Victor Fajemirokun; ọ̀rẹ́kùnrin òṣìṣẹ́ ààbò ojú pópó ti ìjọba àpapọ̀ FRSC tí wọ́n pa náà ti ṣe àlàyé bí iṣu ṣe kú àti bi ọ̀bẹ ṣe bẹ ẹ́.
Ẹni ogójì ọdún ni Fajemirokun, ó jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin Lasisi Funmilayo; ìyá Sewa tí òun àti àwọn adáhunṣe méjì jọ pa àti ọmọ rẹ̀ sínú igbó kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.
Àlàyé tí Victor ṣe náà ni pé nígbà tí òun jáde sí ọ̀rọ̀ òun ni wọ́n sọ fún òun pé òun kò le lu àlùyọ mọ́ láyé àfi tí Funmilayo bá kú nítorí pé ó ti lo ògo òun. Ìdí rèé tí òun fi tàn án láti ìpínlẹ̀ Ogun lọ sí ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun níbi tí wọ́n ti dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.
Orí ìkànnì Tiktok ni Victor ti pàdé Gboyega Daramola tó ṣe àyèwò fún un, nígbà tí ọ̀rọ̀ wọ̀ tán ni ó tan Funmilayo lọ sí ilé Gboyega láti tú ara rẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbèkùn tí Funmilayo dè é mọ́, Gboyega ló pe àwọn méjì mìíràn mọ́ra tí wọ́n jọ pa Funmilayo àti Sewa; ọmọ rẹ̀ obìnrin.
Lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n tán, Victor ní òun sá lọ sí òkè Ikoyi ó sì gba ibẹ̀ lọ sí Ìbàdàn. Ó ní òun kò mọ̀ pé wọ́n yọ ẹ̀yà ara wọn rárá.
James; ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ ṣe iṣẹ́ náà ṣe àlàyé pé ọ̀gá òun; Gboyega ló pàṣẹ kí òun ó pa Funmilayo nítorí pé òun ló de ògo Victor mọ́lẹ̀.
Ọ̀bẹ ni wọ́n fi dú Funmilayo lọ́rùn kí wọ́n tó wá gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ – James.
Gboyega Daramola náà sọ̀rọ̀, ó ní òun kọ́ ló sọ fún Victor pé Funmilayo ti de ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀, Victor ti lọ sí ọ̀dọ Àlùfáà kan tẹ́lẹ̀ tó sọ fún un pé Funmilayo ti gba ògo rẹ̀, òun kàn fẹ́ bá a gba ògo náà padà lásán ni àti pé Victor gan-an ló ní kí àwọn ó pa Funmilayo, ojú rẹ̀ làwọn sì ṣe kun ún wẹ́le.wẹ̀lẹ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Gotan ṣe àlàyé pé Fajemirokun di àwàtì láti ọjọ́ kejì, oṣù Bélú tó ti ṣiṣẹ́ ibi náà títí di ìgbà tí wọ́n ri i ní ọjọ́ kẹrìndínlógún.
Láàŕrín ìgbà náà ni wọ́n mú Gboyega tí ìnagiẹ rẹ̀ ń jẹ́ Aberefa, Gboyega jẹ́wọ́ pé Fajemirokun ló mú Funmilayo wá sí ilé òun pé kí àwọn ó pa á fún oṣólẹ̀ owó.
Àwọn tí wọ́n jọ pa á náà ni Sunday James, Kehinde àti Idowu.
Ọjọ́ kẹtàdínlógún ni Aberefa mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tó pa Funmilayo sí ní nú igbó, kò sí orí, ọyàn méjéèjì, ọrùn ọwọ́ méjéèjì àti ojú ara lára òkú náà mọ́, gbogbo rẹ̀ ni wọ́n ti yọ.
Èkìtì ni wọ́n ti lọ gbé Sunday James, ó ní òun kàn dú Funmilayo àti ọmọ rẹ̀; Sewa lọ́rùn ni, òun kò bá wọn kun ún wẹ́lẹwẹ̀lẹ.
Kehinde àti Idowu ni ó kun iyá àti ọmọ bí ẹran tí wọ́n yọ àwọn ẹ̀yà ara náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ṣe ìlérí pé gbogbo àwọn afurasí yìí ni yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí.
Láti ìbẹ̀rẹ̀:
Òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú pópó ìjọba àpapọ̀ FRSC ni Funmilayo Olumayokun Lasisi, Ẹni ọdún mọ́kàndínlógójì níí ṣe.
Ọjọ́ kejì, oṣù Belu ni Funmilayo àti ọmọ rẹ̀ jáde kúrò nílè tí wọn kò sì padà sílé mọ́.
Obasanjo Hiltop Estate ní Oke- Mosan, Abeokuta ni ilé Funmilayo wà, lọ́jọ́ náà, Funmilayo jáde nílé pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ obìnrin, àti ìgbà náà ni wọ́n ti ń wá a tòun tọmọ tó mú jáde náà.
Ilé adáhunṣe kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ tí wọ́n sì tún rí òkú ọmọ rẹ̀ ní inú igbó kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun kan náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣe akitiyan láti wá Funmilayo lẹ́yìn tí àwọn ẹbí rẹ̀ fi lọ̀ wọ́n pé wọn kò ríi bẹ́ẹ̀ sì ni aago rẹ̀ kò lọ.
Ayomideji Solanke ló kọ́kọ́ kọ ọ́ sí ojú òpó Facebook rẹ̀ pé wọ́n ti rí òkú Funmilayo ní ilé adáhunṣe kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Bákan náà ni mọ̀lẹ́bí ọkọ Funmilayo fìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé wọ́n rí òkú rẹ̀ lóòótọ́.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogunlowo náà ṣe àlàyé pé àwọn ṣe àwárí òkú Funmilayo àti ọmọ rẹ̀ Sewa ní ìpínlẹ̀ Osun. Wọ́n ti mú ìyàwó adáhunṣe náà àmọ́ òun gan-an ti na pápá bora nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn afurasí díẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni yóò ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí nígbà tí ti ìpínlẹ̀ Ogun yóò máa kún wọn lọ́wọ́.
Bí wọ́n ṣe pa ìyá àti ọmọ yìí náà ni Chiemere pa noosi toyún nínú:
Arábìnrin kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó sì tún lóyún sínú ni àwọn méjì kan ti sẹkú pa báyìí tí wọ́n sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Chiemere Elobisi; ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló tan nọ́ọ̀sì náà wá sí ilé rẹ̀ pé kí ó wá tọ́jú òun, nígbà tí nọ́ọ̀sì yìí dé ilé rẹ̀, Chiemere pa á ó sì kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú àwọn ọ̀rá dúdú.
Lẹ́yìn náà ni ó ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn oníṣègùn káàkiri. Ìyókù rẹ̀ tó dà sí inú kòtò ìdaminù ni ó mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya tí wọ́n sì tọpinpin dé ilé rẹ̀.
Chiemere ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ àmọ́ ọwọ́ tẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ; Somtochukwu Nwafor.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Somtochukwu, ó ṣe àlàyé pé òun kò lọ́wọ́ sí pípa àti kíkun nọ́ọ̀sì náà, òun kàn nu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tí Chiemere pa á tán ni.
Somtochukwu ló mú àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ àwọn oníṣègùn tí Chiemere ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún ọwọ́ sì ti tẹ ọ̀kan nínú wọn.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní agbègbè Ogbunike ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyi.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti mú Somtochukwu tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin Chiemere nígbà tí Chiemere gan-an ti sá lọ.
Somtochukwu júwe àwọn oníṣègùn tí Chiemere máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún. Èyí ni wọ́n fi mú Nwafor Chibunna tí wọ́n sì bá ẹ̀yà ara nọ́ọ̀sì yìí àti àwọn mìíràn lákàtà rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń wá àwọn oníbàárà ẹ̀yà ara yòókù àti Chiemere.




