Ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé afẹ́fẹ́ tí ọkọ̀ le mú sàgbára CNG ló pàdánù ìjánu rẹ̀ ní ìtòsí afárá Karu ní Abuja.
Ìrọ̀lẹ́ òní Ọjọ́rú ni ìjàmbá yìí wáyé, ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì lọ kọlu ọkọ̀ mìíràn, kíá ni iná sẹ́yò tí ó sì ràn kárí láàárín ìṣẹ́jú àáyá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí iná yìí ká mọ́ inú ọkọ̀ ni iná yìí ti mú balẹ̀, a kò tíì le sọ ní pàtó iye ènìyàn tí ó ti bá ìsẹ̀lẹ̀ yii rìn.
Nínú fọ́nrán tí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan gbé jáde ni àwọn èèyàn ti ń kígbe tí wọ́n sì ń jó nínú iná náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àti ẹ̀ka mìíràn tọ́rọ̀ kàn ti wà níbẹ̀.
Iná jó ní ibùdókọ̀ Ilorin.
Alagbede ni orúkọ ibùdókọ̀ yìí, ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Ìlọrin ló wà, nínú àwọn ọkọ̀ àjàgbé méjìlélógójì tó wà níbẹ̀, mẹ́ta ló jóná kọjá mímọ̀. Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ kólẹ̀-kódọ̀tí kan tó wá kólẹ̀ ló gbaná ni ìta ibùdókọ̀ yìí, kíá ni iná yìí ràn mọ́ àwọn ọkọ̀ inú ibùdókọ̀ yìí tó sì jó mẹ́ta kan éérú.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Hassan Adekunle fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀. Ó wí pé àwọn ta mọ́ra kán tí àwọn gba ìpè náà àwọn sì kojú rẹ̀ ló jẹ́ kó mọ ní ọkọ̀ mẹ́ta tó jóná nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nígbà tí èyí ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kwara, ọjà ìrẹsì Wurukum tó wà ní ìpínlẹ̀ Benue náà sọ iná dorin, lásìkò tí kò sí oúnjẹ nílùú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpò ìrẹsì tún jọná, èyí ò ha pọ̀jù bí? A rí ìròyìn náà gbà pé iná sẹ́yọ ní ọjà ìrẹsì tó wà ní Wurukum ní ìtòsí afárá odò Benue ní Makurdi tíí ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Benue.
Ìrẹsì tó jóná kọjá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà. Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tilẹ̀ ṣaájò àmọ́ ṣe ni iná náà gori ilé fẹjú toto ni, kò ní òun ò run gbogbo àwọn ìsọ̀ ìrẹsì náà.
Ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́jà náà tó pe orúkọ rẹ̀ ní Mercy wí pé ìrẹsì tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni ó jóná nísọ̀ oun pẹ̀lú àwọn irin iṣẹ́ tí wọ́n fi ń pàkúta inú ìrẹsì.
Jeremiah náà wí pé òun kò tilẹ̀ mọ ibi tí òun yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn ọjà òun jáde lòun ṣe ń wòó títí tó fi jóná tán.
Alága ọja Wurukum; Yerva Igyar wí pé àwọn irin iṣẹ́ bíi mẹ́fà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpò ìrẹsì ló jóná keérú.
Bákan náà ni wọ́n wí pé kìí ṣe wáyà iná ló fa iná náà nítorí pé àwọn kò lo iná ọba rárá ní ọjà náà. Wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Hyacinth Alia fún ìrànlọ́wọ́.
Nígbà tí iná ń ṣe ọṣẹ́ tirẹ̀ lápá kan, àwọn èèyàn náà ò kọ̀ láti má fi ọwọ́ ara wọn fa wàhálà. Ìjà ilẹ̀ àtọdún márùn-ún tún gbérí ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ní èyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti bọ́ lórí rẹ̀. Ìròyìn tí ọwọ́ wa tẹ̀ náà ni pé àwọn ará abúlé Umuobor-Akaeze àti àwọn ará Ishiagu tún ti bá ara wọn wọ̀yá ìjà, ìjọba ìbílẹ̀ Ivo ní ìpínlẹ̀ Ebonyi ni àwọn abúlé méjì yìí wà.
Ilẹ̀ Elueke tó pa àwọn abúlé méjéèjì yìí pọ̀ ni wọ́n ń jà sí. Ó ti lé ní ọdún márùn-ún tí wọ́n ti wà lẹ́nu rẹ̀, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti sùn lórí ìjà ilẹ̀ yìí.
Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí ni ó tún burẹ́kẹ nígbà tí wọ́n dá ọkùnrin kan àti obìnrin kan tí wọ́n ń lọ lórí ilẹ̀ yìí dúró tí wọ́n sì pa wọ́n, èyí ló tún mú kí àwọn ará kejì dìde ogun tí ọpọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àti dúkíà sì ti ṣòfò lórí rẹ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi; Francis Nwifuru ti kéde ilẹ̀ náà ní àìwọ̀ fún àwọn ará abúlé méjéèjì báyìí ó sì tún gbé ikọ̀ dìde láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ebonyi sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Joshua Ukandu pé àwọn kò gba ìfisùn ìpànìyàn Kankan láti ọ̀dọ ẹnikẹ́ni.
Kí la máa rí tí a kò ní fi tó o yín létí? Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa ìkọlù tó wàyé ní ìpínlẹ̀ Plateau? Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé àwọn àgbẹ̀ abúlé Shimankar ní ìjọba ìbílẹ̀ Shendam, ìpínlẹ̀ Plateau ké tantan lórí bí àwọn Fulani ṣe run oko wọn pátápátá.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ẹ̀ya Fulani tako orò tí àwọn onílùú ṣe, èyí ló bí wọn nínú tí wọ́n fi ya wọ oko wọn, wọ́n gé ọdẹ inú oko náà lọ́wọ́ féú wọ́n sì ti iná bọ gbogbo oko náà. Wọ́n lọ káàkiri àwọn ilẹ̀ oko lọ ṣe ọṣẹ́ yìí tó fi já sí pé kò sí àgbẹ̀ kan tó rí nǹkan kan mú lóko rẹ̀.
Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe èyí tán ni wọ́n tún lọ ká àwọn ará abúlé náà mọ́lé, wọn kò pa ẹnikẹ́ni àmọ́ wọ́n sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara.
Tobias; ọ̀kan lára àwọn àgbẹ̀ abúlé Shimankar bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé gbogbo oko elégédé òun ló jóná gúrúgúrú, àti oko rẹ̀ àti ti àwọn ẹbí rẹ̀ méjì mìíràn ló jóná kanlẹ̀.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau; Emmanuel Olugbemiga Adesina fi ọ̀rọ̀ ìdákànró ránṣẹ́ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà pé òun ti ṣètò gbogbo alàkalẹ̀ láti mú kí àlàáfià ó padà sí ìlú. Ó rọ àwọn èèyàn náà láti gba àlàáfíà láàyè.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Plateau náà fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn ará abúlé náà.
Iná lọ́tùn-ún ìjà ilẹ̀ lósì, àwọn agbésùnmọ̀mí náà ń ṣọṣẹ́ tiwọn lọ ní pẹrẹu, àfi kí Elédùmarè ó bá wa dáwọ́ ìtẹ̀jẹ̀ẹ́lẹ̀ dúró.
Discussion about this post