Àwọn léèkàn – léèkàn àti lóókọ- lóókọ nínú ètò ìṣèlú ń kópa tiwọn nínú ètò ìdìbò sí ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀șun lónìí ní ibùgbé kálukú wọn. Nínú wọn ni a ti rí gómìnà ìjẹrin ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Ọlọ́lá Ọlágunsóyè Oyinlọlá tó dìbò tirẹ̀ ní ọjọ́ Sátidé, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù kejì ọdún yìí 2025.
A rí i gbámú pé gómìnà tẹ́lẹ̀ náà dìbò ní ibùdó ìdìbò rẹ̀ ní Ọba Ojomu, wọ́ọ̀dù kìn-ínní, Òkukú ní ìjọba ìbílẹ̀ Odò-ọ̀tìn. Bákan náà ni a gbọ́ ọ pé abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ Așòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Olóyè Adéwálé Ẹgbẹ́dùn náà ṣe ojúṣe rẹ̀ ní ibùdó ìdìbò tóun náà wà.
GÓMÌNÀ ADÉLÉKÈ GBÓRÍYÌN FÚN ÀJỌ ELÉTÒ ÌDÌBÒ :
Gómìnà Adémọ́lá Adélékè náà dìbò tiẹ̀ ni ojútò kẹsàn-án, Ṣàgbà Abógundé, ní wọ́ọ̀dù kejì ní Àríwá Ẹdẹ. Nígbà tóun àtàwọn èèyàn rẹ̀ kọ́wọ̀ọ́ rìn dé ibi ojútò ìdìbò náà, tó ṣe ojúṣe rẹ̀ tán, tó sì rí i bí gbogbo nǹkan ṣe tùbà-tùṣẹ, ó gbóríyìn fáwọn elétò ìdìbò ipinlẹ̀ Ọ̀ṣun ( OSSIEC) fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe láti rí i pé àlàáfíà jọba ní àkókò ìdìbò náà
Adélékè gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn wọ́ọ́rọ́wọ́, kí wọ́n sì jẹ́ kí àlàáfíà jọba.
” Ètò náà lọ ní ìrọwọ́-ìrọsẹ̀. Mo ti bá àwọn èèyàn mi sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n gba àlàáfíà láàyè ; kí wón sì tú yááyáá jáde wá dìbò lálàáfíà. A à gbọ́dọ̀ fún wọn lọ́rọ̀ sọ pé rògbòdìyàn wà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún.
Bí àwọn agbófinró ṣe pariwo kùkù-lajà tó, pàápàá jù lọ àwọn Ọlọ́pàá ilẹ̀ Nàìjíríà (NPF) pé àìbalẹ̀ ọkàn wà, ìdìbò náà ń tẹ̀ síwájú láìbèṣù-bẹ̀gbà, àwọn olùdarí sì ń fi ojú àgbà tẹ̀lé bí ohun gbogbo ṣe ń lọ
Ọ̀rọ̀ àwọn alátakò wá padà já sí ìhàlẹ̀ lásán, wọ́n léríléka pé àwọn yóò da gbogbo ìlú rú bí ìdìbò náà bá fi wáyé lónìí, kódà, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pàṣẹ fún ìjọba ìpínlẹ̀ Osun pé kó fagi lé ìdìbò náà nítorí àwọn tí wọ́n léríléka yìí, Gómìnà Adeleke kò tiẹ̀ rí tiwọn rò, ẹ̀yìn igbá ni wọ́n yín àgbàdo sí.
Ìdìbò náà wáyé pẹ̀lú ìrọ̀rùn, a kò tíì gbọ́ rògbòdìyàn kankan lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí, yègèdè wọn.