Arábìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Promise Eze ni àwọn ọlọ́pàá gbà kalẹ̀ lọ́wọ́ agbénipa tó tàn án lọ sí ilé ìtura.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Promise Eze, orí ìtàkùn ayélujára ni promise ti pàdé Michael, ọ̀rọ̀ ìfẹ́ wọn wọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi lọ pàdé rẹ̀ nílé ìtura kan tó wà ní Abuja.
Ọgbọ̀njọ́, oṣù Ṣẹẹrẹ tó kọjá yìí ni Promise lọ bá Michael nílé ìtura náà ní nǹkan bíi aago méje àárọ̀.
Nigba tí Promise wọ yàrá tọ Michael, ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ, àṣẹ Emmanuel Okoro ni orúkọ ọmọkùnrin tó pe ara rẹ̀ ní Michael fún un, agbenipa ni Emmanuel.
Ó fi ààké halẹ̀ mọ́ Promise, ó dè é mọ́ orí àga pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn ó sì fi aṣọ dí i lẹ́nu. Ojú rẹ̀ náà ni ó ṣe ń pe àwọn yòókù rẹ̀ lórí aago pé ó ti wà nílẹ̀.
Orí Promise tó máa kó o yọ ló ní kí Emmanuel ó jáde lọ pàdé èèyàn kan ní ìta, àsìkò yìí ni òṣìṣẹ́ ilé ìtura kan lọ kan ilẹ̀kùn wò láti tún yàrá náà ṣe.
Nígbà tí kò gbọ́ ohùn kankan ló bá ṣí ilẹ̀kùn wò, orí àga ló bá Promise pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀mí rẹ̀ sì ti fẹ́rẹ̀ bọ́.
Ilé ìtura yìí ló ránṣẹ́ pe àwọn ọlọ́pàá, wọ́n sì tara ṣàṣà dé ibẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá tú ọmọbìnrin yìí sílẹ̀ wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Wuse níbi tó ti lajú sáyé.
Emmanuel ti kẹ́fín àwọn ọlọ́pàá nígbà tó ń padà bọ̀ wá parí iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ ó sì sá lọ tèfètèfè.
Ìgbà tí ara Promise yá ló ṣe àlàyé pé Michael Prince ni Emmanuel pe orúkọ rẹ̀ fún òun lórí ìtàkùn ayélujára, ó ní òun ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ epo tó wà ní Delta.
Promise ṣe àlàyé pé Delta ni Emmanuel ní kí òun ó wá àmọ́ òun yarí pé òun kò le wá àjòjì lọ sí ìlú mìíran ni ó ṣe gbà kí àwọn ó pàdé ní Abuja.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja; Josephine Adeh ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé orí kó Promise yọ lọ́wọ́ atannipa tó ń ṣe bíi olólùfẹ́. Pípa ni Emmanuel fẹ́ pa Promise, ààké àti àwọn nǹkan mìíràn ni wọ́n bá nínú àpò rẹ̀ nílé ìtura náà, ojú Promise náà lo ti ń sọ fún àwọn ìyókù rẹ̀ pé ọjà ti wà nílẹ̀ kó tó di pé ó lọ gba nǹkan ní agbègbè náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Abuja; Olatunji Disu bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti yẹra fún àwọn olólùfẹ́ òjijì orí ayélujára.
Wàyí o, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìwádìí ń lọ lórí bí àwọn yóò ti mú Emmanuel náà.
Ọ̀rọ̀ àwọn atannipa yìí ń fẹ́ àpérò báyìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ni ìròyìn rẹ̀ ti kàn sẹ́yìn kò si jọ ohun tí yóò dópin láìpẹ́.
Ìṣẹ̀lẹ̀ tó fara pẹ́ èyí ni ti ọmọbìnrin akẹ́kọ̀ọ́ FUNAAB kan tí arákùnrin kan pa ní Ikorodu.
Christiana Idowu; ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ẹ̀kó ọ̀gbìn FUNAAB tó sì tún jẹ́ pé ilé ìjọsìn kan náà ni òun àti Ayomide ń lọ ni ó ṣe àgbákò ikú àìtọ́jọ́ lọ́wọ́ Ayomide.
Àṣé òótọ́ ni pé imú níkà ni kò fi jẹ́ ká gbóòórùn aṣebi. Fúnra Christiana ni ó lọ sí ilé Ayomide pé kí ó bá òun tún ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun ṣe láìmọ̀ pé ikú lòun ń lọ bá. Ṣádédé ni Ayomide fún un lọ́rùn pa ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, ìdajì ọjọ́ kejì ni ó sin òkú rẹ̀ sí ẹ̀yìnkùlé ilé rẹ̀.
Lẹ́yìn náà ló pe ìyá Christiana pé òun ti jí ọmọ rẹ̀ gbé kí ó san ẹ̀gbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mẹ́ta náírà owó ìtúsílẹ̀. Ọ̀dúnrún ẹgbẹ̀rún ni ìyá Christiana ṣà jọ tó fi ránṣẹ́ sínú àpò ìlówósí SPORTY BET, lẹ́yìn náà ni ó tún gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàà mìíràn.
Nọ́mbà ìdánimọ̀ orílẹ̀-èdè yìí tí Ayomide so mọ́ àpò ìkówósí náà kí ó tó le gbàá ni àwọn ọlọ́pàá fi tọpinpin rẹ̀ tí wọ́n sì mú un.
Ayomide wí pé òun kábàámọ̀ pé òun pa Christiana pé kí àwọn ọmọ Nàìjíría ó dárí ji òun.
Òmíràn tó tún dàbí rẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ Mutiu Akinbami; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ kánsílọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun tí àwọn kan yìnbọn pa nínú osù Bélú ọdún tó kọjá.
Olomoore ni Mutiu Akinbami ń gbé, òun àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ló wà lórí ọ̀kadà tí wọ́n ń padà lọ sí ilé. Ìgbà tí wọ́n dé Brewery tó kù díẹ̀ kí wọ́n dé ilé ni àwọn kan yín gíláàsì ọkọ̀ wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì yin ìbọn fún un ní orí.
Ọkọ̀ Hilux funfun ni ọkọ̀ náà, ó jọ pé wọ́n ń tẹ̀lé bọ̀ tẹ́lẹ̀, ìgbà tí wọ́n sún mọ́ ọn dáadáa ni wọ́n yín gíláàsì sílẹ̀ tí wọ́n sì yin ìbọn fún un lórí.
Mutiu kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn èèyàn gbìyànjú ipá wọn, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Ìjàyè àmọ́ ó ti bọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Omolola Odutola pé àwọn gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn sì ti mú àwọn kan sí àtìmọ́lé tí wọ́n jẹ́ afurasí.
Àlàyé síwájú síi ni pé Mutiu fúnra rẹ̀ kìí ṣe ẹran rírọ̀, wọ́n ní àwọn ti ń wá a fún ẹ̀sùn ìpànìyàn lásìkò tó fi jẹ́ olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn ní ilé ìwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ olùkọ́ ní Osiele, Abeokuta.
Wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni Mutiu pé ikú rẹ̀ ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ òkùnkùn.
Títí di àsìkò yìí, kò tíì sí ìjábọ̀ kan tààrà láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.