Nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè yìí látìgbà tá a ti gbòmìnira, èyí tá a mọ̀, tó ṣojú wa pọ̀ ju èyí tí a ò mọ̀ lọ. Lóòótọ́ a lè má sìí nígbọ̀n-ọ́nnu ètò ìjọba, a lè má sìí nídìí àgbá agbára. Àmọ́ ohun tó dájú ṣáká ni pé ìtàn ìnàkí lojú wa kò tó, tó bá jẹ́ ti ọ̀bọ ni, a mọ̀ díẹ̀ níbẹ̀. Ìtàn kì í sì í tán, ìtán máa ń tàn ni. Ìdí rèé tí àwọn àgbà fi máà ń pa á lówe pé ọba tó jẹ, tó fiyùn bọ́lẹ̀, ìtàn rẹ̀ kò ní í parẹ́; èyí tó jẹ tí a ń fi imí ẹlẹ́bọ́tọ bọ́lẹ̀, ìtàn rẹ̀ kò ní í parun bákan náà.
A lè béèrè ìdí abájọ atótónu wa yìí. Bí nǹkan ò bá ṣẹ ẹ̀ṣẹ́, ẹ̀ṣẹ́ kì í ṣẹ́ lásán. Ọkùnrin olórí ìjọba ológun tó ti jẹ́ Aarẹ( ológun) nílẹ̀ yìí ni èrò tiwa dá lé lórí. Àìpẹ̀ yìí ni ọkùnrin tí a ń pè ní MARADONA gbé ìwé kan jáde tó dá lórí ìrìn-àjò rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìnrú látìgbà tó ti wọ ilé iṣẹ́ ọmọ ológun ilẹ̀ yìí títí fi di ìgbà tó fi ‘yẹ̀bá fúngbà díẹ̀’ gẹ́gẹ̀ bí olórí ìjọba ológun ìgbà náà. Ó pe ìwé náà ní ‘ A journey in service’.
Nínú ìwé yìí ni ọkùnrin náà ti ṣàlàyé ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ó wà nípò olórí ológun ilẹ̀ yìí. Ibrahim Badamas Babangida fi ìwé náà lọ́lẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì tó kọjá yìí – 21-2-25..
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ làwọn lóókọ-lóókọ àti léèkàn-léèkàn lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba àtàwọn tó ti ṣèjọba rí;àwọn olóṣèlú tàtijọ́ àti tòde-òní tí wọ́n péjú-pésẹ̀. Ká sọ tòótọ́, ọ̀rọ́ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀.
Nínú àwọn àlàyé rẹ̀, òótọ́ ọ̀rọ̀ ọ́ jẹ jáde ; irọ́ jẹyọ; àhọbó, àrògún àti àsọdùn kò gbẹ́hìn níbẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn; òkodoro àlàyé rẹ̀ lórí ìbò ọjọ́ Kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 1993; ikú Délé Gííwá; ẹ̀yáwó látọ̀dọ̀ ajọ IMF, àti ìhà táwọn ọmọ ilẹ̀ yìí kọ sí i ; ìdìtẹ̀ gbàjọba Okar àti Vatsa; ipa tí Abacha kó nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò náà. Gbogbo rẹ̀ ni ọkùnrin yìí rí àwíjàre wí o. Ṣé wón ní bí a gún ata lódó, bí a lọ ata lọ́lọ, ìwà ata kò ní í fi ata sílẹ̀.
Ojú tí Èrò Tiwa fi wò ó ní pé ejò ti lọ tán, kí ọkùnrin yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ tó máa fi ọ̀pá nalẹ̀; aṣọ KÒ BÁ Ọmọ́yẹ mọ́, Ọmọ́yẹ ti rìnhòòhò wọjà ; ọ̀bẹ́ gé ọmọ lọ́wọ́ tán, a ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ọ̀bẹ nù, ọ̀bẹ́ ti ṣiṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ parí. Ìwà Màràdònà rẹ̀ náà ló kó jọ sínú ìwé ọ̀ún. Ó mọ̀ pé ọ̀pọ̀ tó fara gbá lọ́nà kan tàbí òmíràn lákòókò tí ó ń ṣèjọba rẹ̀, tí wọ́n lè ja òun níyàn, ni wọn ti di ẹni àkọlẹ̀bò. Ara kò rọ okùn, ara kò rọ adìẹ ni oníkálukú bá dúró nígbà náà. Àwọn tó sá lọ kò lóǹkà, àwọn tó kú ikú abàadì pọ̀ jáǹtìrẹrẹ.
Èyí tí okùnrin yìí ì bá fi lo àkókò yìí láti fi tọrọ ìdáríjì iṣẹ́ láabi tó ṣe, àmọna àti ọ̀rọ̀ rírùn ló ń jáde nígboro ẹnu rẹ̀, tó sì ń fi ẹ̀rín yẹ̀ẹ̀ bí ìṣe rẹ̀ gbè é lẹ́sẹ̀. Orísìírísìí awuyewuye ló ń lọ káàkiri nígbà náà; orísìírísìí ìwé táwọn Òǹkọ̀wé ń kọ lásìkò náà ni wọ́n ń fi ìnira táwùjọ ń kojú hàn.
Òǹkọ̀wé èdè Yorùbá kan tilẹ̀ wà, ìwé márùn-ún ni Alàgbà yìí kọ lédè Yorùbá láti fi ṣe àpèjúwe ohun tí àwùjọ wa ń là kọjá lákòókò ìjọba ológun tí Babangida ń darí
* Ẹkún Elédùmarè ( Ewì ni)
*Pápá ń jó. ( Ewì ni)
* Dìgbòlùjà. ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
* Pelemọ. ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
* Kannakánná ( Ìwé ọlọ́rọ̀ wuuru ni)
Gbogbo àwọn ìwé yìí ni Débọ̀ Awẹ́ fi ṣàpèjúwe pọ́nǹpọ́nnáyan tójú ọmọ Nàìjíríà rí lásìkò tí Màràdónà wà lórí ìjọba. Àsìkò Jẹnẹra Babangida kò sanmọna fọ́mọ orílẹ̀-èdè yìí rárá ni. Àléébù rẹ̀ pọ̀ ju àǹfààní rẹ̀ lọ.