Obìnrin kan ní ìpínlẹ̀ Ogun ti bí ọmọ ìbẹrin sílé ìwòsàn, òun àti ọkọ rẹ̀ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí ìtọ́jú àwọn ọmọ náà.
Ọmọ márùn-ún ni arábìnrin Mutiat Olateju ti bí tẹ́lẹ̀ kí ó tó wá bí ìbẹrin yìí. Ó ṣe àlàyé pé òjijì ni àwọn ọmọ náà bá òun àti ọkọ rẹ̀, wọn kò gbaradì fún ọmọ mẹ́rin rárá.
‘N kò fi orúkọ sílẹ̀ nílé ìwòsàn kankan fụn ìtọ́jú inú oyún náà, ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí rọbí ni wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn náà. Mo ti ya àwòrán oyún náà ṣáájú kí ń tó bímọ, ọmọ kan ni àwòrán náà gbé jáde àmọ́ nígbà tí mo ya òmíràn, ọmọ méjì ni ó rí kí n tó wá bi ìbẹrin yìí.
Ẹni ogóji ọdún ni mí, ọmọ márùn-ún ni mo ti bí tẹ́lẹ̀, èmi àti ọkọ mi ò ní agbára àti tọ́jú àwọn ọmọ mẹ́rin yìí, kí ìjọba dákun rọ̀ wá lọ́wọ́’.
Ọkọ ìyá ìbẹrin; ọ̀gbẹ́ni Oluwaseun Olateju náà kín ọ̀rọ̀ ìyàwó rẹ̀ lẹ́yìn pé òun kò ní le kó bùkátà àwọn ìbẹrin titun yìí pọ̀ mọ́ àwọn márùn-ún tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀, ipá rẹ̀ kò ká a. Mo kọ́ fẹ́ sá lọ tẹ́lẹ̀ àmọ́ mo tún èrò mi pa nítorí mo nígbàgbọ́ pé yóò dára.
Dọ́kítà tó gbẹ̀bí àwọn ọmọ náà nílé ìwòsàn FMC ìjọba tó wà ní Atan, ọta; Dọ́kítà Taofiq Ogunfunmilayo ṣe àlàyé pé oyún àwọn ọmọ náà ku ọ̀sẹ̀ mẹ́rin kó gbó dáadáa àmọ́ nítorí pé wọ́n jẹ́ mẹ́rin ni ó ṣe bíi ní ọ̀sẹ̀ méjìlélógbọ̀n. Bákan náà ni pé ipò tí ìyá àti àwọn ọmọ náà wà ń fẹ́ ìtọ́jú tó péye.
Ọ̀rọ̀ dọ́kítà Ogunfunmilayo tẹ̀síwájú pé àwọn kọ́ ló ṣe ìtọ́jú ìyá ìbẹrin nínú oyún, ìgbà tí ó ń rọbí ni wọ́n darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn wọn, iṣẹ́ abẹ ni wọ́n fi gbé àwọn ọmọ mẹ́rin náà jáde tí gbogbo wọn sì yè.
Ìyá wọn wà lálàáfíà, ara rẹ̀ sì ń mókun àmọ́ àwọn ọmọ náà kò gbó tó wọ́n sì ti kó wọn lọ sí ẹ̀ka ọmọdé níbi tí wọn yóò fi gba ìtọ́jú tó péye. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé méjì nínú àwọn ọmọ náà ń ṣe dáadáa àmọ́ àwọn méjì yòókù ń fẹ́ àmójútó gidi.
Ìyá ìbejì fúnra rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí ìtọ́jú àwọn ọmọ náà nípa owó ilé ìwòsàn àti àwọn ohun tí wọ́n nílò.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi ara pẹ́ ti arábìnrin Ikenna Obianeri tí òun náà bí ọmọ méje lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.
Ọdún 2023 ni arábìnrin Obianeri bí ọmọ méje àmọ́ mẹ́fà ló yè nínú wọn, òun àti ọkọ rẹ̀ ké gbàjarè lọ́dún náà, wọ́ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti ṣe ìrànwọ́ fún wọn lórí ìtọ́jú àwọn ọmọ náà pàápàá lórí owó ilé ìwòsàn tí iye rẹ̀ jẹ́ mílíọ́nù mọ́kàndínlógún.
Ọkọ obìnrin yìí; Celestine Uzodike bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́. Ó ṣe àlàyé pé ìbejì ni gbogbo àwòrán oyún tí àwọn ń yà fi hàn tí àwọn sì ń palẹ̀mọ́ fún ìbejì àfi ìgbà tí ó bí méje lẹ́èkan náà yìí.
Ọkùnrin méjì àti obìnrin márùn-ún ni àwọn ọmọ náà àmọ́ ẹyọkan nínú àwọn obìnrin náà kò yè, ló fi jẹ́ mẹ́fà ni gbogbo àwọn ọmọ náà. Mílíọ́nù kan náírà ni wọ́n rí gbá jọ nínú mílíọ́nù mọ́kàndínlógún náírà tí ilé ìwòsàn náà fẹ́ gbà.
Ọdún 2020 ni Uzodike àti Ngozi ṣe ìgbéyàwó ní ìpínlẹ̀ Anambra, kò ní oyún rí, oyún àkọ́ní rẹ̀ náà ló fi bí ìbeje yìí.
Ọ̀rọ̀ Uzodike tẹ̀síwájú pé òun náà kò bí ọmọ rí, ọmọ tí àwọn yóò kọ́ bí rèé àwọn náà sì ni wọn yóò jẹ́ àbígbẹ̀yìn, òun àti ìyàwó òun kò tún bímọ mọ́ lé àwọn ọmọ mẹ́fà yìí. Bákan náà ló wí pé ìyàwó òun kò lo òògùn, iṣẹ́ Ọlọ́run ni oyún àwọn ọmọ náà.
Ibi tó le sí ni pé ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni ó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí dípò ọ̀sẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí oyún ń lò níkùn aláboyún, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún un wọ́n sì gbé àwọn ọmọ náà jáde. Àwọn ọmọ náà kò gbó wọ́n sì gbọdọ̀ gba ìtọ́jú tó péye, inú agolo oyún àtọwọ́dá ni wọn yóò wà títí wọn yóò fi gbó.
Ilé ìwòsàn náà wí pé mílíọ́nù mẹ́ta ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba náírà ni iye tí yóò san lórí ọmọ kọ̀ọ̀kan tó bá wọ inú agolo náà ní èyí tí àpapọ̀ rẹ̀ ń pajúdé sí mílíọ́nù mọ́kàndínlógún náírà.
Oṣù méjì ni àwọn ọmọ náà yóò fi gba ìtọ́jú yìí, Uzodike ní òun ti gbá ilé àti ọ̀nà òun kò sì mọ èyí tí ó tún kàn ni òun ṣe ń rọ ìjọba láti gbé bùkátà yìí fún òun kkí wọn ó ran òun lówọ́ lórí ìtọ́jú àwọn ẹ̀jẹ̀ ọ̀run mẹ́fà yíì.
Ìyá ibẹfà náà ṣe àlàyé bí bíbí àwọn ọmọ náà ṣe lọ, ó ní nígbà tí ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí ní mú òun, gbogbo ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé òun lọ ni kò gba òun, wọ́n darí òun lọ síbòmíràn àwọn ìyẹn náà á tún darí rẹ̀ síbòmíràn pé àwọn kò le ṣe é.
Ètò ààbò tí kò fararọ kò jẹ́ kí ó le lọ sílé ìwòsàn tí wọ́n júwe fún un mọ́ lálẹ́ ọjọ́ náà àmọ́ wọ́n jí dé ibẹ̀ ni aago méje òwúrọ̀ wọ́n sì ṣe iṣẹ́ abẹ náà ní aago mẹ́sàn-án.
Kódà, wọn kò rí owó àsan-ánlẹ̀ san, àwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí ni o? dáwó jọ fún wọn tí àwọn dọ́kítà fi bèrẹ̀ iṣẹ́.
Ọdún 2023 ni ti Uzodike yìí wáyé, lọ́dún 2026 yìí, Olateju náà bí mẹ́rin lẹ́èkan náà. Ire á karị o!





