Gómìnà ìpínlẹ̀ ògùn; Ọmọọba Dapo Abiodun ti já ewé jókòójẹ́ olóṣù mẹ́fà fún ọba AbdulSemiu Ogunjobi Olorile ti Orílé Ifọ̀ lórí fọ́nrán ìfìyàjẹni tó gbòde.
Nínú fọ́nrán kan tó lu síta lórí ìkànnì ayélujára ni ọba AbdulSemiu Ogunjobi ti dá baálẹ̀ Areola Abraham kúnlẹ̀ tó sì ń nù ún ní ọ̀rọ̀ bí òkèlè ẹ̀bà.
Bó bá ṣe pé ó nù ún lọ́rọ̀ nìkan ni kò bá sunwọn, ọba AbdulSemiu Ogunjobi ki ìpọ̀nrí baba ńlá rẹ̀ fún un, ó fi wé játijàti réderède, èébú kò tó èpè, àwọn èpè àgbọ́fọwọ́detí àtirandíran ni ó gbé baálẹ̀ Areola ṣẹ́.
Ìgbà tí yóò fọ́ gbogbo rẹ̀ lójú pọ̀, ló bá ní òun yóò rán Areola ní ẹ̀wọ̀n pé òun lòun ń pàṣẹ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíría.
Àwọn èèyàn wí pé bóyá nítorí pé ọba AbdulSemiu jẹ́ ọlọ́pàá-fẹ̀yìntì ló fún un ní irú ìgboyà bẹ́ẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ́ kìí déédé ṣẹ́, ẹ̀sùn tí Olórílé Ifọ̀ fi kan Areola ni pé ó lẹ́dǐ àpò pọ̀ dìtẹ̀ mọ́ òun.
Nínú fọ́nrán náà, baálẹ̀ Areola wà lórí ìkúnlẹ̀, ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé òun kò dìtẹ̀ mọ́ ọba AbdulSemiu. Ẹnìkan gbá bàbá ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin yìí létí ó sì pàṣẹ fún un pé kó dọ̀bálẹ̀.
Ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ náà ni baálẹ̀ Areola dọ̀bálẹ̀ gbalaja tó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí olúwa rẹ̀.
Kò sí ẹni tí a ó gbé gun orí ẹṣin tí kò ní sọ ìpàkọ́ àmọ́ ṣé èyí kò wa pọ̀jù?
Gómìnà Dapo Abiodun pàṣẹ kí Olórílé ti orílé Ifọ̀ náà; ọba AbdulSemiu Ogunjobi ó lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà gbáko bẹ̀rẹ̀ láti òní, ṣé ọjọ́ tí a bá ríbi náà níí wọlẹ̀.
Kò tán síbẹ̀ o, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pe ọba AbdulSemiu fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní ó lòdì sí òfin àti pé ẹ̀ṣẹ̀ ni kí èèyàn kan ó sọ pé òun nì agbára láti ṣe ohun tó bá wu òun nílǔ tó lófin.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíría; Olumuyiwa Adejobi bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ọba yìí, ó kọ ọ́ sí ojú òpó X rẹ̀ pé ìwà yìí lòdì sí òfin pátápátá, kò sí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìyà jẹ ẹnikẹ́ni bẹ́ẹ̀ sì ni kò lẹ́tọ̀ọ́ kí èèyàn kan ó wí pé òun ló ń darí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíría, ohun tí òun bá fẹ́ ni wọn yóò ṣe.
Ọba AbdulSemiu yọjú sí àgọ́ ọlọ́pàá kódà ó fojú ba ilé-ẹjọ́ lónìí fún ẹ̀sùn ìṣenimọ́kumọ̀ku àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn bẹ́ẹ̀.
Ẹjọ́ náà kò forítì síbìkan, yóò sì tẹ̀síwájú.
Oríṣìí ìhà ni àwọn èèyàn kọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àwọn kan bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí Ọba AbdulSemiu hù yìí pé ìfìyàjẹni àti ìjẹgàba ni nígbà tí àwọn kan gbè lẹ́yìn rẹ̀ pé baálẹ̀ Areola ló dánú bíi.
Irú èèyàn wo ni ọba AbdulSemiu Ogunjobi?
Àwọn èèyàn ṣe àpèjúwe ọba AbdulSemiu Ogunjobi gẹ́gẹ́ bíi èèyàn dáadáa, ẹni iyì àti ẹ̀yẹ tó sì nífẹ̀ẹ́ afẹ́ púpọ̀.
Wọ́n ní ó lẹ́yinjú àánú ó sì ní ìwà tútù bí àdàbà.
Báwo wá ni ká ṣe ṣe àlàyé ìwà tí oníwààdabà yìí hù báyìí?