Gómìnà Caleb Mutfwang Kéde Kónílé-ó-Gbélé Ní Ipínlẹ̀ Plateau. Látàrí bí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ṣe di èyí tí wọ́n ń ya wọ àwọn ilé ìjọba kó ẹrù àti oúnjẹ tí ó sì ti ń mú ọwọ́ rògbòdìyàn dání, Gómínà Plateau, Ọ̀gbẹ́ni Caleb Mutfwang ti kéde kónílé-ó-gbélé oníwákàtí mẹ́rinlélógún ní Jos àti agbègbè rẹ̀.
Àtẹ̀jáde yìí ló jáde láṣàálẹ́ àná láti ilé iṣẹ́ Gómínà Caleb tí Gyang bere; ẹni tó jẹ́ adárí iròyìn àti àtẹ̀jáde ilé iṣẹ́ Gomínà náà ṣe agbátẹrù rẹ̀.
https://iweiroyinyoruba.com/a-ko-reni-ra-ohun-ti-a-n-ta-awon-oni%e1%b9%a3owo-kastina-figbe-ta/
Nínú àtèjáde náà tí Gyang bu ọwọ́ lù ni a ti kàá pé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ àbò lórí bí àwọn kan ṣe kó àdá, àáké àti àwọn ohùn ìjà olóró mìíràn lọ fọ́ àwọn ilé ìjọba àti ilé ìtajà káàkiri ní agbègbè Bauchi àti oríta Zololo tí wọ́n sì kó àwọn ohun olówó iyebíye lọ ní èyí tó ti da omi àlàáfíà agbègbè náà rú.
Lẹ́yìn àpérò náà ni Gómínà àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ fẹnukò sí pé kí onílé-ó-gbélé fún wákàtí mẹ́rìnlélógún bẹ̀rẹ̀ lónìí ọjọ́ karùn-ún oṣù Ògún kí àlàáfíà ó le jọba.