Kò din ni èèyàn méjìlá tí ibà LÁSÀ ti rán lọ sọ́run àpàpàǹdodo ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Èèyàn bíi mejìléláàádọ́fà ni ìjọba ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti lùgbàdì àìsàn náà, nígbà tí nnkan bí ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún ó dín méje èèyàn ló wà lórí akete àìsàn yíi.
Alábòójútó ètò ìsìrò bí nǹkan ṣe rí ló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ nígbà tó ń bá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń bójú tó Ìmọ́tótó ìlú, ní Akúrẹ́. Arákùnrin Àjàyí rọ àwọn òșìșẹ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò ìlera láti jẹ́ kí ayikà wọn mọ́ tónítóní láti lè kápá ìtànkálẹ̀ àrùn náà.
Ó fi yé wọn pé ìgbésẹ̀ kánkán gbọ́dọ̀ di gbígbé ní kíákíá. Bákan náà, alákòóso ètò ìlera ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó Ọ̀mọ̀wé Adenran Ikúòmọ̀la fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ bíi irínwó ni wọn ti fetí àwọn kọ́ látìgbà tí àìsàn yìí ti gbòde.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní Akúrẹ́, Ọ̀mọ̀wé Ikúòmọ̀la ní ìjọba àpapọ̀ àti àwọn lájọlájọ kan tí fi ẹ̀rọ tí yóò máa ṣe ayẹ̀wò àìsàn náà, tí yóò sì mú ìwòsàn rẹ̀ rọrùn. Ó fi dá won lójú pé ìjọba Ìpínlẹ̀ ń ṣiṣẹ́ kárakára láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn lájọlájọ lati dín ikú ọ̀wọwọ̀ọ́ kù láwùjọ wa.
Ìba lásà yìí gbòde lẹ́yìn tí ààrùn onígbáméjì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Sokoto.
Ó lé ní èèyàn mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ààrùn onígbáméjì ti rán níwo ẹṣin lẹ́nu ìgbà tó bẹ́ sílẹ̀. Àwọn tó ń gba ìtọ́jú lé ní ẹgbẹ̀rún.
Kọmísọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ Sokoto; Asabe Balarabe sọ̀rọ̀ ilẹ̀ kún. Ó wí pé àwọn ń sa gbogbo ipá wọn láti wa egbò dẹ́kun fún àjàkálẹ̀ ààrùn náà. Asabe jábọ̀ pé wọ́n ti kó oògùn àti abẹ́rẹ́ ránṣẹ́ sí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba gbogbo kí wọn ó máa fi ṣe ìtọ́jú àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́.
Bákan náà ló lu àwọn obìnrin àti àwọn aláboyún lọ́gọ ẹnu pé wọ́n káre lórí bí wọ́n ṣe ń lọ fún àyẹ̀wò ààrùn náà.
Ìjọba àpapọ̀ àti ìjọba Sokoto pawọ́pọ̀ láti dojú ìjà kọ ààrùn yìí kó le tètè kógbá wọlé.
Asabe kò ṣe aláìmámẹ́nuba àwọn àdojúkọ ẹ̀kà ètò ìlera. Lára àwọn àdojúkọ náà ni ipò tí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba wà, gbogbo ògiri ló ti dẹnu kọlẹ̀. Yàtọ̀ sí pé kò sí iná ọba láwọn ilé ìwòsàn náà, omi tí aláìsàn ó mu gan-an kò sí dépo ibùsùn tí yóò sùn lé. Èyí kò mọ́ pé àwọn nọ́ọ̀sì àti dọ́kítà kò pọ̀ tó, omi aláìsàn pọ̀ ju ọkà wọn lọ.
Pẹ̀lú gbogbo àwọn àdojúkọ yìí, Asabe ṣe ìlérí láti gbógun ti ààrùn onígbáméjì tó gbòde yìí ó sì rọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto láti wá nǹkan ṣe sí ipò àti àwọn àdojúkọ ilé ìwòsàn ìjọba gbogbo.
Bí a kò bá gbàgbé, kọ̀pẹ́kọ̀pẹ́ yìí ni àjàkálẹ̀ ààrùn HMPV gbilẹ̀ ní orílẹ̀-ẹ̀dẹ̀ China.
A mú ìròyìn àjàkálẹ̀ ààrùn náà wá fún yín pé ìjọba Nàìjíría kéde pé àwọn yóò ṣe àmójútó àwọn arìnrìnàjò láti ilẹ̀ China.
Àjàkálẹ̀ ààrùn titun tó bẹ́ sílẹ̀ ní China yìí fara pẹ́ kòrónà ọdún 2020, èémí ni ààrùn náà ń bá ṣiṣẹ́, HMPV ni orúkọ rẹ̀.
Ọ̀pọlọpọ̀ àwọn èèyàn ni ó ti lu ìgbàdí ààrùn yìí ní àríwá China, àwọn ọmọdé tí ọjọ́-orí wọn kò wọ ọdún mẹ́rìnlá ni ààrùn yìí bá fínra jù.
Àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé ti China bíi Hong-Kong, Taiwan àti Cambodia náà ti ní ìpín nínú ààrùn yìí àmọ́ kò tíì bu rẹ́kẹ lọ́dọ tiwọn bíi ti China.
Ní Àríwá China, nǹkan kò sẹnu re, gbogbo ilé ìwòsàn ti kún àkúnfàya, ọmọdé àti àgbà ni ààrùn náà ti mú balẹ̀.
Ìjọba China kéde lílo ìbomú, fífọ ọwọ́ lóòrèkóòrè àti ṣíṣe ìmọ́tótó àyíká láti dènà lílu ìgbàdì ààrùn HMPV náà.
Ọdún karùn-ún rèé tí Kòrónà pa àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù méje káàkiri àgbáyé, HMPV tún ti gbòde, a kò ní lu ìgbàdì ààrùn o.
HMPV gbilẹ̀ ní China, Lásà bá Nàìjíría lálejò, ẹ jẹ́ ká gbìyànjú láti ríi dájú pé àyíká wa wà ní tónítóní ní gbogbo ìgbà nítorí pé ìmọ́tótó ló le ṣẹ́gun ààrùn gbogbo.