Ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀, ẹ fìkàlẹ̀ síi.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìpínlẹ̀ Osun léríléka lórí èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Osun tó wáyé lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, wọ́n kọ èsì ìbò náà jálẹ̀, wọ́n ní àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ti ìdìbò àkọ́kọ́ tó wáyé ní ọdún tó kọjá ní èyí tí àwọn olùdíje lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC wọlé ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ pátá ni ojúlówó èsì ìdìbò.
Ọ̀gbẹ́ni Jamiu Olawunmi; ẹni tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun àná; Adegboyega Oyetola ṣe àlàyé fún àwọn ikọ̀ akọ̀ròyìn pé àwọn ìgbésẹ̀ tí àwọn yóò gbé lórí ọ̀rọ̀ alága ìjọba ìbílẹ̀ yìí yóò mú kí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ó mọ̀ pé ìkan ju ìkan lọ.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn yóò kọ ìwé sí gbogbo ilé ìfowópamọ́ láti ti àpò owó àwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbogbo kí àwọn tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ yàn yìí ó má baà lẹ́tọ̀ọ́ sí owó kankan.
Bákan náà ni wọ́n wí pé ilé ìfowópamọ́ tó bá fún àwọn alága titun yìí lówó yóò fojú winá òfin.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé ipò alága ìjọba ìbílẹ̀ yìí ti di òjé tí wọ́n tì bọ olóòṣà lọ́wọ́ tí kò sí ẹni tí yóò bọ́ ọ, wọ́n gbàgbé pé wọn a máa gé òjé tí kò bá ṣe é bọ́.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò máa lọ sí ibi iṣẹ́ wọn, gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ pátá ni awon ti ránṣẹ́ sí pé kí wọn ó padà sí ẹnu ìṣẹ́ wọn láàárọ̀ yìí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé àwọn ọlọ́pàá wà ní sẹ́pẹ́ ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ láti kojú ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbémú, wọ́n ní àwọn ṣe ìdìbò lọ́dún tó kọjá àwọn sì wọlé àti pé ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti dá àwọn láre, nítorí náà, àwọn alága náà ni ojúlówó kò séwu fún wọn.
Gbogbo bí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ń léríléka yìí, tí ajá wọn ń gbó bí èyí tí eyin rẹ̀ yóò yọ, ìran ni àgùntàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń fi wọ́n wò.
Ẹni a bá ń bá nájà làá kọjú sí, Gómìnà Adeleke kò wo ti ariwo ọjà rárá, ó ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn alága àṣẹ̀ṣẹ̀dìbòyàn titun náà pé kí wọn ó má lọ sí ibi iṣẹ́ lónìí o nítorí òun kò fẹ́ kí àwọn ajá tó wà ní ibẹ̀ bù wọ́n jẹ.
Níbi tí Gómìnà Adeleke ti ṣe ìbúrawọlé fún wọn lọ́jọ́ Àìkú ni ó ti ṣe ìkìlọ̀ náà pé kí wọn ó wà nílé wọn lónìí ná kí wọ́n fi wojú ilẹ̀, Adeleke wí pé àwọn tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ń pọ̀n lẹ́yìn láti wà ní àwọn ọ́fíìsì náà kò kọ ohunkóhun, nítorí náà kí wọn ó jókòó sílé lónìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà kó ipa tirẹ̀ ___
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará osun àti agbègbè ti fi ẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá àti kọmísọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun pé àwọn ló ń kín Oyetola lẹ́yìn tó fi ń ṣe gbogbo ohun tó ń ṣe. Wọ́n ní ìromi Oyetola tó ń jó pé kọmísọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni onílù rẹ̀ tó wà ní ìsàlẹ̀ odò.
Kódà, àbúrò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun; gbajúgbajà olórin tàkasúfě Adeleke David tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Davido nàka àbùkù sí kọmísọ́nà ọlọ́pàá Osun pé ó ṣe ojúsàájú nínú rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ náà.
Pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí lọ́tùn-ún lósì, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kó àwọn ọlọ́pàá tí ojú wọn le koko, àwọn tí wọn ò gbọ́ nǹkankan tí wọ́n ti gé etí wọn lọ dà sí gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ pé ẹni tó bá láyà kó wá fa wàhálà kankan. Ìròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọn yóò wà ní ibẹ̀ kolẹ̀ oṣù yìí ni.
Gbogbo wàhálà yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun àná; Adegboyega Oyetola pàṣẹ fún àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí wọ́n dá dúró pé kí wọn ó padà sípò.
Olóyè Oyetọ́lá ní kí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ àná Padà sí orí àga lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù yìí ( 17/02/25. Nínú ìpàdé tí gómìnà Adélékè ṣe pẹ̀lú àwọn oníròyìn ní ọjọ́ Àìkú-16/02/25 ló ti fẹ̀sùn kan Mínístà fún ètò ìrìnnà Orí omi, Adégbóyega Oyetọ́lá pé ó ń pète-pèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀șun, ó sì fẹ́ lo àwọn agbófinró ṣáájú àti láti ṣe atọ́nà awon alága àti Káńsẹ́lọ́ àná náà lọ sí ibùjókòó ìjọba ìbílẹ̀ kálukú.
Gómìnà Adélékè șàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀gbẹ́ni Oyetọ́lá jẹ́ ìbátan sí Ààrẹ Tinubu, ìyẹn ò fún un ní agbára kankan láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Adélékè ní ” àwa ò ní í gbà pé kí ẹnikẹ́ni gorí ìjọba ìbílẹ̀ láìjẹ́ pé a bá lo ìlànà ìdájọ́ òdodo tàbí ílànà ìyànsípò tó bófin mu nípa ìlànà ètò ìdìbò”
Ademola Adélékè ní òun ò mọ nǹkan kan nípa lílé tí wọ́n lé àwọn alága àná kúrò lórí àlééfà. Ó ní ilé ẹjọ́ ti yọ ọwọ́ kí-là-ń-kó wọn kúrò kóun tóó dórí oyè. Ó ní ó ṣe òun láàánú láti fi tó Ààrẹ àti àwọn èèyàn àwùjọ létí pé Oyetọ́lá ti parí gbogbo ètò látidá rògbòdìyàn sílẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Ajé – 17/02/25. Pé ó sì ti pàṣẹ oníkùùmọ̀ fún àwọn ẹ̀ka agbófinró láti gbé ìgbésẹ̀ tí kò bójú mú un. Oyetọ́lá ń ṣe èyí nítorí pé ó jẹ́ ìbátan Tinubu, ó sì ń pakuru mọ́ àwọn agbofinro láti tẹ̀ lé àṣẹ oníkùùmọ̀ rẹ̀.
Ní báyìí, wọ́n ti dìbò ìjọba ìbílẹ̀ titun ní Osun, ẹgbẹ́ PDP ló jáwé olúborí ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀, ẹgbẹ́ APC kọ̀ láti kúrò ní ọ́fíìsì, kí ló máa ṣẹlẹ̀ báyìí?