Ewu Iná Kìí P’awòdì, Àwòdì O Kú Ewu. Àwọn ebi, ará àti olólùfẹ́ arákùnrinbìnrin Idris Okuneye tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Bob Risky lọ pàdé rẹ̀ lónìí tó gba ominira lẹ́yìn àtìmọ́lé oṣù mẹ́fà.

Itokasi – Punch
Nínú fọ́nrán tó jáde ni a ti rí ọkùnrinbìnrin nnì Bob Risky tó da ara rẹ̀ pè sí MUMMY OF LAGOS jókòó sínú ọkọ̀ bọ̀gìnì pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó sì ń kí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kú àdúrótì àti àtìlẹ́yìn wọn.
https://iweiroyinyoruba.com/gomina-caleb-mutfwang-kede-konile-o-gbele-ni-ipinle-plateau/
https://www.vanguardngr.com/2024/04/why-court-sentenced-bobrisky-to-six-months-in-prison/
Bob Risky sọ nínú ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ rẹ̀ pé òun ti lọ òun sì ti bọ̀, òun ti kọ́ ẹ̀kọ́, òun ò tún ṣe irú àsìṣe bẹ́ẹ̀ mọ́. Ó sì rọ àwọn èèyàn láti pa òfin ilẹ̀ yìí mọ́.