Ní báyìí, Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun tó ti ń tùbà-tùṣẹ tẹ́lẹ̀ ti di ibùdó ẹ̀rù-jẹ̀ẹ̀ fún aráàlú nítorí wàhálà tó Bẹ́ sílẹ̀ láàrin Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Olóyè Adégbóyega Oyetọ́lá tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, àti Gomina Adélékè ti Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wà lórí àlééfà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun
Ohun tó sì fa ìbẹ̀rù-bojo yìí ni ìgbésẹ̀ tí Olóyè Oyétọ́lá fẹ́ẹ́ gbé láti pàṣẹ fún àwọn alága ijoba ìbílẹ̀ tí wọ́n lé kúrò lórí àlééfà pé kí wọ́n padà sí i iṣẹ́ wọn ní tìpá-tìkúùkù, nítorí ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ kò-tẹ̀-mi-lọ́rùn tí àwọn ẹgbẹ́ APC àti PDP ń lọ́ lọ́rùn mọ́ra wọn lọ́wọ́ .
Olóyè Oyetọ́lá ní kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àná Padà sí orí àga lónìí, ojọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù yìí ( 17/02/25. Nínú ìpàdé tí gómìnà Adélékè ṣe pẹ̀lú àwọn oníròhìn ní àná ọjọ́ Àìkú-16/02/25,ó fẹ̀sùn kan Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Adégbóyega Oyetọ́lá pé ó ń pète-pèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, ó sì fẹ́ lo àwọn agbófinró ṣáájú àti láti ṣe atọ́nà awon alága àti Káńsẹ́lọ́ àná náà lọ sí ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ kálukú.
Gómìnà Adélékè șàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gbẹ́ni Oyetọ́lá jẹ́ ìbátan sí Ààrẹ Tinubu, ìyẹn ò fún un ní agbára kankan láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Adélékè ní ” àwa ò ní í gbà pé kí ẹnikẹ́ni gorí ìjọba ìbílẹ̀ láìjẹ́ pé a bá lo ìlànà ìdájọ́ òdodo tàbí ílànà ìyànsípò tó bófin mu nípa ìlànà ètò ìdìbò”
Ademola Adélékè ní òun ò mọ nǹkan kan nípa lílé tí wọ́n lé àwọn alága àná kúrò lórí àlééfà. Ó ní ilé ẹjọ́ ti yọ ọwọ́ kí-là-ń-kó wọn kúrò kóun tóó dórí oyè. Ó ní ó ṣe òun láàánú láti fi tó Ààrẹ àti àwọn èèyàn àwùjọ létí pé Oyetọ́lá ti parí gbogbo ètò látidá rògbòdìyàn sílẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé – 17/02/25. Pé ó sì ti pàṣẹ oníkùùmọ̀ fún àwọn ẹ̀ka agbófinró láti gbé ìgbésẹ̀ tí kò bójú mú un. Oyetọ́lá ń ṣe èyí nítorí pé ó jẹ́ ìbátan Tinubu, ó sì ń pakuru mọ́ àwọn agbofinro láti tẹ̀ lé àṣẹ oníkùùmọ̀ rẹ̀.