Ìbánújẹ́ ńlá ló wọlé bá àwọn ẹbí Sunday Jimoh lálejò ní ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Èbìbí yìí nígbà tí Sunday kó sínú kànǹga láti yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ tó jábọ́ sínú rẹ̀.
Ọmọ odún mọ́kànlélọ́gbọ̀n ni Sunday, agbègbè Laditan ní ọjà ọ̀dàn ìpínlẹ̀ Ogun ni ilé rẹ̀ wà, ìbẹ̀ náà ni ìsọ̀ rẹ̀ wà.
Arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Kabiru Aladeshayi Ayigbere tí òun náà ń gbé ní ọjà ọ̀dàn ló ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ fún àwọn ọlọ́pàá pé ní ọjọ́ náà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Sunday jábọ́ sínú kànǹga tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ìsọ̀ rẹ̀. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Sunday ti fẹ́ kó sínú kànǹga yìí láti yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yìí, àwọn tó wà níbẹ̀ ni wọ́n dá a lẹ́kun pé ó léwu àmọ́ nígbà tójú pofírí, Sunday padà wọ inú kànǹga yìí láti yọ ẹ̀rọ náà àmọ́ kò padà jáde láàyè, òkú rẹ̀ ni wọ́n gbé jáde.
Àwọn èèyàn kò tiẹ̀ mọ̀ pé Sunday ti padà lọ yọ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà, Aladeshayi ló kọ́kọ́ fura pé òun kò rí Sunday ni àwọn èèyàn náà bá rokàn rẹ̀, wọ́n kàn ní kí àwọn wo inú kànǹga náà ni pé bóyá ó padà wọ inú ẹ̀, ohun tí ojú wọn bá pàdé kọjá sísọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láàárọ̀ yìí láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Omolola Odutola. Omolola ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè láti ọjà ọ̀dàn pé arákùnrin Sunday Jimoh kan kó sínú kànǹga. Àwọn ọlọ́pàá pakítí mọ́ra, wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n gbé òkú Sunday jáde, àyẹ̀wò fi hàn pé kò sí àpá tàbí àmì kankan lára rẹ̀ pé bóyá èèyàn kan ló tìí.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ti gba ojú rẹ̀ láti ṣètò bí wọn yóò ṣe sin ín.