Ọmọ́yẹlé Ṣòwòrẹ́ , ẹni tó ti fi ìgbà kan dupò Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yìí rí nígbà kan ti tako bí àwọn ìpínlẹ́ kan lókè ọya lọ́hùn ún ti ní kí gbogbo ọmọ ilé ìwé, bẹ̀rẹ̀ láti ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga Ifáfitì dúró sílẹ́ báyìí látàrí oṣù àwẹ̀ Ramadan tó n lọ lọ́wọ́-lọ́wọ́ títí pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ọdún àwẹ̀ yóò fi kásẹ̀ nílẹ̀, ìjọba ní ọjọ́ karùn ún oṣù kẹrin ni ìgbẹ̀kọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní pẹrẹu. Láti ọjọ́ kejìdínlógún ni ìjọba ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan lókè ọya ti kéde ìkìlọ̀ yìí àti pé ìjìyà n bẹ́ fún ilé ìwé aládani tó bá tàpá sófin ìjọba lásìkò yìí. Ọ̀kan lára òpó ẹ̀sìn ìsìláàmù ni Àwẹ̀ gbígbà, ọ̀rànọyàn sì ni ÁLÀ ṣé é fún gbogbo àwọn Mùsùlùmí òdodo káàkiri orílẹ̀ èdè Àgbánlá ayé. Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ BAUCHIJALALUDEEN MAINA, lókè ọya ni kí gbogbo ọmọ ilé ìwé gbélé wọn, kò sí ilé ìwé lílọ mọ́ láti ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù yìí títí di Ọjọ́ karùn ún oṣù kẹrin ọdún nítorí kí gbogbo olùkọ́ àti Akẹ́kọ̀ọ́ le è fi tọkàn tọkàn àti tara-tara gba àwẹ̀.
Mìnísítà fún ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ BAUCHI, JALALUDEEN MAINA sọ pé èyí ti wà nínú àlàkalẹ̀ bí ètò ẹ̀kọ́ sáà kejì yìí yóò ti ṣe lọ láti ọjọ́ karùn ún oṣù kínní ọdún yìí. Gbogbo ilé ìwé ìjọba àti Aládani bẹ̀rẹ̀ láti kíláàsì alákọ́bẹ̀rẹ̀ dé sẹ́kọ́ndírì títí dé ilé ẹ̀kọ́ gíga tàwọn olùkọ́ni, ilé ẹ̀kọ́ gbogbonṣe àti Ifáfitì. Apá kejì ètò ẹ̀kọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu lẹ́yìn ọdún ìtunu àwẹ ọdún 2025.
Mínísítà JALALUDEEN MAINA wí pé : ‘Ní ìbẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ sáà kejì tí a bẹ̀rẹ̀ ní 5/1/2025 ni àwọn ti ṣe àlàkalẹ̀ náà sínú ètò ẹ̀kọ́ pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ dáwọ́ dúró tàbí kí abala àkọ́kọ́ wá sí òpin ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Èrèlé 2025 látàrí oṣù àwẹ̀ tó gbòde báyìí. Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní ọjọ́ kẹfà oṣù kẹrin ọdún 2025 lẹ́yìn tí ọdún ìtunnu àwẹ̀ bá tí kásẹ̀ nílẹ̀ tán pátápátá.
Lánàá òde yìí náà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina náà ṣe bí ìjọba BAUCHI ti ṣe lórí ìgbélé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ nínú oṣù àwẹ̀, ìjọba ní gbogbo ilé ẹ̀kọ́, bẹ̀rẹ̀ láti ilé ìwé Alákọ́bẹ̀rẹ̀, Ṣẹ́kọ́ndírì, Ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni,Ilé ẹ̀kọ́ gbogbonṣe àti Ifáfitì ni kí ilẹ̀kùn wọn wà ní títì pa kí àwọn ọmọ le è ráàyè fi tọkàn tọkàn àti tẹ̀mí tẹ̀mí kópa nínú oṣù àwẹ̀ Mùsùlùmí tó bẹ̀rẹ̀ lónìí ọjọ́ kínní,oṣù kẹta ọdún 2025. Ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina ní ìjìyà m bẹ fún ilé ìwé Aládàní tó bá tàpá sí òfin yìí. Ìjọba tún ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún gbogbo lẹ́síìnì kéréje kéréje pé òfin yìí kò yọ wọ́n sílẹ̀, ìjọba ni òun kò ní fojú rere wo òbí, Akẹ́kọ̀ọ́ àti ilé ẹ̀kọ́ tó bá tàpá sí òfin ìjọba ìpínlẹ̀ Katsina. Àjọ HISBAH ti ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Katsina lókè ọya ló fi ìwé ìkìlọ̀ yìí ránṣẹ́.Wọ́n gbàá ní àdúà pé kí ÁLÀ gbàá ní iṣẹ́ olóore fún gbogbo wa. Ọ̀rọ̀ yìí ti dá awuyewuye sílẹ̀ lorí ẹ̀rọ ayélujára , àwọn kan ní ṣebí àwẹ̀ lẹ́ntì náà n lọ lọ́wọ́lọ́wọ́, kí ló dé tí àwọn Gómìnà ààrin gbùngbùn tàbí ilẹ̀ íbò náà kò kéde ìsìnmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́? Àwọn kan tilẹ̀ ní ìran Hausa tún n bá ẹlẹ́yà-mẹyà bọ níyẹn oooo, wọ́n tún fẹ́ gbé boko haram mìíràn kalẹ̀. Àwọn mìíràn ní abájọ tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Hausa kò fi n pegede nínú ìdánwò WASSCE, NECO àti JAMB. Àwọn kan tún ni ṣé àwọn ọmọ àti ọmọọmọ Gómínà náà wà lára Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní lọ sí ilé ẹ̀kọ́ látàrí Àwẹ̀ Ramadan àbí òkè òkun ni wọ́n wà, ofin ìsọnu yìí kò báwọn wí?
Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ tí ìpínlẹ̀ òkè ọya, Arábìnrin SUWAIBA AHMAD ló kọ́kọ́ lòdì sí bí wọ́n ti ní kí gbogbo Akẹ́kọ̀ọ́ gbélé lásìkò oṣù àwẹ̀ Ramadan, pé kò sí ìgbẹ̀kọ́ lásìkò yìí, nnkan tó burú jáì ni, kò ṣe é gbọ́ sétí rárá, Lọ́gán! Ọmọ́yẹlé Ṣòwòrẹ́ náà bá ta mọ́ ẹ̀rọ̀ ayélujára túwítà láti kín ọ̀rọ̀ SUWAIBA AHMAD lẹ́yìn lórí èrò rẹ̀. Ẹ gbọ́ ohun tí Mínísítà SUWAIBA AHMAD sọ :
‘ Kò sí òfin tàbí ìlànà kan lábẹ́ òfin ní àgbáyé tó ní kí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ má lọ ilé ìwé lásìkò oṣù àwẹ̀ Ramadan àgàgà ilẹ̀ Sàúdí tí ẹ̀sìn Mùsùlùmí ti gbilẹ̀, ibẹ̀ gan an ni ìlú ẹ̀sìn Mùsùlùmí nítorí ibẹ̀ ni wọ́n ti n rí oṣù àwẹ̀ Ramadan, títí dí bí a tí sọ yìí, Ẹ̀kọ́ ṣì n lọ níbẹ̀, wọn kò dáwọ́ ẹ̀kọ́ dúró rárá, bí wọ́n ti n gba àwẹ̀ náà ni wọ́n n kẹ́kọ̀ọ́, ọ̀kan kò dá ọ̀kan dúró. Báwo ni ọ̀rọ̀ ti wá bẹ́yìn yọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà? Kìí sì ṣe ẹ̀sìn Mùsùlùmí níkàn ló wà nílẹ̀ yìí. Párá! Ọmọ́yẹlé Ṣòwòrẹ́ kín ọ̀rọ̀ Mínísítà SUWAIBA AHMAD lẹ́yìn , Ṣòwòrẹ́ ní :
Àwọn ọmọ olórí tó n pàṣẹ̀ pé kí wọ́n ti ilè ìwé pa lásìkò oṣù àwẹ̀ Ramadan kìí lọ ilé ìwé ìjọba débi pé òfin yìí yóò mú àwọn náà, òkè òkun ní púpọ̀ nínú wọn tí n kàwé èyí tí kò lọ kàwé lókè òkun n lọ sí ilé ìwé Aládáni olówó gọbọi, tó sì jẹ́ wí pé kìí ṣe owó òógùn ojú wọn ni wọ́n n ná bí kò ṣe láti inú àpò ìṣúná owó fún ètò ẹ̀kọ́ tí ìjọba àpapọ̀ yà sọ́tọ́ fún àwọn ọmọ mèkúnnù,irú àwọn wọnyìí kò le è tí ilé ìwé pa láéláé.
Awuyewuye ni ọ̀rọ̀ yìí dá sílẹ̀ nínú ìlú, àwọn kan ní àsìkò òòrùn tó n mú hánhán lawà yìí, yóò nira púpọ̀ láti pé kí ìwé wọ orí àgàgà ní ilẹ̀ HAUSA tó jẹ́ òòrùn ibẹ̀ lékan sí. Àwọn mìíràn ní ìjọba BAUCHI àti àwọn ìpínlẹ̀ tí ọ̀rọ̀ kàn ti fi àkókò oṣù àwẹ̀ Ramadan sọ́kàn nígbà tí wọ́n ṣètò kàlẹ́ndà ètò ẹ̀kọ́ wọ́n fún sáà kejì yìí, kò le è wọ̀ rárá nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni olójú jínjìn wọn ti mú ẹ̀kún sun.
Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé àwọn ará òkè ọya lóni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, àwọn ló pọ̀ jù ní ètò iṣèjọba, ohun tó bá wu alágbẹ̀dẹ ló le è rọ irin tún irin rọ.