Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi; Francis Nwifuru ti pàṣẹ kí wọn ó rọ gbogbo àwọn baálẹ̀ ìlú Amasiri lóyè lórí ìpànìyàn kan tó wáyé ní ìlú náà níbi tí wọ́n ti bẹ́ orí àwọn èèyàn mẹ́rin tí wọ́n sì tún kó àwọn orí náà lọ. Gómìnà tún pàṣẹ kí kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́; Amari Omaka ó lọ rọ́kún nílé lórí ẹ̀sùn pé ó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn náà.
Níbi àbẹ̀wò tí Gómìnà Francis ṣe sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ló ti pàṣẹ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lórí ìdúró níbẹ̀ náà. Ó ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi èyí tó burú jáì, ó ní irú rẹ̀ kò tún gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀ mọ́, ó sì ṣe ìlérí pé àwọn tí aje ọ̀ràn náà bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ẹnu fẹ́ra bí abẹ̀bẹ̀.

ABUBAKAR ṢEKÚ PA Ẹ̀GBỌ́N RẸ̀ NÍ ADAMAWA.
Abubakar Sadiq; ẹni ogójì ọdún ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn pé ó ṣe kú pa ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Alhaji Sadiq Kawu ní Gombi, Adamawa.
A gbọ́ pé ogúnjọ́, oṣù Ṣẹẹrẹ ni Abubakar pa ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn márùn-ún mìíràn.
Ìbọn gígùn tí wọ́n fi pa á náà ti wà ní ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí, ọta mẹ́rìnlélógụn mìíràn ni wọ́n bá lọ́wọ́ wọn.
Àwọn afurasí náà fi ìbọn pàdé àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n lọ já wọn mọ́ ibùdó wọn, wọ́n jọ fọta ìbọn rọ̀jò, mẹ́ta ló sá lọ nínú wọn nígbà tí ọwọ́ tẹ méjì.
Ìtọpinpin bí wọn yóò ṣe mú àwọn méjì náà ṣì ń lọ báyìí.
ABALA AFÁRÁ TÍ WỌ́N Ń KỌ́ LỌ́WỌ́ YA LULẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀́ OGUN.
Abala afárá kan tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní Oju-ore, Ado-odo Ota ní ìpínlẹ̀ Ogun ti ya lulẹ̀ ó sì wó lu òǹtajà kan.
A gbọ́ pé afárá náà kò tíì parí, iṣẹ́ ṣì ń lọ lórí rẹ̀, ọkọ̀ o tíì máa gùn-ún. Òjijì ni abala kan jábọ́ tó sì ba ọkùnrin kan tó jẹ́ òǹtajà lábẹ́ nítòsí afárá náà, àwọn kan sọ pé ọkùnrin náà kú àmọ́ àwọn akọ̀ròyìn ṣe àbẹ̀wò síi nílé ìwòsàn, a sì ríi pé kò kú àmọ́ ó fi ara pa lọ́pọ̀.
Babatunde Akinbiyi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ẹ̀ka Trace ṣe àlàyé pé ọkùnrin náà há sí abẹ́ kankéré afárá tó jábọ́ náà, àwọn agbọ̀ràndùn àti àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ ni wọ́n yọ ọ́ jáde wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Akinbiyi ṣe àlàyé pé Hausa ni ọkùnrin tó farapa náà ó sì fi ara pa lọ́pọ̀ kódà, ẹsẹ̀ kan ayé ló wà báyìí àti pé kankéré náà mú orí rẹ̀ mọ́ ọn.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ti gba ètò ìtọ́jú rẹ̀ lọ́wọ́ Trace, wọ́n ti lọ mójútó o fúnra wọn nílé ìwòsàn.

OṢÙ KẸTA RÈÉ TÍ WỌ́N TI LO INÁ ỌBA GBẸ̀YÌN NÍ GOWON ESTATE, ÀWỌN OLÙGBÉ YARÍ.
Àwọn olùgbé Gowon Estate yarí mó ilé iṣẹ́ tó ń pín iná ọba ní Èkó Ikedc lọ́wọ́ pé ó tó gẹ́, alubàtá kan kìí tún dárin, iná wọn tó bàjẹ́ láti oṣù mẹ́ta sẹ́yìn ti tó tún ṣe báyìí. Wọ́n tú síta wọ́n sì fi ẹ̀sùn àìbìkítà kan ilé iṣẹ́ Ikedc.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ẹ̀rọ amúnáwá wọn bàjẹ́ láti oṣù mẹ́ta sẹ́yìn wọn kò sì bá wọ́n tún un ṣe. Gbogbo ìwé tí wọ́n kọ sí wọn kò ní àbọ̀ kankan wọn kò tilẹ̀ fèsì sí ọ̀kankan nínú rẹ̀.
Wọ́n ní àwọn kò le ra oúnjẹ sílé nítorí kò sí iná tí wọn yóò tàn sí fírísà, gbogbo owó ni wọ́n ti fi ra epo sí ẹ̀rọ amúnáwá tán.
Bákan náà ni wọ́n ṣe àlàyé pé owó wà lórí káàdì iná wọn àmọ́ wọn kò le lòó wọ́n tún ún fi owó ra epo ni. Ìyà ńlá ni èyí jẹ́ fún wọn.
Àwọn ẹni náà kò ṣeré, wọ́n ní àwọn fún Ikedc di ọsẹ̀ tó ń bọ̀, bí wọn kò bá ṣe iná wọn, àwọn yóò ti ilé iṣẹ́ náà pa ni, kò sí ẹni tí yóò wọlé tàbí jáde ní ọ́fíìsì náà.

AṢÒFIN ÈKÓ PÀṢẸ KÍ WỌN Ó MÁ WÓ ILÉ NÍ MAKOKO ÀTI AGBÈGBÈ MỌ́ BÁYÌÍ NÁ.
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó ti pàṣẹ kí àwọn òṣìṣẹ́ wóléwólé ó dáwó dúró ná ní Makoko àti agbègbè rẹ̀ báyìí náà, wọ́n tún ṣe ìlérí owó gbà-má-bínú fún àwọn tí wọ́n ti wó ilé wọn.
Lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹta, oṣù Èrèlé, wọ́n fi orí korí fi ikùn lukùn wọ́n sì fi ẹnu kò síbi pé kí wọn ó dáwó wíwó àwọn ilé náà dúró ná.
Bákan náà ni wọ́n ṣe ìlérí pé gbogbo àwọn tí wọ́n ti wó ilé wọn ni àwọn yóò fún ní owó gbà-má-bínú.
Àwọn ará Makoko dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba Èkó wọ́n sì ní àwọn ń retí kí wọn ó mú ìlérí náà ṣẹ.

BABA MATTIAS BÈÈRÈ FÚN ÌDÁJỌ́ ÒDODO LÓRÍ IKÚ ỌMỌ RẸ̀.
Bàbá Mattias ti jáde síta láti bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lọ́rí ikú tó pa ọmọ rẹ̀ sí ilé ìtura Signatious tó wà ní Ajah, ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé tí bàbá Mattias ṣe náà ni pé Mattias lọ sí ilé ìtura náà fún àríyá etí odò ni wọ́n bá ní ó kó sínú odò ìwẹ̀ ilé ìtura náà kí àwọn wá pàdé rẹ̀ nílé ìwòsàn.
Ẹ̀yìn ọkọ̀ tí wọ́n fi gbé e ló sí ilé ìwòsàn ìjọba Isolo náà ni àwọn ẹbí rẹ̀ bá a, wọ̀n kò gbé wọ inú ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú rárá, bàbá Mattias ní òun kò gbà pé ọmọ náà kú sínú odò ìwẹ̀ ni nítorí àwọn àpá tó wà lára òkú rẹ̀ tí kò sì ní nígbà tó wà láyé.
Yàtọ̀ sí àpá ara rẹ̀, bàbá Mattias ní ẹnìkan pe ọmọ náà ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà gan-an lórí aago pé kí ni kí àwọn fi yanjú ọ̀rọ̀ náà?
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtura náà ṣe àlàyé fún bàbá Mattias pé Mattias àti obìnrin kan ni wọ́n jókòó sí etí odò ìwẹ̀ náà níbi àríyá náà, ṣàdédé ni àwọn kò rí Mattias mọ́, wọ́n bèèrè rẹ̀ ọmọbìnrin náà sì dáhùn pé ó ti lọ, wọ́n ní àwọn fèsì pé kò le tíì ló nítorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó wà lórí àga tó fi jókòó náà ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí ní wá a, wọ́n wá a títí wọ́n sì ríi nínú odò ìwẹ̀ ilé ìtura náà. Bàbá Mattias ní òun kò gba àlàyé yìí wọlé pé ejò lọ́wọ́ nínú ikú ọmọ rẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá dé ilé ìtura náà, wọ́n ṣe àkíyèsí pé ibẹ̀ ní àwọn kọ́lọ́fín tó yàtọ̀ sí gbàgede tí àwọn èèyàn ti ń gbafẹ́, àwọn kọ́lọ́fín yìí kún fún àwọn nǹkan tó jọ eegun àti àwọn nǹkan mìíràn tí kò yéni tààrà, àwọn òṣìṣẹ́ ní alámòójútó ilé ìtura náà ló le ṣe àlàyé, wọ́n ní àwọn kò mọ nǹkankan nípa àwọn yàrá kọ́lọ́fín náà.
Wọ́n gbé alámòójútó ilé ìtura yìí wọ́n sì ní kó mú fọ́nrán ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìtura náà jáde. Obìnrin tó jẹ́ alámòójútó yìí ní oun ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ náà ni pé òun kò mọ̀ nípa ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀.
Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìtura Signatious tó wà ní Ajah ló ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ikú tó pa Mattias sílé ìtura náà.

GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ EBONYI KÉDE KÓNÍLÉ-Ó-GBÉLÉ ỌLỌ́JỌ́ MÉJÌ LẸ́YÌN ÌKỌLÙ TÓ BURÚ JÁÌ.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ebonyi; Francis Nwifuru ti kéde kónílé-ó-gbélé oníwákàtí méjìdínláàdọ́ta ní gbogbo agbègbè Amasiri, ó sì tún pàṣẹ kí gbogbo iléèwé ó wà ní títì pa lásìkò yìí.
Ìdí èyí ni ìkọlù burúkú kan tó wáyé ní Amasiri níbi tí wọ́n ti bẹ́ orí àwọn èèyàn mẹ́rin tí wọ́n sì tún kó àwọn orí náà lọ. Fúnra Gómìnà ló ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó pàṣẹ kí wọn ó rọ gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè náà lóyè kí wọ́n sì tún dá kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ dúró nítorí ọ̀rọ̀ náà tọ́ka síi.
Ọjọ́ náà gan-an ni Gómìnà ti ṣe ìlérí pé òun yóò fi àwọn ọ̀daràn tó pitú náà jófin.
Ní báyìí, Gómìnà Nwifuru ti kéde kónílé-ó-gbélé ọlọ́jọ́ méjì ó sì ti kó àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò dà síbẹ̀ bìbà láti pètù sí agbègbè náà àti láti dẹ́kun irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí lọ́jọ́ iwájú.





