Gómínà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fi àwọn baálẹ̀ àti àgbà ìjòyè mẹ́rìnlá jẹ ọba aládé ní òní; ọjọ́ kẹtàlá, oṣù Èrèlé.
Igbákejì gómínà; Bayo Lawal ló ṣojú gómínà níbi ayẹyẹ ìfinijoyè náà tó wáyé ní Oliveth Heights, ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Àwọn tó jẹ oyè ọba náà ni Alaaguo ti ilẹ̀ Aguo; Oba David Oyediran, Baba Eyaji ti ìlú Ọ̀yọ́; Oba Afonja Mukaila, Alajagba Ọ̀yọ́; Oba Samuel Odurinde, Ona-Isokun ti ìlú Ọ̀yọ́; Oba Isiaka Tella-Titiloye, Onimileke ti Imileke Ọ̀yọ́; Oba Fakayode Alowonle, Onigbudugbu ti Gbudugbu Ọ̀yọ́; Oba Salawu Oyeniran, Oloodu ti Ojongbodu; Oba Olaniyi Adegboye àti Alapa-Ara ti Apa-Ara; Oba Tijani Ajeigbe.
Àwọn yòókù ni Onidode ti Idode; Oba Oyeleke Yusuff. Iba Samu Ọ̀yọ́; Oba Lamidi Jimoh, Alago-Oja tiAgo-Oja; Oba Ganiyu Busari, Agbaakin Ọ̀yọ́; Oba Asimiyu Jimoh, Alakeitan ti Akeitan; Oba Jimoh Oyeleye àti Elepe ti Iseke; Oba Abel Oyekan.
Nínú ọ̀rọ̀ gómínà tí igbákejì rẹ̀ kà ni pé ìgbésẹ̀ yìí yóò mú kí ìṣèjọba ìbílẹ̀ ó túbọ̀ fi ẹsẹ̀ múḷ̀ láti mú ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú bá ilẹ̀ Yorùbá.

NATASHA TÚN WỌ̀YÁÀJÀ NÍ ILÉ ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN.
Natasha Akpoti-Uduaghan; aṣòfin tó ń ṣojú ẹ̀kun ààrin gbùngbùn Kogi tún wọ̀yáàjà pẹ̀lú aṣòfin mìíràn lónìí.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde ni a ti rí Natasha àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń kojú ara wọn ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé ọ́fíìsì aṣòfin náà.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ìpàdé ètò ìsùná tí wọ́n dá láàgo mẹ́wàá ti parí kí Natasha tó dé, ó yarí pé òun gbọ́dọ̀ fi ojú kan alága ìgbìmọ̀ náà; ìyẹn aṣòfin tó ń ṣojú ẹ̀kun ìwọ̀ òòrùn Borno; Titus Zam fún àlàyé lórí ìdí tí ìpàdé náà fi wáyé ṣaájú àkókò tí wọ́n dá.
Àwọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Titus kò gbà fún un, wọ́n dí i lọ́wọ́ láti wọ inú ọ́fíìsì Titus ni òun náà tutọ́ sókè tó sì fi ojú gbàá. Wọ́n jọ tahùn síra wọn àmọ́ a kò tíì le sọ ibi tó yọrí sí báyìí.

ÒKÚ ÈÈYÀN MÉJÌ NÍNÚ ỌKỌ̀ NISSAN NÍLÉ ÌWÒSÀN EVERCARE.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú tó pa àwọn méjì kan tí wọ́n bá òkú wọn nínú ọkọ̀ Nissan kan ní Lekki.
Àwọn méjì náà jẹ́ òṣìṣẹ́ Nollywood, iná títàn fún eré yíyà ni iṣẹ́ tiwọn, wọ́n lọ ya eré kan nílé ìwòsàn Evercare tó wà ní Lekki lásìkò tí wọ́n kú náà. Ekemini “GeeTee” Imeh àti èkejì rẹ̀; Ayodeji Walter Odediran ni àwọn tí wọ́n kú yìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé Ekemini àti Ayodeji ti parí iṣẹ́ wọn nínú ilé wọ́n sì bọ́ síta lọ jókòó sínú ọkọ̀, wọ́n bèèrè fún oúnjẹ, ẹni tó ń gbọ́ oúnjẹ fún wọn ní ibùdó eré náà sì gbé oúnjẹ wá fún wọn. Inú ọkọ̀ náà ni wọ́n ti jẹ oúnjẹ náà.
Nígbà tí àwọn tó ń ya eré nílò wọn nínú ilé ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pe aago wọn, wọn kò gbé aago ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá wọn kiri.
Wọ́n bá àwọn méjéèjì nínú ọkọ̀ tí wọ́n ti kú, Ayodeji da ẹ̀jẹ̀ nímú àti ẹnu nígbà tí Ekemini po ọṣẹ lẹ́nu. Ohun tó ṣe okùnfà ikú wọn ní pàtó kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Àwọn ọlọ́pàá ti mú ẹni tó gbé oúnjẹ fún wọn gẹ́gẹ́ bíi afurasí, wọ́n sì ti gbé òkú wọn lọ sí ilé ìgbókùúsí fún àyẹ̀wò màjèlé.
Ekemini ni ó tan iná fún eré King of Boys ti Kemi Adetiba ṣe, ó ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ fún àwọn òṣèré àti olórin, ó ti ṣe iṣẹ́ àìmọye iṣẹ́ fún Davido náà nígbà tó wà láyé.

MẸ́RÌNLÁ NÍNÚ ÀWỌN ÈRÒ TÓ LỌ SÍBI ÌGBÉYÀWÓ NI KÒ PADÀ DÉLÉ.
Ọkọ̀ ojú omi tó kó àwọn èrò tó lọ síbi ìgbéyàwó kan ní Kebbi ni kò darí délé nígbà tí ọkọ̀ náà dànù. Obìnrin àti ọmọdé ni àwọn mẹ́rìnlá yìí, wọ́n sin ìyàwó lọ sílé ọkọ rẹ̀ ni ọkọ̀ wọn dànù nígbà tí wọ́n ń darí bọ̀.
Gómìnà Nasir Idris bá àwọn mọ̀lẹ́bí náà kẹ́dùn, ó ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tó bani lọ́kàn jẹ́.

ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ TI PA ỌBA ALÁDÉ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ONDÓ.
Àwọn agbésùnmọ̀mí bíi mẹ́wàá ni wọ́n ya wọ ààfin ọba Agamọ ní Akure láti jíi gbé. Ọba yìí kojú wọn ó sì kọ̀ láti tẹ̀lé wọn. Wọ́n yìn ín níbọn àmọ́ kò wọlé ni wọ́n bá fọ́ nǹkan mọ́ ọn lórí kí wọ́n tó sá lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abayomi Jimoh pé àwọn gba ìfisùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n fẹ́ jí ọba náà gbé ni àmọ́ nígbà tó kọ̀ ni wọ́n ṣe pa á. Nǹkan tó wúwo gan-an ni wọ́n fọ́ mọ́ ọn lórí nígbà tí ìbọn kò ràn-án.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti da àwọn ẹṣọ́ síta wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ nífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn láti wá àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi yìí jáde. Wọn yóò fọ́ gbogbo inú igbó àti agbègbè bákan náà.
Wọ́n ṣe ìlérí pé àwọn yóò hú wọn jáde níbikíbi tí wọ́n bá farasin sí.

OLURANTI LỌ SÍ UK FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́JÁDE ỌMỌ RẸ̀ ÀMỌ́ IKÚ KÁ A MỌ́ Ọ̀HÚN.
Ìyá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oluranti Akinyemi ni ó kú ní kété tí ó dé orílẹ̀-ède UK fún ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde ọmọ rẹ̀, ayẹyẹ náà kò tíì wáyé tí ó fi kú.
Òru ọjọ́ tó dé sílé ọmọ rẹ̀ ni ìpayà mú un láti ojú oorun, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Dunstable àmọ́ ó kú lẹ́yìn ọjọ́ kẹta.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ń bèèrè fún ìrànwọ́ owó láti san owó ilé ìwòsàn náà àti láti gbé òkú rẹ̀ wálé fún sínsin.

MPIGI; AṢÒFIN ÌPÍNLẸ̀ RIVERS TI DÁGBÉRE FÁYÉ.
Barinada Mpigi; aṣòfin tó ń ṣojú ẹ̀kun Gúúsù-Ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Rivers ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Rivers ló túfọ̀ Mpigi pé ó kú lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ́.





