Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia tẹ́lẹ̀rí, ẹni tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà báyìí; Orji Kalu ti gba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu nímọ̀ràn pé kí ó yọ àwọn mínísítà tí wọn kò mọ iṣẹ́ wọn níṣẹ́ nípò.
Gbogbo àwọn mínísítà tí wọ́n joyè àwòdì tí wọn kò le gbé adìyẹ ni ó ní kí ààrẹ ó fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún.
Orji Kalu wí pé àwọn mínísítà yìí ni ìrẹ̀ nínú ìṣejọba Tinubu tí wọ́n ń wa orílẹ̀-èdè yìí lọ sẹ́yìn, wọn kò ní àǹfààní kankan tí wọ́n ń ṣe fún Nàìjíríà ju pé kí wọn ó fàá sẹ́yìn lọ.
Ọ̀rọ̀ Kalu tẹ̀síwájú pé àṣẹ lọba ń pa, àsìkò ti tó fún Tinubu láti kojú àwọn mínísítà yìí kó sì gbọ̀n wọ́n yọ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo iṣẹ́ tí Tinubu ń ṣe ni wọn yóò máa dojú rẹ̀ délẹ̀.
Láti orí àwọn tí wọ́n wà ní ẹ̀ka ètò ààbò ni Kalu ní kí Tinubu ó ti bẹ̀rẹ̀, ó ní bí ó bá ṣe èyì, Nàìjíríà yóò bọ́ sípò.
Ọdún iléyá.
Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀ wa ti kéde ọjọ́ Ẹtì àti ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ lọ́nà yìí ní ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún ọdún iléyá.
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́; Olubunmi Tunji-Ojo ló kéde èyí lówùúrọ̀ òní. O rọ àwọn Mùsùlùmí láti wà ní ìṣọ̀kan lásìkò ọdún iléyá yìí.
Olubunmi gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí a má gbàgbé láti gba àdúrà fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, kí Allahu ó ṣe ìrànwọ́ fún un lórí ìṣèjọba rẹ̀.
Lórí ọdún iléyá yìí náà ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto ti pàṣẹ pé —
Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu ti pàṣẹ kí wọn ó san owó oṣù Igbe fún àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà. Ó wí pé òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó rówó fi ṣe ọdún Iléyá tó ń bọ̀ yìí.
Láti ìlú Mẹ́kà ni Gómìnà ti pàṣẹ náà nítorí pé ó wà ní hájì báyìí. Akọ̀wé rẹ̀; Malam Abubakar Bawa ló fi ọ̀rọ̀ náà léde lówùúrọ̀ àná pé àwọn yóò san owó oṣù tó ń bọ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì oṣù Igbe.
Èyí ni ìgbà kẹ́ta tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto yóò san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ṣáájú kí oṣù ó tó parí nítorí ọdún.
Gómìnà Ahmed Aliyu wí pé ìrọ̀rùn àwọn ará ìlú òun ló jẹ òun lógún, òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó ṣe ọdún ayọ̀ kí wọn ó rówó ṣe ọdún náà.
Lórí ọdún iléyá yìí náà ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto ti pàṣẹ pé —
Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu ti pàṣẹ kí wọn ó san owó oṣù Igbe fún àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ náà. Ó wí pé òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó rówó fi ṣe ọdún Iléyá tó ń bọ̀ yìí.
Láti ìlú Mẹ́kà ni Gómìnà ti pàṣẹ náà nítorí pé ó wà ní hájì báyìí. Akọ̀wé rẹ̀; Malam Abubakar Bawa ló fi ọ̀rọ̀ náà léde lówùúrọ̀ àná pé àwọn yóò san owó oṣù tó ń bọ̀ ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì oṣù Igbe.
Èyí ni ìgbà kẹ́ta tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto yóò san owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ ṣáájú kí oṣù ó tó parí nítorí ọdún.
Gómìnà Ahmed Aliyu wí pé ìrọ̀rùn àwọn ará ìlú òun ló jẹ òun lógún, òun fẹ́ kí gbogbo wọn ó ṣe ọdún ayọ̀ kí wọn ó rówó ṣe ọdún náà.
Páńpẹ́ ikú ni afárá náà jẹ́ láti ọjọ́ tó ti pẹ́.
Ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ nílẹ̀ yìí; FRSC ti wí pé àwọn yóò ṣe ọ̀fintótó ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ìjàm̀bá ọkọ̀ tó mú ẹ̀mí àwọn agbábọ́ọ̀lù Kano méjìlélógún lọ.
Ahmad Umar; ọ̀gá àjọ FRSC tó wà ní ẹ̀kun Kastina, Jigawa àti Kaduna ló sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Kano. Umar ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi èyí tó bani lọ́kàn jẹ́.
Ahmad Umar wí pé ọ̀gangan ibi tí ìjàm̀bá náà ti wáyé jẹ́ ibi tó léwu púpọ̀ lórí afárá náà tí wọ́n ti ń pariwo rẹ̀ fún ìjọba tipẹ́. Ó wí pé àwọn yóò kàn sí ẹ̀ka tọ́rọ̀ kàn láti ṣe àtúnṣe sí afárá náà láti dènà irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí lọ́jọ́ iwájú.
Bí ó ṣe ṣẹlẹ
Àwọn agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ wa tí wọ́n ti ìpínlẹ̀ Kano wá kópa nínú eré ìdárayá tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀.
Ìròyìn fi yé wa pé ọgbọ̀n ni àwọn agbábọ́ọ̀lù náà tí wọ́n wá láti Kano, nígbà tí wọ́n ń padà lọ sí Kano ni ọkọ̀ wọn dànù tí ogún sì kú nínú wọn.
Orí afárá Dakatsalle tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Kura ní ìpínlẹ̀ Kano ni ìjàm̀bá náà ti wáyé. Ọkọ̀ wọn náà jábọ́ láti orí afárá náà sílẹ̀ tí ogún sì kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nínú wọn.
Wọ́n ti gbé àwọn mẹ́wàá tó yè náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Kura fún ìtọ́jú.
Ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé ní ìpínlẹ̀ Niger ti bá ọ̀nà mìíràn yọ báyìí, ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún òkú èèyàn tí wọ́n ti rí yọ báyìí.
Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń rí òkú èèyàn tó ń lé téńté lórí omi.
Igbákejì Gómìna ìpínlẹ̀ Niger; Yakubu Garba ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Mokwa tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti rinlẹ̀. Àwọn agbègbè tó tún kàn bẹ́ẹ̀ ni Tiffin Maza àti Anguwan Hausawa.
Garba wí pé Gómìnà ìpínlẹ̀ náà ló rán òun wá wo bí nǹkan ṣe rí ní àwọn agbègbè náà, ó wí pé òkú èèyàn tí wọ́n ti rí yọ báyìí ti lé ní ọgọ́rùn-ún.
Àwọn adóòlà ẹ̀mí ṣì ń wá àwọn èèyàn yòókù tí àwọn ẹbí wọn fi sùn pé wọn kò rí mọ́.
Ọ̀rọ̀ Garba tẹ̀síwájú pé kí àwọn èèyàn náà ó ṣe sùúrù fún ìjọba, ó wí pé ìjọba ti ń ṣe ètò àwọn ohun amáyédẹrùn fún àwọn èèyàn náà lásìkò yìí ná. Àwọn èyí tó ti wà nílẹ̀ báyìí yóò jẹ́ pínpín fún àwọn tọ́rọ̀ kàn.
Ó wí pé òun yóò jábọ̀ ipò tí ìlu náà wá fún Gómìnà tó rán òun wá. Bákan náà ló rọ àwọn aráàlú láti yé kọ́ ilé sí ojúdò àti etí odò ní èyí tó le fa irú ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé báyìí.
Ìròyin fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ìdílé mẹ́tàlélógún ló ti parun nínú ìṣẹ̀lẹ̀ omiyalé yìí.
Discussion about this post