọkọ tayà yóò gbó kùjẹ́-kùjẹ́ ṣùgbọ́n ikú dóró, ikú ṣebí, ikú kò gbowó,ikú kò gbobì, ikú kọ̀ kò ṣe é tù lójú, ikú wólé ọlá, ikú sọ ilé ọlá di ahoro.
Dozie àti Joan ṣàgbákò ikú òjijì níbi ìjàmbá afẹ́fẹ́ iná gáàsì lórí afárá Ọ̀tẹ́dọlá tó wà láàrín Èkó sí Ìbàdàn. Ọjọ́ tí wọ́n padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ìnáwó ìgbéyàwó ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn kò lọ mọ́, èyí dá ìpòruru ọkàn sílẹ̀ fún òbí, ẹbí àti ará. Wọ́n tilẹ̀ kọ́kọ́ ṣebí ọwọ́ àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ni wọ́n bọ́ sí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà lọ sí ilé ìpòkúmọ́ BURNS CENTER ní Gbàgádà àti YABA kí wọ́n tó rí àjókù wọn ní ojọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí.
Nọ́nbà ọkọ̀ ni wọ́n rí lára ọkọ̀ tó jóná keérú. Alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní déédé agogo mẹ́jọ kọjá díẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Tánkà tó n gbé afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná ṣubú lulẹ̀ gbìì lórí afárá rànyìnrànyìn, ìbó ṣe n mú ilé, bẹ̀ẹ́ ó n mú ọkọ̀, eruku n sọ làùlàù. Iná náà ràn dé DE-TWIST DENTAL CLINIC látàrí ẹ̀rọ amúnáwá wọn tó wà nítòsí àti ilé ìjọsìn tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. Ọṣẹ́ kékeré kọ́ ni iná yìí ṣẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí.
Ìjàmba iná yìí tún dá ẹ̀mí Mẹkáníìkì Olóòtú ìwé Ìròyìn EAGLE légbodò lọ́jọ́ yìí. DOTUN OLADAPO n fi tomi ojú-tomi ojú sọ lórí TVC NEWS bí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣe banilọ́kànjẹ́ gidigidi, nítorí ṣe ni ROTIMI ADELEYE ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ọkọ̀ TOYOTA ìyàwó mi tán ni, Ó sì sọ pé kí n wá yẹ̀ẹ́wó pé o ti n ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni mò n gbọ́ tí Dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ náà n kígbe : Ọkọ̀ yìí kò ní ìjánu! a ò tilẹ̀ tètè gbọ́ nítorí fèrèsé wà ní títì pa ṣùgbọ́n nígbà tí a máa fi gbọ́, ó ti pẹ́ jù , ní mo bá n ké tantan fún ROTIMI ADELEYE kó kúrò lójú ọ̀nà àmọ́ kò gbọ́, àṣọ ò bá ọmọ́yẹ mọ́, ọmọ́yẹ ti rin ìhòhò wọ ọjà.Dozie àti Joan ṣàgbákò ikú òjijì níbi ìjàmbá afẹ́fẹ́ iná gáàsì lórí afárá Ọ̀tẹ́dọlá tó wà láàrín Èkó sí Ìbàdàn. Ọjọ́ tí wọ́n padà sẹ́nu iṣẹ́ lẹ́yìn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ìnáwó ìgbéyàwó ni ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn kò lọ mọ́, èyí dá ìpòruru ọkàn sílẹ̀ fún òbí, ẹbí àti ará. Wọ́n tilẹ̀ kọ́kọ́ ṣebí ọwọ́ àwọn gbọ́mọgbọ́mọ ni wọ́n bọ́ sí. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà lọ sí ilé ìpòkúmọ́ BURNS CENTER ní Gbàgádà àti YABA kí wọ́n tó rí àjókù wọn ní ojọ́ Rú ọ̀sẹ̀ yìí.
Nọ́nbà ọkọ̀ ni wọ́n rí lára ọkọ̀ tó jóná keérú. Alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní déédé agogo mẹ́jọ kọjá díẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Tánkà tó n gbé afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná ṣubú lulẹ̀ gbìì lórí afárá rànyìnrànyìn, ìbó ṣe n mú ilé, bẹ̀ẹ́ ó n mú ọkọ̀, eruku n sọ làùlàù. Iná náà ràn dé DE-TWIST DENTAL CLINIC látàrí ẹ̀rọ amúnáwá jẹnẹrétọ̀ wọn tó wà nítòsí àti ilé ìjọsìn tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀. Ọṣẹ́ kékeré kọ́ ni iná yìí ṣẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu yìí.
Ní bàyìí, àwọn Aláṣẹ tí ọ̀rọ̀ kàn ti n ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí. A gbọ́ pé ènìyàn márùn ún ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ pé àwọn èrò tètè dù ẹ̀mí wọn lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Gbàgádà ṣùgbọ́n àìsàn ni a rí wò, a ò rí ti ọlọ́jọ́ ṣe. Èlòmìíràn tó tún bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná náà lọ ní ọ̀gbẹ́ni AKINTAYO AKINJOYE. Kí Olúwa bá wa dáwọ́ ibi dúró nílẹ̀ yìí