Pásítọ̀ ìjọ ìràpadà, The Redeemed christain Church of God; pásítọ̀ Enoch Adeboye sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn àjọ ẹlẹ́sìn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Christain youth forum ṣe fi ọlọ́pàá gbé Olumide Ogunsanwo tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ seaking lórí ẹ̀sùn pé ó sọ̀rọ̀ sí Adeboye.
Olumide jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì ayélujára Tiktok, ohun tó gbé e kọlu àjọ náà ni ọ̀rọ̀ tó sọ sí pásítọ̀ Adeboye lórí ojú òpó Tiktok rẹ̀.
Olumide Ogunsanya alias Seaking wí pé òmùgọ̀ ni pásítọ̀ Adeboye nítorí pé ó ní kí àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ ó gba ààwẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọjọ́ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Seaking wí pé ohun tí Adeboye sọ yìí fi hàn pé bàbá náà kò lọ́gbọ́n lórí bẹ́ẹ̀ sì ni kò lóye, ó ní kín ni ìdí tí yóò fi sọ pé kí àwọn èèyàn ó gba ààwẹ̀ fún odidi ọgọ́rùn-ún ọjọ́ nítorí orílẹ̀-èdè Nàìjíría?
Ọ̀rọ̀ yìí kò ṣe déédéé ara àwọn ọ̀dọ́ kìrìsìtẹ́nì tí wọ́n pe ara wọn ní christain youth forum yìí, wọ́n fi ọlọ́pàá gbé seaking láti oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá wọ́n sì ń bá a ṣe ẹjọ́.
Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan seaking náà ni pé ó tàbùkù pásítọ̀ Adeboye, wọ́n ní ó pe àgbàlagbà ní òmùgọ̀ ní èyí tó lòdì sí ìwà ọmọlúàbí tí a ń lò nílẹ̀ wa.
Pásítọ̀ Adeboye ṣe fọ́nrán kan lánàá, nínú rẹ̀ ló ti sọ pé òun gbọ́ pé wọ́n torí tòun ti èèyàn kan mọ́lé, Adeboye wí pé òun kò mọ̀ nípa rẹ̀ àti pé kí wọn ó dá ọmọkùnrin náà sílẹ̀ ní kíákíá.
Pásítọ̀ Adeboye wí pé àwọn ọmọ ìjọ ìràpadà ìyẹn àwọn ọmọ ìjọ The Redeemed christain Church of God ni òun ní kí wọn ó gba ààwẹ̀ ọlọ́gọ́rùn-ún ọjọ́ náà bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí kìí ṣe ọmọkùnrin seaking yìí bẹ́ẹ̀ sì ni òun kò bá ẹni tí kìí ṣe ọmọ ìjọ òun wí rárá.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé ẹ̀mí mímọ́ ti sọ fún òun tẹ́lẹ̀ pé ẹnìkan yóò tàbùkù òun lórí ọ̀rọ̀ ààwẹ̀ náà, nítorí náà kí wọn ó dá ọmọkùnrin náà sílẹ̀ òun kò lọ́wọ́ sí ẹjọ́ náà.
James Adama; ẹni tó jẹ́ olùdarí àjọ Christian youth forum gbé ẹnu sí máìkì lórí ọ̀rọ̀ náà, ó ṣe àlàyé pé àwọn ló kọ ìwé ìfisùn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó láti gbé arákùnrin Olumide Ogunsanwo tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí seaking yìí.
Adama ṣe àlàyé pé ohun tí seaking ṣe náà ni pé ó tàbùkù ẹni àmì òróró, ó pe àgbàlagbà tí àwọn èèyàn ń pọ́nlé tí wọ́n sì ń gbé gẹ̀gẹ̀ ní òmùgọ̀ àti òpònú ó sì wọ́ ọ nílẹ̀ turutu ó tún rọ omi sí ìdi rẹ̀.
Adama wí pé fọ́nrán náà ba òun lọ́kàn jẹ́ pé ọmọ ọdún méjìlélọ́gbọ̀n kan ṣe ẹnu yánkanyànkan sí àgbàlagbà ẹni àmì òróró. Ó wí pé irú àwọn ọ̀rọ̀ àlùfàǹsá báyìí le da omi àlàáfíà ìlú rú àti pé kò fi ìwà ọmọlúàbí hàn rárá.
James Adama fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ti fi ọlọ́pàá gbé seaking yóò sì fojú ba ilé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn náà.
Ní báyìí, pásítọ̀ Adeboye wí pé òun kò rídìíkan lórí ohun tí ìjọ Christian youth forum ṣe yìí, ó ní òun kò rán wọn láti fi ọlọ́pàá gbé ẹnikẹ́ni tàbí bá ẹnikẹ́ni ṣẹjọ́ nítorí pé ó bú òun o, nítorí náà kí wọn ó dá ọmọkùnrin náà sílẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà.
Ọ̀rọ̀ yìí ti di ti àjà tí wọ́n ń torí rẹ̀ jà tó tún wá ní ta ló ń jà lẹ́yìnkùlé òun?
Ta la na? Ta lara ń ro? Èyí ni ìbéèrè tí àwọn èèyàn ń bi ara wọn pé kí ló kan àjọ Christian youth forum nínú ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀? Ẹni tí wọ́n bú ní òun kò bínú, àwọn wá yarí wọ́n fi ààké kọ́rí bí ti olójúkan tó ń ṣe ìnàwó.
Ìwé ìròyìn yorùbá kọ́ ló sọ bẹ́ẹ̀ o, àwọn àríwísí orí ìtàkùn ayélujára ni.
Ó kù ni ìbọn ń ró, ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn nnì, Deji Adeyanju wí pé bí àgbàlagbà onígbàgbọ́ ṣe yẹ kó ṣe ni pásítọ̀ Adeboye ṣe yẹn, ó ní onígbàgbọ́ tó bá bá èèyàn ṣe ẹjọ́ nítorí pé ó bú u kìí ṣe onígbàgbọ́ gidi nítorí pé Jesu gan-an fúnra rẹ̀, àwọn èèyàn bú u.
Ó wí pé àwọn yóò gba seaking nímọ̀ràn pé kó pe ẹni tó kọ ìwé ìfisùn náà lẹ́jọ́ nítorí pé òun kọ́ ni ó bú kò sì ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti fi ọlọ́pàá gbé e láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá fúnra wọn mọ̀ pé àjọ Christian youth forum kò lẹ́tọ̀ọ́ láti bá Seaking ṣe ẹjọ́ àyàfi pẹ̀lú ìfọwọ́sí Adeboye, ó ní wọ́n kàn fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ pa làpálàpá lásán ni.
Adeyanju ṣe àlàyé pé iṣẹ́ kò ká àwọn ọlọ́pàá lára ni wọ́n fi ń gbé èèyàn tó ń bú èèbú. Ó ní àwọn ọlọ́pàá mọ̀ pé àwọn àjọ náà kò lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé arákùnrin náà nítorí pé àwọn kọ́ ni ó bú, àìníṣẹ́ àti àìmọ ohun tó kàn ló ń bá wọn jà.
Adeyanju wí pé ohun tó kàn náà ni kí òun ó ṣe àtúpalẹ̀ fọ́nrán tí Adeboye ṣe náà kí àwọn ó sì gba seaking sílẹ̀, àmọ́ ìdásílẹ̀ rẹ̀ le má yá kíákíá, adeyanju wí pé ṣebí ẹ mọ̀ pé kò sí ọgbọ́n lórí àwọn ọlọ́pàá.
Agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn ni Deji Adeyanju, èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tó máa kọ̀yà fún aláìléèyàn rèé, òun gan-an là bá pè ní ìrànlọ́wọ́ aláìlẹ́nìkan tàbí ká sọ pé òun ni onídùúró fún ẹni tí ò lẹ́sẹ̀.