Lórí ohun tí a ń jẹ lẹ́nu tí a ò tíì jẹ tán, Obasa fèsì nínú àtẹ̀jáde kan tó bu ọwọ́ lù pé òun kò mọ ohunkóhun nípa àwọn ìbọn bíi mẹ́tàdínláàdọ́ta tí wọ́n ní wọ́n bá ní ọ́fíìsì òun. Ó ṣe àlàyé pé aláwàdà kẹríkẹrì ni àwọn DSS yìí, ó ṣe jẹ́ ìsin yìí ni wọ́n rí ìbọn ní ọ́fíìsì òun? Dájúdájú, isẹ́ owó wọn ni wọ́n ń ṣe.
Àtèjáde náà ṣe àpèjúwe àwárí àwọn ìbọn náà bíi àgbélẹ̀rọ ofúùtùfẹẹ̀tẹ̀ lásán. Obasa wí pé ó hàn gbangba gbàǹgbà pé àwọn kan ni wọ́n jọ pètepèrò tí wọ́n ṣe sinimá náà ní èyí tó fi àbùkù ara wọn hàn síta.
Ó tẹ̀síwájú pé wọ́n ń gbìyànjú láti ba orúkọ tí òun ti ń là kàkà láti ọdun yìí wá lé lórí jẹ́, wọ́n ń wá àwáwí ẹ̀sùn sí òun lẹ́sẹ̀ láti bo ojúlówó ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀.
Àná ọjọ́rú ni àwọn ẹ̀ṣọ́ DSS lọ sí ọ́fíìsì Obasa láti túu wò, àwọn ìbọn ńlá ńlá ni wọ́n bá níbẹ̀. Wọ́n wá fi ẹ̀sùn kàn án pé ó ń kó àwọn ohun ìjà olóró kiri ní ọ̀nà tí kò bá òfin mu. Ìròyìn náà kà báyìí pé;
‘Wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìbọn tí wọ́n rí ní ọ́fíìsì abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó tí wọ́n rọ̀ lóyè, ìyẹn Mudashiru Ọbasá. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí a gbọ́, wọ́n ṣàwárí àwọn ìbọn náà ni àsìkò tí àwọn DSS ń ṣe ìpalẹ̀mọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún rí àwọn ọta ìbọn tí kò lóǹkà.
Yàtọ̀ sí pé wọ́n kàn sí Ọbasá láti mọ èrò ọkàn rè, ọ̀kan nínú àwọn abẹ́ṣinkáwọ́ rẹ̀ ní àròyé ìpoloñgo ẹnu lásán ni láti dínà mọ́ Ọbasá kí ó má leè padà wá sí ibùjókòó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí abẹnugan ilé. Wọ́n ní Ọbasá sì ń tẹnu mọ́ ọn pé ìyọnípò òun kò bá òfin mu rárá ni, ati pé òún sì wà ní ipò kẹ́ta ni Ìpínlẹ̀ Èkó.
Ẹlòmíràn tilẹ̀ tún ní àwọn kẹ́fiín ohun ìjà mìíràn tí wọ́n tò rọ́jọ́ rọ́jọ́ sí ọ́fíìsì olórí Ẹ̀ṣọ́ fún Ọbasá. Ní wàràǹṣeṣà ni wọn tún fi eléyìí tó àwọn DSS létí, táwọn ọ̀hún náà sì gbé èèyàn wọn dìde tí wọ́n sì wáá ṣe àyẹ̀wò wọn ; wọ́n sì tún kó wọn lọ sí kàtà DSS wọn lọ́hùn-ún fún àyẹ̀wò tó nípọn.
Wọ́n tilẹ̀ sọ ọ́ pé Ọbasá ń jà fitafita láti padà wá sí ibùba rẹẹ̀ kí ó lè ní àǹfààní àtipalẹ̀ mọ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án gbogbo ni. Lára ẹ̀sùn náà ni pé ó ń kó ohun ìjà bíi ìbọn, ọta ìbọn àti ohun olóró mìíràn kiri’.
Nígbà tí ìròyìn kan wí pé inú ọ́fíìsì Obasa ni wọ́n ti bá àwọn ìbọn náà, ìròyìn mìíràn wí pé inú ọ́fíìsì olórí ẹ̀ṣọ́ ààbò Obasa ni.
Ti Obasa lápá kan, lápá keji ni ti agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin titun: Meranda tí wọ́n ló kọ̀wé fipò sílẹ̀.
Ìwé ìfipòsílẹ̀ kan gba orí afẹ́fẹ́ kan lánàá, nínú rẹ̀ ni wọ́n ti kọ ọ́ pé Meranda ti fi ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin sílè. Déétì tó wà lórí lẹ́tà náà jẹ/ 17/02/2025.
Ẹni tó jẹ́ akọ̀wé àtẹ̀jáde fún Meranda: Segun Ajiboye sọ pé òfegèé ni ìwé ifipòsílẹ̀ náà, òun kò mọ ẹni tó gbé e jáde. Ajiboye wí pé digbí ni Meranda wà, mìmì kan kò mì ín ní ipò agbẹnusọ tó wà, nítorí náà, kí àwọn èèyàn ó gbójú kúrò lára ìwé òfegèé náà.
Àyèwò àẉọn oníròyìn fi hàn pé ìwé ìfipòsílẹ̀ náà kò ní ìbuwọ́lù Meranda.
Ó kù nìbọn ń ró, ìròyìn tún kàn pé àwọn ọmọ ẹgbé òṣèlú ọlọ́wọ̀ APC mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ti yapa lọ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour. Ogundipe Olukayode: ẹni tó jẹ́ alága ikọ̀ ètò àti ààbò wí pé òfegèé ni ìròyìn náà nítorí pé ẹgbẹ́ APC wà ní digbí. Olukayode wí pé àwọn kò yindin, wọn ò kẹtan kódà wọn ò kẹsẹ̀, ṣinṣin ni ẹṣẹ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC múlẹ̀.